Ọ̀wọ́n gógó Náírà mú àdínkù bá ìdámẹ́wàá àti ọrẹ ní ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn ìjọ figbe ta

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ń ṣe ni àwọn àlúfàá ìjọ ní ilé ìjọsìn káàkiri orílẹ̀ èdè yìí ti ń kùn yùmùyùmù báyìí nítorí bí kò ṣe sí owó náírà níta, tí fífí owó ránṣẹ́ lórí fóònù ìyẹn “transfer” náà kò sì rọrùn ní àsìkò yìí.
Àwọn ilé ìjọsìn kan ní ìpínlẹ̀ Kaduna ní àdínkù ti bá iye owó tó máa ń wọlé sí àpò ilé ìjọsìn àwọn, gẹ́gẹ́ bí owó ìdá mẹ́wàá àti owó ọrẹ nítorí ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ ni kò rí bi lọ sílé ìjọsìn.
Gẹgẹbi ile ijọsin Daily Post ti gbe sita, pásítọ̀ ìjọ Mountain of Fire and Miracle Ministries tẹ̀ka North Central 2 Barnawa, Sunday Owolabi kọminú lórí iye tó ń wọ àpò ilé ìjọsìn náà báyìí.
"N1m si N2.5m là ń rí tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí kò ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún sí àádọ́ta náírà báyìí"
Pásítọ̀ Owolabi ní àìsí owó náírà níta ń kó ìpalára gidi bá àwọn ènìyàn, tó sì gbàdúrà kí Ọlọ́run kó sí àwọn adarí orílẹ̀ èdè yìí lọ́kàn láti ṣe ohun tó yẹ.
Pásítọ̀ ìjọ mìíràn, Pásítọ̀ John David ní iye tí àwọn máa ń rí gbà gẹ́gẹ́ bí ìdá mẹ́wàá àti owó ọrẹ máa ń tó mílíọ̀nù kan sí mílíọ̀nù méjì àbọ̀ náírà tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí kò ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún sí àádọ́ta náírà báyìí.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọ àwọn ni àwọn kò ì tíì san owó oṣù fún nítorí owó tó wà ní àpò ìjọ kò tó nǹkan rárá láti ìgbà tí ètò owó tuntun ti bẹ̀rẹ̀.
Bákan náà ní ilé ìjọsìn Dunamis Church, Kaduna Pásítọ̀ John Moses ní yàtọ̀ sí ìdá mẹ́wàá àti owó ọrẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ìjọ ni ko ti yọjú sí ilé ìjọsìn mọ́ nítorí wọn ò ní owo ọkọ̀ láti lọ sí ilé ìjọsìn.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ ló ń pariwo ebi àti ìyàn àti àwọn ìpèníjà tí àìsí owó náírà ń kó báwọn.
UNILAG, LASU sún ọjọ́ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò wọlé síwájú

Oríṣun àwòrán, @SAKarounwi_Esq
Fasiti ijọba ilu Eko ati ti ijọba apapọ to wa niluu Eko, UNILAG ati LASU, ti sun ọjọ to yẹ ki awọn akẹkọọ pada sile ẹkọ siwaju.
Eredi igbesẹ naa ko ṣẹyin bi ajọ eleto idibo, INEC, ṣe sun ọjọ dibo gomina ati ti ile aṣofin ipinlẹ siwaju pẹlu ọsẹ kan.
Ṣaaju ni INEC ti kọkọ kede afikun ọsẹ kan si ọjọ to yẹ ki eto dibo naa yoo waye lọna ati ṣatunṣe si ẹrọ BVAS ti wọn yoo lo fun eto naa.
Ninu atẹjade meji ọtọtọ ni ile ẹkọ LASU ati UNILAG ti kede ọjọ tuntun ti saa ẹkọ tuntun yoo bẹrẹ.
UNILAg ninu atẹjajde to fi lede loju opo Facebook sọ pe “Lorukọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ yii ati ọga agba, Folasade Ogunsola, wọn ti sun akoko ti awọn akẹkọọ yoo pada silẹ ẹkọ si ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023.”
“Amọ ṣa, awọn eto fasiti naa bii idanilẹkọọ pataki atawọn ipade mii to yẹ ko waye ko ni yipada.”
Fasiti ọhun tun sọ siwaju sii pe ijọba ti kede ṣaaju pe gbogbo awọn akẹkọo kaakiri Naijiria gbọdọ pada sile lọdọ awọn obi wọn ṣaaju eto idibo gbogbogbo naa.
Lẹyin naa ni wọn ke si awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ ile ẹkọ ọhun lati jẹ aṣoju rere, ki wọn si ṣọra fun irufẹ awọn ohun ti wọn yoo maa sọ laarin ilu ati lori ayelujara.
Ninu iroyin kan naa, ọga agba LASU Ọjọgbọn Ibiyemi Olatunji-Bello ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ti fọwọ si ki wọn sun igba ti ẹkọ yoo pada bẹrẹ siwaju.
Olatunji-Bello wa ke si awọn akẹkọọ naa lati pada sile ẹkọ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2023.
Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta yii lo yẹ ki eto idibo naa waye amọ INEC sun siwaju nitori ọrọ BVAS.












