"Iná ọba tó dé lójijì níbi iṣẹ́ mi, ló gé ọwọ́ mi méjéèjì"

Iṣẹ́ wa kò ní di ìṣẹ́ mọ́ wa lọ́wọ́ láṣẹ Èdùmàrè.
Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni Samuel Odugbesan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ NEPA tó ń ṣiṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan tó ṣẹlẹ̀ si.
Ní orí iná 11KV ni Samuel ti ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ lásìkò tí kò sí iná mọ̀nàmọ́ná àmọ́ tí wọ́n ṣàdédé múná dé ba níbẹ̀.
Láti ìgbà náà ni àyípadà ti bá ìgbé ayé Samuel nítorí iná tó gbe ní ọjọ́ náà ṣokùnfà kí wọ́n gé apá rẹ̀ méjéèjì.
Àti ìgbà náà ló ti di àkàndá ènìyàn èyí tí wọn kò bí mọ.
“Mo wà lórí òpó láti ṣiṣẹ́ lórí iná 11KVA gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ Nepa tí mo jẹ́, kò sì sí iná nígbà náà, wọ́n kàn dédé múná dé ní òjijì ni.”
“Nǹkan tí mo rí lẹ́yìn náà ni pé mo bá ara mi ní ilé ìwòsàn tí wọ́n sì ní àwọn máa gé apá mi tí mo bá fẹ́ wà láyé.”
"Mo yarí pé wọn kò ní gé apá mi, ìyá mi ló fọwọ́ lé mi ní éjìká tí mo fi gbà"
Samuel ṣàlàyé fún BBC pé nígbà tí òun gbọ́ ní ilé ìwòsàn pé wọ́n máa gé apá òun, òun fárígá pé kò sí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀.
“Àwọn ọ̀rẹ́ àti ìyá mi ló bá mi sọ̀rọ̀ pé ki ń gbà nítorí ki n le wà ní ààyè ni mo ṣe gbà pé kí wọ́n gé ọwọ́ mi.”
“Àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ fún mi pé ọwọ́ mi tí wọ́n máa gé kọ́ ni yóò ní kí n má jẹ́ ènìyàn láyé.”
“Kìí ṣe ohun tó rọrùn fún mi báyìí bí mi ò ṣe ní ọwọ́ méjéèjì mọ́ àmọ́ mò ń gbìyànjù láti gba nǹkan tó dé bá mi.”
“Ènìyàn tó ní ọwọ́ méjéèjì gan kò rọrùn láti ṣe gbogbo nǹkan ká tó wá ní èmi tí mi ò ní rárá.”

"Wọ́n ní kí n máṣe lọ sí ibi iṣẹ́ lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé èmi ni ń kò gbà"
Samuel Odugbesan fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ohun tó jọ òun lójú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé ó yẹ kí òun tẹ̀lé àwọn yòókù òun lọ sí òde kan ṣùgbọ́n òun pinnu láti lọ sí ibi iṣẹ́.
“Ó yẹ kí n lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan ní Abeokuta, kódà ọ̀kan lára àwọn ta jọ́ ń ṣiṣẹ́ ti wá wọ́ mi sínú ọkọ̀ àmọ́ mo kọ̀ láti lọ nítorí mo fẹ́ ṣiṣẹ́.”
“Ká ní mo mọ̀ wí pé irú nǹkan báyìí máa ṣẹlẹ̀ sí mi ni, mi ò bá ti tẹ̀lé wọn lọ sí Abeokuta.”
Bákan náà ló ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun pé nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí òun nítorí gbogbo nǹkan tí àwọn fi máa ń dá ààbò bo ara àwọn ní òun lò ní ọjọ́ náà.
“Ìbọ̀wọ́ 11,000 Volts ni mo lò, mo ní ìgbàgbọ́ pé ìbọ̀wọ́ tí mo lò náà ni kò jẹ́ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ju bó ṣe wà yìí lọ, bóyá mi ò bá ti kú tí kò bá sí ìbọ̀wọ́ ní ọwọ́ mi.”
“Ọ̀pọ̀ àwọn tí irú ìjàmbá báyìí bá ṣe ni kìí bọ́ nínú rẹ̀.
"Ẹsẹ̀ ni mo fi ń tẹ fóònù mi báyìí"
Samuel ní ìpèníjà ńlá ni òun ń kojú láti ìgbà tí wọ́n ti gé ọwọ́ òun méjéèjì.
Ó ní láti ilé ìwòsàn ni òun ti ń kọ́ láti máa lo ẹsẹ̀ òun láti máa fi tẹ fóònù òun àti láti fi ma gbé àwọn nǹkan tí kò bá wúwo.
Ó ní òun kò lè wẹ̀, jẹun, wọṣọ fúnra òun mọ́ láti ìgbà tí ìjàmbá náà ti wáyé.
“Àbúrò mi ọkùnrin lọ máa ń wọ aṣọ fún mi, fún mi ní oúnjẹ, wẹ̀ fún mi, ṣàndí fún mi tí mo bá yàgbẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
Samuel ní àwọn ẹbí òun lọ ń ran òun lọ́wọ́ tí wọ́n sì ń ṣe àtìlẹyìn fún òun láti ṣe gbogbo nǹkan.
“Gbogbo nǹkan tí mo bá fẹ́ ni wọ́n máa ń ṣe fún mi, mi ò sì lè dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi lórí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí mi, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó fún mi láàyè láti tún wà láyẹ”
“ Mo kàbámọ̀ pé mo lọ sí ibi iṣẹ́ lọ́jọ́ náà.”















