Ohun tí amọ̀ nípa ikú Baba Bintin, òṣìṣẹ́ rédíò tó ṣubú lulẹ̀ lásìkò tó ń lọ ibi iṣẹ́ ní Ibadan nìyí

Oríṣun àwòrán, Fresh FM
Òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ rédíò Fresh FM tó wà ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo èyí tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Baba Bintin ti pàdánù rẹ̀ nígbà tó dédé ṣubí lásìkò tó ń rìn lọ sí ibi iṣẹ́ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Baba Bintin ń ló sí ibi iṣẹ́ láti lọ kópa lórí ètò kan kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé.
Ní orí ètò náà ni àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ti kéde ikú àgbà àgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà.
Mayor Isaac Brown nígbà tó ń kéde ikú náà ní ó ṣe òun láànú pé àwọn ń kéde ikú Baba Bintin.
Àwọn akégbẹ́ rẹ̀ lórí rédíò náà ní Baba Bintin ló ń rìn láti ilé rẹ̀ ní Amuloko lọ sí ilé iṣẹ́ Fresh FM tó wà ní Challenge nítorí kò sí owó lọ́wọ́ rẹ̀ tó sì ń wá PoS tí yóò gba owó lọ́wọ́ rẹ̀.
Wọ́n ni àwọn kan ló fi tó àwọn létí pé Baba Bintin ṣàdédé ṣubú lójú ọ̀nà tó sì gba ibẹ̀ kú kí àwọn tó gbe dé ilé ìwòsàn UCH.
Baba Bintin tó máa ń sọ èdè Ijesha jẹ gbajúmọ̀ lórí ètò Oyin Ado níbi tó ti máa ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọjà ní gbogbo ọjọ́ Àbámẹ́ta.











