Oṣù mẹ́fà sẹ́yìn ni mo ti ń bá àìlera fínra, ẹ yé bú mi mọ́ pé mo rù - Ronke Oshodi Oke

Ronke Oshodi Oke

Oríṣun àwòrán, ronkeoshodioke/Instagram

Gbajúgbajà òṣèré tíátà nnì, Ronke Ojo, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ronke Oshodi Oke ti rọ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti yé sọ òdì ọ̀rọ̀ sí òun mọ́ nítorí bí òun ṣe rù.

Oshodi Oke nínú fídíò kan tó fi sórí ayélujára Instagram rẹ̀, fi àìdùnnú rẹ̀ hàn lórí bí àwọn ènìyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ si lórí bó ṣe rù, tí àwọ̀ ara rẹ̀ ko si jọlọ lẹnu ọjọ mẹta yii.

Ó ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò mọ ohun tí òun ń bá fínra láti bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn èyí tó ṣokùnfà bí òun ṣe ń fi ojoojúmọ́ rù.

"Ṣé torí mi ò gbé ara mi wá sórí Facebook láti tọrọ owó lẹ ò ṣe mọ̀ pé nǹkan ń ṣe mí"

Gbajúmọ̀ òṣèré náà tẹ̀síwájú pé kìí ṣe oògùn tàbí àgbo kankan ló jẹ́ kí òun rù báyìí àmọ́ bíkòṣe nǹkan tí òun ń là kọjá.

Ó fi kun pé láti oṣù mẹ́fà ni òun ti ń bá àìlera kan fínra èyí tó fà á ti òun fi ń rù.

“Ṣé nítorí mi ò gbé ara mi wá sórí Facebook láti wá tọrọ owó lẹ ò ṣe mọ̀ pé nǹkan ń ṣe mí”

“Ṣé tí mo bá máa darúgbó, ṣé láàárín oṣù mẹ́fà ni?”

“Nǹkan tó jẹ́ kí n máa rù ó wà lára mi, èmi ni mo mọ̀ ọ́n, Ọlọ́run náà ló mọ̀-ọ́n.”

"Ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fi ọ̀rọ̀ wọn pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ láìmọ̀"

Ronke Osodi Oke

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Bákan náà ló ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà láti yé bú ènìyàn lórí ayélujára láì mọ ìṣòro tí wọ́n ń là kọjá.

Oshodi Oke ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ni àwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ òdì sí ènìyàn lórí ayélujára ti fi ọ̀rọ̀ wọn ṣàkóbá fún láìmọ̀.

Ó ní ó dára láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹlòmíràn kó tó di wí pé wọ́n kàn máa sọ nǹkan tí ẹnu wọn bá bá.

Ó sọ wí pé ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń bu òun náà má le la ìṣòro tí òun ń kojú já btó bá jẹ́ wí pé àwọn ni wọ́n ń dojúkọ irú ìṣòro tó ń bá òun fínra.

Àgbà òṣèré náà ní kí ó yẹ kí gbogbo àwọn tó máa ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń kọ nígba mìíràn ti ṣokùnfà ikú láìmọ̀.

Bákan náà ló ní àwọn tí kò bá nífẹ̀ẹ́ òun pọ̀ sókè rajà kí wọ́n yé kọ àwọn nǹkan tí kò da sórí ayélujára fún òun mọ́.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post