Amosun, jọ̀ọ́ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú yókù láti bá wa lé Dapo Abiodun kúrò nípọ̀ gómìnà - Àwọn olùwọ́de

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Saaju idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ogun, awọn oluwọde kan labẹ aburada awọn ọmọ ipinlẹ Ogun to n gbarata (CCOS) ti ṣewọde lọ si ile gomina tẹlẹri nipinlẹ naa, Ibikunle Amosun.

Awọn oluwọde naa lo n rọ Amosun pe ko darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa lati le gomina Dapo Abiodun kuro nipo lasiko idibo sipo gomina ti yoo waye naa.

Ọjọ Kejidinlogun, Osu Kẹta, ọdun 2023 ni idibo si ipo gomina yoo waye ni ipinlẹ Ogun ati kaakiri orilẹede Naijiria.

Bi o tilẹ jẹ pe Amosun wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC kan naa pẹlu Dapo Abiodun amọ to tako iwọle saa keji gomina APC naa.

Oludije fẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Biyi Otegbeye si ni Ibikunle Amosun n ṣe atilẹyin fun lati di gomina ipinlẹ Ogun.

Bakan naa ni Amosun ko ṣe atilẹyin fun Abiodun ni idibo sipo gomina to gbe wọle ni ọdun 2019.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

‘’ Dapo Abiodun gbọdọ lọ’’

Awọn afẹhọnu han ni wọn gbe asia dani loriṣirisi, ti wọn si wọ agbegbe Ibara Housing Estate ti ile Ibikunle Amosun wa.

Wọn wa n bẹ Amosun lati ṣatilẹyin fun oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Ladi Adebutu ninu eto idibo naa.

Lara awọn ọrọ ti wọn kọ sinu asia ti wọn gbe dani pe ‘’ Dapo Abiodun gbọdọ lọ’’ , ‘’Sẹnetọ Ibikunle Amosun ma ja awa ara ipinlẹ Ogun lulẹ’’, ‘’ Ṣẹnetọ Amosun jọwọ ṣe atilẹyin fun wa.’’

Adari awọn afẹhọnu han naa, Ajirotutu Oluwafemi to fi lẹta ṣọwọ si ṣẹnetọ Amosun ni ayafi tawọn ẹgbẹ oselu loniruuru ba ṣiṣẹ pọ ni wọn to le bori gomina Abiodun ninu idibo to n bọ naa.

‘’ Amọ daju pe ko rọrun lati jẹ ki ẹni to wa ni ipo fidi rẹmi, nitori naa ni a gbọdọ se ṣiṣẹ pọ’’

"Amosun, ẹgbẹ oselu ADC nikan ko le le Dapo Abiodun kuro nipo"

Bakan naa ni wọn bẹ Amosun pe ko mase lo ẹgbẹ oselu ADC nikan lati le Dapo Abiodun kuro nipo nitori igbesẹ naa ko ni ṣiṣẹ.

Awọn oluwọde naa ni ibo ti wọn ba di fun ADC yoo lọ si ọdọ Dapo Abiodun ati ADC ni.

Muyiwa Oladipo, tii se adari ikọ ipolongo ibo fun oludije sipo gomina fẹgbẹ oselu ADC, Biyi Otegbeye, lo tẹwọ gba lẹta naa lọwọ awọn oluwọde to n fapa janu naa ni orukọ Ibikunle Amosun.

O wa fi dawọn oluwọde naa loju pe gbogbo ẹdun ọkan wọn ni gomina tẹlẹri naa yoo ṣayẹwo rẹ, ti wọn yoo si gbọ lati ọdọ rẹ laipẹ.

Awọn akanda ẹda n satilẹyin fun Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR

Ki ni Dapo Abiodun sọ lori igbesẹ lati gbimọ yọ nipo?

Titi di akoko yii, gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ko tii sọrọ kankan lori bi awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oselu se n dipanpa lati le kuro nipo.

Sugbọn lawọn oju opo ayelujara rẹ, a se akiyesi pe ọpọ awọn ẹgbẹ to wa nipinlẹ Ogun lo ti n satilẹyin fun Abiodun ninu ilakaka rẹ lati pada se saa keji bii gomina.

Gẹgẹ bo se wa loju opo Twitter Dapo Abiodun, lara awọn ẹgbẹ oselu to ti n kede atilẹyin wọn fun gomina naa ni ẹgbẹ awọn osisẹ NLC, ẹka tipinlẹ naa.

Bakan naa, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ onisẹ ọwọ bii awọn aransọ.

Koda ẹgbẹ agbarijọpọ awọn Imaamu ati Alfa nipinlẹ Ogun naa ti fi ifẹ han lati maa ba Dapo Abiodun lọ lasiko ibo.

Awọn Imaamu ati Alfa n satilẹyin fun Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR