Wo bí ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn láàrin Oyetola àti Adeleke ṣe wáyé

Oyetola and Adeleke

Oríṣun àwòrán, Afolabi Henry Adedapo

Ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Abuja ko tii kede ọjọ ti yoo da ẹjọ ti gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, pe tako idajọ igbimọ to n gbọ ẹsun awuyewuye ibo gomina nipinlẹ Osun.

Ọjọ Kẹsan an, oṣu Keji, ọdun 2023 yii ni Adeleke pe ẹjọ ọhun lẹyin ti igbimọ to n gbọ awuyewuye to waye lasiko isibo gomina Osun kede pe Adegboyega Oyetola lo bori ibo gomina to waye lọdun 2022.

Adeleke wa n bẹ ile ẹjọ kotẹmilọrun naa pe ko da idajọ igbimọ ọhun nu.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni igbimọ to gbọ ẹjọ naa l’Osun ti kọkọ sọ pe iye ibo ti wọn di lawọn ibudo idibo kan kere ju iye esi ibo to jade lawọn ibudo idibo naa lọ.

Eredi ree ti meji ninu igbimọ ẹlẹni mẹta to gbọ awuyewuye naa fi fẹnuko pe Oyetola lo jawe olubori ninu eto idibo ọhun.

Amọ lẹyin ọsẹ diẹ si, ni Adeleke pe ẹjọ kotẹmilọrun ni ẹka ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Akure tako idajọ igbimọ naa.

“Go lo lo lo ati Buga wọn" ti igbimọ naa ṣọ ninu ẹjọ rẹ ko jẹ ki idajọ rẹ ni gbongbo”

Adeleke ni oun n fẹ ki ile ẹjọ naa da idajọ igbimọ naa nu.

Gomina ọhun fi kun pe ‘go lo lo lo’ ati ‘buga wọn’ ti igbimọ ọhun lo ninu idajọ rẹ fi han pe, wọn fi si apa kan ju apa keji lọ.

O ni “Igbimọ naa, ninu idajọ rẹ tako ofin, o si fi iha to fi si han bo ṣe mẹnuba bi gomina ọhun ṣe jo lasiko iburawọle rẹ gẹge bii gomina Osun.”

“Niwọn igba ti igbimọ naa ti mẹnuba ijo rẹ, igbimọ ọhun mọọmọ fi gomina naa ṣe ẹlẹya ni, eyii to fi han pe wọn tako o.”

“Bi igbimọ to dajọ ọhun ṣe mẹnuba ijo rẹ, paapaa ijo Buga, ko jẹ ki idajọ rẹ ni gbongbo mọ.”