Ìdí rèé tí ń kò fi le ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú olùdíje LP, Gbadebo Rhodes Vivour - Jandor

Oríṣun àwòrán, Collage
Oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Abdul-Azeez Olajide Adediran, ti ọpọ eeyan mọ si Jandor, ti sọ idi ti oun ko le fi ṣiṣẹ pọ pẹlu oludije lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Gbadebo Rhodes-Vivour.
Adediran sọ eleyii lasiko to n kopa lori eto kan lori ẹrọ tẹlifiṣan Arise.
Jandour ni awọn mejeeji ko lee jọ ṣiṣẹ pọ nitori Gbadebo Rhodes-Vivour ni ẹjọ meji lati jẹ ni ileẹjọ lọwọ lọwọ.
Gbadebo Rhodes-Vivour ń jẹ́jọ́ méjì lọ́wọ́ nílé ẹjọ́, à kò le ṣiṣẹ́ pọ̀ - Jandor
Jandor ni ohun ti oun sọ nigba ti Peter Obi pe oun ni pe, ko si ohun to le ninu ki oun ṣiṣẹ pọ pẹlu oludije Labour Party.
Amọ awọn ẹjọ to wa lọrun rẹ nile ẹjọ ni yoo mu ki oun kọ pe ki awọn ṣiṣẹ pọ.
‘’Nigba ti Peter Obi pe mi, ti Atiku Abubakar naa si pe mi lori ọrọ yii.
Peter Obi ni Atiku yoo pe mi, ti oun naa yoo si pe oludije ti Labour naa lati jọ jiroro boya awọn le ṣiṣẹ pọ.
Ohun ti mo sọ fun wọn ni pe, mi o ṣọpe mi o ni ṣiṣẹ pọ pẹlu Gbadebo Rhodes-Vivour amọ a ko gbọdọ fi asiko yii ṣere ayo pẹlu ẹni ti yoo jade gẹgẹ bi oludije.’’
‘’Amọ ohun ti ibaṣẹpọ wa ko ṣe le ṣiṣẹ pọ ni pe oludije keji ni ẹjọ meji ni ileẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria.
Ti a ba fi eto idibo yii tayo, o le bajẹ mọ wa lọwọ, nitori naa ni ko ṣe le e ṣeeṣe.''
Bakan naa ni Jandor fikun un pe, o ṣe ni laanu pe oun ko ni alatilẹyin laarin awọn agbagba ẹgbẹ oṣelu PDP.
O ni idi ni pe wọn n ṣe atilẹyin fun oludije ẹgbẹ oṣelu miran.
N150,000 ni owó oṣù òṣìṣẹ́ kan bí mo bá di gómìnà l’Eko - Gbadebọ Rhodes-Vivour
Oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Eko, Gbadebọ Rhodes-Vivour ti sọ pe bi oun ba lee wọle sipo gomina ni ipinlẹ naa, iye owo to kere julọ ti awọn oṣiṣẹ ọba yoo maa gba yoo kuro ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira
Ọgbẹni Rhodes-Vivour sọ pe oun yoo rii daju pe iye owo to kere julọ tawon oṣiṣẹ ijọba n gba nipinlẹ Eko di ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira.
Oludije fun ẹgbẹ oṣelu Labour naa seleri yii ninu fidio kan to fi sita.
O ni awọn eeyan kan ti n gbe iroyin kiri pe oun yoo da awọn oṣiṣẹ duro lẹnu iṣẹ ati pe ko si idi fun awọn oṣiṣẹ ijọba lati bẹru bi oun ba wọle.

Oríṣun àwòrán, Gbadebo Rhodes-Vivour/twitter
"Ko si idi fun oṣiṣẹ ijọba lati bẹru bi mo ba wọle, n ko ni da osisẹ kankan duro"
“Ni ọgọrun ọjọ akọkọ mi lori oye, mo maa gbe owo oṣu awọn oṣiṣẹ soke lati rii pe owo osu ti oṣiṣẹ n gba to o lati gbe igbe aye irọrun.
Pẹlu iṣiro wa, a rii pe ki eeyan to le gbe igbe aye to ṣe e dimu l’ Eko, o ni lati maa gba owo oṣu ti ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira.”
O ni eyi lee maa ṣeeṣe ni ibẹrẹ pẹpẹ, ṣugbọn maa rii pe mo ṣe e ni odun akọkọ.
O ni awọn to n ṣe owo ilu baṣubaṣu ni ipinlẹ Eko nikan lẹru lee maa ba nitori pe oun yoo gba gbogbo owo naa pada lati mu igbe aye irọrun burẹkẹ sii fun araalu.
















