''Ẹ̀ẹ̀mejì ní mo lá àlá pé Tinubu di ààrẹ ní mo ṣe wa kẹ̀kẹ́ láti Kaduna dé Eko''

Mallam Bello Ahmed

Oríṣun àwòrán, The Nation

Ọkunrin onikẹkẹ kan lati ipinlẹ Kaduna, Mallam Bello Ahmed ti ṣalaye bi oun ṣe wa kẹkẹ lati Katsina wa si ilu Eko lati wa ri aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Ahmed Tinubu.

Bẹẹ ba gbagbe, ọsẹ to kọja la mu iroyin kan wa fun yin pe ọkunrin ọlọkada kan, Alhaji Abdulahhi Obodo naa gun ọkada lati Plateau wa si Eko.

Ahmed to sọ iriri rẹ fun ileeṣẹ iroyin ‘’The Nation’’ pe oun wa lati agbegbe Gubuchi, ni ijọba ibilẹ Kaduna, o ni awọn eniyan n sọrọ nipa rẹ lori ẹrọ ayelujara.

Ọjọ marundinlogun ni Ahmed fi rin irinajo rẹ lati Kaduna wa si ilu Eko lati yọ pẹlu Tinubu to jawe olubori.

"Ninu ala mi, mo ri ara mi ni ile Tinubu, ile nla ni, ti mo si n gbiyanju lati ri ni oju ala naa amọ mi o ri"

Ahmed to jẹ agbẹ oloko, to si wa lati idile to pọ, ṣalaye bi ohun ṣe bẹrẹ igbeṣẹ lati wa ri Tinubu.

O ni lọdun to kọja, lẹyin ti ojo rọ ni ọjọ kan ni oun sun, ti Ọlọrun si fi han oun pe Tinubu ni yoo bori ninu idibo sipo aarẹ to kọja lọ naa.

"Ninu ala naa, mo ri ara mi ni ile Tinubu, ile nla ni, ti mo si n gbiyanju lati ri ni oju ala naa amọ mi o ri.

Ẹlẹẹkeji ti mo tun la ala, ni nkan bi ọṣẹ̀ melo si eto idibo sipo aarẹ, ni mo ri ti wọn kede Tinubu gẹgẹ bi aarẹ, to si duro pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari."

Lẹyin naa lo ronu pe oun gbọdọ ṣe nkan to yẹ lori nkan ti oun ri, to si gbaradi lati wa ọkada wa si Eko lati wa ri Tinubu.

"Awọn eeyan mi yari pe ki n ma gbe iru igbeṣẹ bẹẹ lasiko yii amọ n ko gbọ"

Mallam Bello Ahmed tẹsiwaju pe ‘’Lasiko ti mo sọ fun awọn eniyan mi, wọn yari pe ki n ma gbe iru igbeṣẹ bẹẹ lasiko yii.

Wọn ni pe ki n duro ki wọn pari iburawọle fun Tinubu.

Amọ mi o sọ ala ti mo la fun ẹnikẹni."

Ahmed sọ fun akọroyin naa pe oun duro ni ipinlẹ kọọkan lati fi ara oun han ni awọn ọfisi ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn ipinlẹ ti oun n de.

O ni ni ipinlẹ Niger, ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti tun taya ọkada oun ṣe, ti wọn si n gboriyin fun oun ni mẹsan mẹsan.

''Ọjọ meje ni mo fi sun si ita ile Tinubu amọ ti wọn ko jẹ ki n ri"

Ahmed sọ fun akọroyin naa pe oun ko i tii ri Tinubu lẹyin ọjọ meje ti oun de si Eko.

O ni oun lọ si Bourdillion ni Ikoyi lati ri Asiwaju Tinubu amọ oun ko i tii ri.

‘’Ọjọ meje ni mo fi sun si ita ile Tinubu amọ ti wọn ko jẹ ki n ri.

Ọlọpaa kan fun mi ni ẹgbẹrun kan naira kan lati fi ra ounjẹ.

Bakan naa ni mo ri Seyi ọmọ Tinubu, to si fun mi ni ẹgbẹrun mẹwaa Naira.’’

Amọ mi o lee sọ boya Tinubu mọ pe mo wa ni iwaju ile rẹ, amọ mi o ni jẹ ki o rẹmi lati ri.

Ninu ọrọ rẹ, Ahmed ni nkan miran to tun wu oun ki oun ṣe ni ile aye ni lati darapọ mọ ikọ ologun ni Naijiria.

Bakan naa lo ni o tun wu oun lati wa kẹkẹ lo si Ilẹ mimọ ni Saudi Arabia.

Àkọlé fídíò, Brt-Train Accident: Grandma Oreoluwa ní ìlá alásepọ̀ ló ní òun máà se fún òun tó bá dé

Ọkùnrin tó fẹ́ fi kẹ̀kẹ́ ta Tinubu lọ́rẹ, ti gùn kẹkẹ fún ọjọ́ mẹ́wàá láti Plateau dé Ekiti

Alhaji Abdulahi Obodo ati kẹkẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Raheem Akingbolu/Facebook

Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ, Alhaji abdullahi Obodo ni ó kuro niluu Jos nipinlẹ Plateau ni ọjọ mẹwaa sẹyin lati lọ rí Aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu nilu Eko, ni o ti balẹ si ipinlẹ Ekiti bayi.

Obodo ni wọn ri bi o ṣe gun kẹkẹ rẹ kiri awọn abule ati ileto nipinlẹ Ekiti.

Nigba to n ba akọroyin kan sọrọ niluu Aramoko lọjọ Satide, Obodo ni oun kuro nipinlẹ Plateau ni ọjọ mẹwaa sẹyin pẹlu erongba lati ri Aarẹ tuntun, Bola Ahmed Tinubu niluu Eko, ko si fi kẹkẹ naa ta a lọrẹ.

Aworan Abdulahi Obodo

Oríṣun àwòrán, Raheem Akingbolu

Mo ti kọkọ gun kẹkẹ lati Naijiria lọ si Saudi Arabia laarin ọdun kan ati osu mẹwa - Obodo

"Orukọ mi ni Abdullahi Obodo. Mo wa lati ipinlẹ Plateau.

Emi ni ẹni naa to gun kẹkẹ lọ si Saudi Arabia ni aipẹ yii.

"Mo lo ọdun kan ati oṣu mẹwaa lati rin irinajo naa lọ ati lati padà.

"Ọpọlọpọ awọn eeyan lo fẹ ra kẹkẹ mi yìí ni ọpọlọpọ owo sugbọn mo kọ lati ta.

Idi ni pe mo ti pinnu pe maa fi ṣe ẹbun fun ẹnikẹni to ba borí ìdibo aarẹ Orilẹede Naijiria.

"Ìdí tí mo fi bẹrẹ irinajo lọ si ipinlẹ Eko nìyẹn lati lọ gbe kẹkẹ mi fun Asiwaju Tinubu.

"Oni lo pe ọjọ kẹwaa pẹlu agbara Ọlọrun Allah, maa de ipinlẹ Eko, ti maa si gbe kẹkẹ mi fun Asiwaju Bola Ahmed Tinubu."

Aworan Abdulahi Obodo

Oríṣun àwòrán, Raheem Akingbolu

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Tinubu, APC gbé amòfin àgbà SAN méjìlá kalẹ̀ nítorí ẹjọ́ tí Atiku, Obi nílé ẹjọ́

Aworan Tinubu ati atẹjade naa

Oríṣun àwòrán, APC/asiwajubolaahmedtinubu/twitter

Ẹgbẹ oṣelu APC ti gba amofina agba mejila, SAN lati mojuto ọrọ ẹjọ gbogbo to ba suyọ nipasẹ eto idibo sipo aarẹ eyi to waye lọjọ karundinlọgbọn oṣu keji ọdun 2023 ninu eyi ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti bori.

Ibo to din diẹ ni miliọnu mẹsan an(8,794,726 kaakiri ipinlẹ mejila ni Tinubu ni eyi to ku diẹ ko to miliọnu meji to fi lewaju igbakeji aarẹ nigbakanri, Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP to gbe ipo keji.

Ibo to din diẹ ni miliọnu meje (6,984,520) ni Atiku ni; nigbati Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu LP to ṣe ipo kẹta si ni ibo to le diẹ ni miliọnu mẹfa (6, 101,533)

Atiku ati Obi ti faake kọri pe awọn ko faramọ esi idibo naa ati pe awọn n gba ile ẹjọ lọ ni.

Amọṣa ẹgbẹ oṣelu APC to gbegba oroke ti sọ pe oun naa ṣetan lati pade awọn nile ẹjọ.

Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun, amugbalẹgbẹ lori ọrọ ofin fun igbimọ adari ẹgbẹ oṣelu APC, Ahmad Usman El-Marzuq fi ọrukọ awọn amofin mẹtala sita ninu eyi ti mejila wọn ti jẹ Amofin agba SAN.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Lara awọn eekan agbẹjọro to wa nibẹ ni Ọmọọba Lateef Fagbemi SAN ti yoo maa ko igbimọ naa sodi.

Awọn miran to wa ninu igbimọ agbẹjọro APC naa ni awọn amofin agba, SAN bii Sam Ologunorisa, SAN; Rotimi Oguneso, SAN; Olabisi Soyebo, SAN; Gboyega Oyewole, SAN; Muritala Abdulrasheed, SAN; Aliyu Omezia Saiki, SAN; Tajudeen Oladoja, SAN; Pius Akubo, SAN; Oluseye Opasanya, SAN; Suraju Saida, SAN pẹlu Kazeem Adeniyi , SAN.