Iléèṣẹ̀ wọ gáù bí òṣìṣẹ́ méjì ṣe dédé já sínú alagbalúgbú ìpápánu Ṣokoléètì

Ṣokoleeti

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ajọ to n ri si aabo lẹnu iṣẹ lorilẹede Amẹrika ti fi ofin gbe ileeṣẹ Pennsylva kan, Mars Wrigley factory to w ani ilu Elisabethtown.

Wọn paṣẹ ki ileeṣẹ naa san faani to le ni ẹgbẹrun mẹrinla abọ dọla ($14,500) ni ibamu pẹlu aṣẹ to de abo ati eto ilera.

Awọn oṣiṣẹ naa jẹ kọngila ti kii ṣe pe wọn n ṣe iṣẹ gẹgẹ bii oṣiṣẹ wọn gangan.

Agba Ṣokoleeti

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Iṣẹlẹ yii waye ninu oṣu Kẹfa ọdun 2022. Ki wọn to lee ri awọn oṣiṣẹ ọhun gbe jade, wọn ni lati wa ọna ge idi àgbá to kun fọ́fọ́ fun ipapanu Ṣokoleeti.

O to eeyan mejila to yọnda lati doola awọ́n mejeji to yọju koda wọn gbe oṣiṣẹ kan pẹlu ọkọ baalu lọ si ile iwosan gẹgẹ bi awọn oniroyin abẹle ṣe sọ ọ.

Ileeṣẹ iroyin kan, The regulator’s report fi ẹnu kun un pe iṣẹlẹ naa jẹ eyi to lagbara gan. O ni “wọn gba awọn oṣiṣẹ kọngila naa lati wa fọ inu tanki wọn amọ wọn ko pese awọn nnkan tabi ṣe ikọni nipa abo fun wọn.

O jẹ ko di mimọ pe awọn oṣiṣẹ kọngila naa jabọ sinu tanki ti wọn n lo lati fi po awọn elo pọ fun “Dove Chocolate, eyi ti wọn maa n ta nilẹ Amẹrika koda ni UK atawọn ibomii, ọba ni Dove Chocolate.

Aṣoju to tun jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ Mars Wrigley ni awọn tẹwọ gba abajade iwadii naa.

“Abo awọn alabaṣiṣẹ wa to fi mọ awọn kọngila jẹ nnkan to jẹ wa logun gidi gan.”

“Bi a ṣe maa n ṣe ni gbogbo igba, a mọ riri ipa ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ abo lẹnu iṣẹ ati eto ilera ti wọn si n pawọpọ ba wa ṣiṣẹ lati ṣe ayẹwo lẹyin iṣẹlẹ naa.”

Ileeṣẹ meji, Mars ati Wrigle ti wọn jọ jẹ ileeṣẹ nilẹ Amẹrika ti awọn mejeji si ti le ni ọgọrun ọdun darapọ ninu ọdun 2008.

Ileeṣẹ yii lo n pese oniruuru ipapanu gbajumọ ti ọpọ eeyan mọ bii M&Ms, Snickers ati Twix.