Èèyàn 30 ló kù nílé ìwòsàn lára àwọn tó wà níńú bọ́ọ̀sì BRT tó kọlu rélùwéè l'Eko

Aworan bọọsi BRT to forigbari pẹlu reluwe

Iye awọn to ti kuro ni ile iwosan lara awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to wa ninu bọọsi BRT to forigbari pẹlu reluwe lọsẹ to kọja nilu Eko ti di mẹrindinlaadọrin bayii.

Eeyan mẹfa lo ku, ti mẹtadinlọgọrun miran si farapa loriṣiriṣi lowurọ ọjọbọ ọjọ kẹsan oṣu kẹta ọdun 2023 nigba ti awakọ bọọsi kan to n ko awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko lọ si iṣẹ wọn, fi aigbọran ko si oju irin reluwe to n kọja ti reluwe naa si kọluu.

Oniruuru iṣẹ abẹ ni wọn ṣe fawọn to nilo rẹ laarin awọn to farapa - Ijọba Eko

Kọmiṣọna fun eto ilera ni ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi ṣalaye loju opo Twitter rẹ pe, lẹyin awọn eeyan mẹfa to ku lọjọ ti iṣẹlẹ buruku naa ṣẹ, ko si ẹnikẹni ninu awọn oṣiṣẹ naa ti wọn tun padanu mọ lawọn ile iwosan naa.

O ni oniruuru iṣẹ abẹ ni wọn ti n ṣe fun awọn to nilo rẹ laarin wọn ni ile iwosan nla LASUTH nilu Eko lati lee ri pe gbogbogb wọn ni ara wọn ya lasiko.

Nibayii iye awọn to ṣi wa labẹ itọju ni ile iwosan jẹ ọgbọn; mẹrindinlọgbọn ninu wọn lo wa ni ile iwosan nla LASUTH, meji wa ni ile iwosan ijọba ni Lagos Island, meji miran si wa ni ile iwosan ijọba to wa ni Gbagada.

Àkọlé fídíò, Brt-Train Accident: Grandma Oreoluwa ní ìlá alásepọ̀ ló ní òun máà se fún òun tó bá dé

Awakọ̀ BRT ṣubú lulẹ̀ ní ágọ́ ọlọ́pàá, ó dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tó kó sẹ́nu rélùwéè l‘Eko

Ọkọ̀ BRT tó ní ìjàmbá pẹ̀lú ọkọ̀ ojú irin

Awakọ̀ tó wa ọkọ̀ BRT tó ní ìjàmbá pẹ̀lú ọkọ̀ oju irin ní ìpínlẹ̀ Eko ti wà ní ilé ìwòsàn.

Ìròyìn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni wọ́n gbé Oluwaseun Osinbajo dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn tó ṣàdédé ṣubú lulẹ̀ ní àhámọ́ ọlọ́pàá tó wà.

Wọ́n ní awakọ̀ náà ló ní ìfarapa nínú ikùn rẹ̀ láìmọ̀, tí ẹ̀jẹ̀ sì ń dà nínú rẹ̀ àmọ́ kò farahàn títí di ìgbà tí wọ́n gbe dé ilé ìwòsàn níbi tí àyẹ̀wò ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

"Awakọ̀ BRT wà lẹ́ka ICU fún ìtọ́jú aláìsàn tó bá lágbára lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ"

Títí di àsìkò yìí kò ì tíì sí ìròyìn mìíràn lórí ipò tí ìlera awakọ̀ náà wà báyìí.

Ẹ ó rántí pé wọ́n ní ìwàkuwà Osinbajo ló sokùnfà bí ọkọ̀ tó wà ṣe forí sọrí pẹ̀lú ọkọ̀ ojú irin ní agbègbè PWD, Ikeja, tí ènìyàn mẹ́fà sì pàdánù ẹ̀mí wọn, tí ọ̀pọ̀ si farapa nínú ìkọlù ọ̀hún.

Ẹni tó fìdí ìròyìn yìí múlẹ̀ ní ilé ìwòsàn Federal Medical Centre (FMC) tó wà ní reluwé agbègbè Yaba ni wọn gbé awakọ̀ náà lọ fún ìtọ́jú.

Bákan náà ló ní wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ fún-un ní ojú ẹ̀sẹ̀ láti fi dóòlà ẹ̀mí rẹ̀ tó sì ti wà ní ẹ̀ka tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá lágbára púpọ̀ ìyẹn ICU ní ilé ìwòsàn náà.

Ọmọ mi ń múra láti lọ kàwé ní UK, kó tó pàdé ikú òjijì nínú BRT – Bàbá Oreoluwa Aina

Agunabnirọ to ku ninu ijamba BRT

Oríṣun àwòrán, Oreoluwa Aina

Wọn ti sin oku Oreoluwa Aina, agunbanirọ to jẹ ọkan lara awọn to jade laye lẹyin ijamba ọkọ BRT ati ọkọ oju irin niluu Eko.

Pẹlu omije loju lawọn mọlẹbi, ojugba, ọrẹ atawọn aladugbo rẹ fi ṣe ẹyẹ ikẹyin fun oloogbe naa.

Oloogbe naa wa lara awọn eeyan mẹfa to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa, to kan awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko, lagbegbe PWD, ni Ikeja.

Oloogbe naa jẹ ọkan lara awọn agunbanirọ to n ṣiṣẹ nileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko, eyii to n ri si ọrọ eto ẹkọ ni Alausa.

Gomina Babajide Sanwo-Olu atawọn oṣiṣẹ rẹ ti ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn mọlẹbi oloogbe ọhun.

Lagos BRT accident

Oríṣun àwòrán, others

Ọwọngogo owo naira lo mu ki ọmọ mi wọ ọkọ BRT naa – Baba Oloogbe

Ẹwẹ, baba oloogbe naa, Femi Aina ti sọ pe ọwọngogo owo naira lo mu ki ọmọ oun lọ wọ ọkọ BRT naa ko to pade iku ojiji.

Ọgbẹni Aina lo sọ ọrọ naa ninu irora iku ọmọ rẹ.

O ni “Ti ko ba n ṣe ti ọrọ owo ti wọn ko pamọ yii ni, ọmọ mi ko ba ma ti wọ ọkọ naa.”

“Amọ nitori ko si owo lọwọ rẹ lo ṣe tẹlẹ bọọsi ọhun.”

Baba oloogbe naa ṣalaye siwaju si pe ilu Abuja loun wa ti oun ti n wo ẹrọ amohunmaworan ni nnkan bii aago mẹsan owurọ ti oun gbọ nipa ijamba naa.

Oreoluwa Aina

Oríṣun àwòrán, @SamuelOmogor

O ni lẹyin naa loun gba ipe lori aago pe ọmọ oun wa lara awọn ti iṣẹlẹ ọhun kan.

Aina sọ siwaju si pe “Lẹsẹ kan naa ni mo pe awọn aburo mi ti wọn wa l’Eko... lẹyinorẹyin, mo gbọ pe o ti wa ni ẹka pajawiri, ICU.”

Nigba to n sọrọ npa ibaṣepọ rẹ pẹlu oloogbe ọhun, o ni “Ẹbun Ọlọrun si mi lati ọrun ni, o si ṣe pataki si mi pupọ.”

“O bẹru Ọlọrun, ko si n fi iṣẹ rẹ ṣere rara.”

“Ọmọ mi n mura lati lọ kawe siwaju ni UK ṣaaju ijamba ọkọ naa”

Baba oloogbe naa tẹsiwaju pe oloogbe ọhun sọ erongba rẹ fun oun ṣaaju iku rẹ.

O ni “O sọ ọpọlọpọ erongba rẹ fun mi, o pinnu lati lọ kawe gboye Masters rẹ nilẹ Gẹẹsi...”

“O jẹ ọmọ to ja fafa ninmu gbogbo ohun to ba n ṣe... o n da ajọ kan nibi to ti n fowopamọ, eyii ti yoo fi bẹrẹ ounjẹ tita.”

“Ọpọlọpọ nnkan lo gbiyanju lati ṣe, o tun maa n kọ orin, ko si fi Ọlọrun ṣere.”

Baba ọmọ naa pari ọrọ rẹ pe inu oun ko dun si awakọ to wa ọkọ akero BRT naa, ati pe oun si n reti ki ijọba wa ojutu si ọrọ awọn awakọ ọhun ipinlẹ Eko.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Ìgbà márùn-ún ni mo fi aṣọ pupa kìlọ̀, fọn fèrè fún Dẹrẹba BRT àmọ́ kò dáhùn - Òṣìṣẹ́ rélùwéè

Aworab oko BRT

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

Ọkan lara awọn osisẹ ileeṣẹ ìjọba to n risi akoso oju irin to wa nibi isẹ lasiko ti ijamba waye laarin reluwee ati ọkọ BRT nilu Eko ti sọrọ soke nipa isẹlẹ naa.

Arakunrin naa to kọ lati darukọ rẹ fun awọn akọroyin salaye pe oun ni oun wa lẹnu isẹ lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye, ọkunrin naa ni igba marun-un ọtọtọ ni oun ni ki Dẹrẹba BRT to ni ijamba naa duro fun reluwee lati kọja sugbọn ko da oun lohun rara.

O ni " N ṣe ni mo bẹrẹ si ni ma fi aṣọ pupa fi ṣe ikilọ, fọn fere, tí mo kígbe pe ki Dẹrẹba naa mase gbinyanju lati sọda sugbọn o kọ lati da mi lohun.

"Ko si ẹnikẹni to le ni n ko se iṣẹ mi, ti wọn ba ke si mi níbikibi pe ki n wa wi tẹnu mi, mo maa de bẹ nítorí awọn Dẹrẹba ko ki n gbọrọ rara."

''Àwọn Dẹrẹba BRT kii ni suuru, ọpọ igba ni a ti ja''

Osisẹ BRT naa tẹsiwaju pe ọpọ awọn Dẹrẹba BRT ni wọn ko ki ni suuru ti wọn ba sọda loju irin naa.

O ni ti oun ba ke si wọn, wọn maa ta omi si oun lara tabi sọrọ odi sì oun ti wọn ba kọja.

"Lọjọ kan, ọkan ninu wọn ta a omi sí mi lara nítorí mo ṣe ikilọ lori ewu to wa niwaju rẹ to le gba ẹmi rẹ.

"Ko da mi lohun. Nnkan to dùn mi pe awọn eeyan wa ninu bọọsi naa, to ba jẹ awakọ yẹn nìkan ni, ko si nnkan to kan mi

''Ti Reluwee ba n kọja, ilẹ maa mi''

Osisẹ NRC tẹsiwaju pe ko si bí eeyan ṣe fẹ fi nnkan di eti to, yoo mọ pe reluwee wa ni tosi nitori ilẹ maa n mi.

"Ko si nnkan to ti bọ eti ṣe dun to, ti Reluwee ba n bọ, ilẹ maa mi. Gbogbo wa laa mọ.

"Ki lo de to fi fẹ salọ nigba ti iṣẹlẹ naa waye, to si fẹ fi awọn eeyan silẹ ninu ọkọ naa lati ku. Ki lo de?

Dẹ́rẹ́bà BRT tọ̀rọ̀ aforijin lọ́wọ́ àwọn tó farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ àti rélùwéè

Dẹrẹba ọkọ ijọba ipinlẹ Eko to sokunfa bi ọkọ BRT ṣe kọlu ọkọ reluwee ni agbegbe ojurin PWD/ Shogunle loju ọna Agege motor niluu Eko, tí rọ awọn to ninu bọọsi akero, to lugbadi ijamba kan tabi omiran lati diriji oun.

Tí a ko ba gbagbe, awọn eeyan kan ti orí ko yọ ninu iṣẹlẹ ijamba naa fẹsun kan Dẹrẹba naa, ti orukọ rẹ jẹ Oluwasegun Osinbajo pe o fi nnkan di eti, to si kọ lati gbọ lọwọ awọn ẹsọ oju popo.

Dẹrẹba ni kudiẹkudiẹ to wa lara ọkọ bọọsi akero BRT lo fa ijamba.

"Ko ki n ṣe ẹjọ mi rara. Bawo ni maa ṣe kọ etí kun si ipe yẹn? Bọọsi ni isoro

"O ṣe ni ni laanu pe iṣẹlẹ naa waye. Mo rọ gbogbo to lugbadi ijamba yii pe ki wọn dari jin mi, mo kabamọ nínú iṣẹlẹ ijamba naa."

Ki lo waye saaju?

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, ti fidi rẹ mulẹ pe bọọsi kan to jẹ ọ́kọ́ ijọba ipinlẹ Eko ni ọkọ̀ oju irin reluwe kan kọlu to si gbe hanu titi to fi rin gbẹẹrẹ lati agbegbe Ikeja titi de agbegbe Shogunle ni ipinlẹ Eko.

Oludari ẹka iha Iwọ Oorun-Guusu Naijiria, Ibrahim Farinloye sọ fun BBC Yoruba atawọn oniroyin to wa nibi iṣẹlẹ naa pe iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ ti di mẹfa bayii.

O ṣalaye pe eeyan meji ti ku tẹlẹ lati ibi iṣẹlẹ naa, kete ti wọn gbe gbogbo awọn to farapa de ileewosan LASUTH ni awọn mẹrin mii ku.

Nigba ti wọn kọkọ wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, aṣoju ajọ LASEMA ti kọkọ sọ pe ohun ti awọn ba nibẹ ni pe ọkunrin kan ati obinrin meji lo ti ku, amọ nigba ti ikọ to ko awọn to fara pa lọ ileewosan yoo fi de ibẹ, wọn gba iroyin pe iye awọn to ku ti di mẹfa.