Abike Dabiri Erewa fèsì fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ní Ikorodu tó ń pariwo ‘kò sówó, kò síbò’

Abike Dabiri, ami idamọ APC ati afẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Collage

Àwọn oloṣelu to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC nilu Ikorodu nipinlẹ Eko, ti ke gbajare lori bi ẹgbẹ naa ṣe kọ lati mu adehun rẹ ṣẹ nipa ṣiṣan owo to yẹ fun wọn lasiko eto idibo aarẹ to kọja.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa, ninu fọnran aworan kan togba ori ayelujara kan, ni wọn ti faraya nitori owo iṣẹ ti wọn ṣe fun ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo aarẹ to kọja amọ ti wọn ko ri owo rẹ gba.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu Labour Party lo jawe olubori ninu ibo aarẹ nipinlẹ Eko, amọ ibo ti ẹgbẹ oselu APC ri ni agbegbe Ikorodu pọ pupọ.

Ọkan ninu awọn eeyan to fi ẹhonu han naa ni agbegbe naa ni oun ti ṣiṣẹ ni Ikorodu, to si jẹ ọkan lara awọn agbegbe ti oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oselu APC, Bola Tinubu, ti rí ibo to pọju lọ.

O ni iṣẹ tawọn se lasiko eto idibo ni lati pe awọn ara adugbo jade wa dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC ni Ikorodu.

Obinrin naa ni bo tilẹ jẹ wi pe inu ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn bi oun si, oun ko tii jẹ adun ẹgbẹ oṣelu naa rara.

O fikun pe bẹẹ iṣẹ ti oun se fun ẹgbẹ naa ninu eto idibo to kọja, owo rẹ ni wọn jẹ oun, ti oun si fẹ gbaa.

Awọn olufẹhonuhan naa wa leri leka pe ti wọn ko ba san owo awọn ki eto idibo gomina to waye lọjọ Satide, awọn ko ni gba ki eto idibo waye nilu naa.

Wọn fikun pe ko sowo, ko sibo ni awọn yoo fi ọrọ naa se lọjọ idibo.

Ikede ti Abike Dabiri Erewa se ni Twitter

Oríṣun àwòrán, Abike Dabiri-Erewa

A wọn ti ọrọ kan ti kan sawọn olupolongo ibo ni Ikorodu, ọrọ naa ti yanju - Abike Dabiri-Erewa

Wayi o, Oludamọran si aarẹ Muhammadu Buhari fọrọ awọn eeyan to wa nilẹ okeere, Abike Dabiri Erewa ti fesi si ifẹhonuhan awọn eeyan naa.

Dabiri, tii se eekan kan ninu ẹgbẹ oselu APC lagbegbe Ikorodu, ti wa gbe ikede kan nipa isẹlẹ naa soju opo Twitter rẹ lasiko to n fesi si ẹnikan to pe akiyesi rẹ si ẹhonu awọn olupolongo ibo naa.

Ninu ikede naa, Abike Dabiri Erewa ni asise kan lo waye nidi kikan si awọn olupolongo ibo fun ẹgbẹ oselu naa lẹyin ibo.

O wa fi ọwọ gbaya pe wọn ti kan si awọn eeyan naa, ti wọn si ti yanju gbogbo aawọ naa patapata.