Afurasí méjì tó ń fọnrere wàhálà ṣáájú ìbò gómìnà wọ gàù

awọn oṣiṣẹ alaabo

Oríṣun àwòrán, dss

Ileeṣẹ alaabo DSS lorilẹede Naijiria ni awọn ti fi panpẹ ofin mu awọn arakunrin meji kan, Sharu Tabula ati Isma’il Mangu lori ẹsun pe wọn n fẹ da wahala silẹ nipinlẹ Kano.

Ileeṣẹ alaabo DSS ni awọn afurasi naa n pin akasilẹ fidio kan lori ayelujara, ninu eyi ti wọn ti n pe awọn ololufẹ wọn lati kọlu ẹnikẹni to ba dibo tako ẹgbẹ oṣelu wọn.

"Ẹnikẹni to ba di ẹgbẹ NNPP lọwọ yoo rugi oyin"

Ninu awọn ọrọ ti wọn n pin kiri naa, DSS sọ pe awọn afurasi naa, ni wọn n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu kan ni ipinlẹ Kano.

O ni wọn n ke si awọn ọmọlẹyin wọn pe ki wọn dide kọlu awọn agbofinro pẹlu ti wọn ba woye pe o n ṣiṣẹ to le di awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lọna lasiko idibo gomina ati ile aṣofin ipinlẹ ti yoo waye lọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023.

Ajọ DSS ni gbogbo igbesẹ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan lati ṣe iwọde lọ sawọn ileeṣẹ ajọ alaabo gbogbo ni ipinlẹ Kano nitori awọn afurasi ti wọn mu naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

DSS fi idaniloju han pe oun ko ni gba ki ki ẹgbẹ kan da wahala silẹ

“Ileeṣẹ DSS wa ti jẹ ko di mimọ fun araalu pe, iwa irufin patapata ni igbesẹ ti wọn n pinnu naa.

O wa n ke si ẹgbẹ oṣelu ti ọrọ kan lati ṣẹwe le igbesẹ yii, bibẹẹkọ, wọn yoo fimu ko ata ofin.

Ileeṣẹ alaabo DSS tun fi idaniloju han pe awọn ko ni la oju awọn silẹ ki awọn kọlọransi ẹda tabi ẹgbẹ kan maa da omi alaafia ati abo ipinlẹ naa ru.

Ninu ọkan lara awọn fidio naa, ni ọkan lara awọn afurasi ọhun ti n ke si awọn ọmọlẹyin wọn atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NNPP ni ipinlẹ Kano pe ki wọn maṣe gba gbẹrẹ fun ẹnikẹni ti ko ba tẹlẹ ilana oṣelu ‘Kwankwasiya’ti wọn duro fun.

Arakunrin naa ni ki wọn kọlu gbogbo eeyan tabi agbofinro to ba fẹ di wọn lọwọ lasiko idibo sipo gomina ati ile aṣofin ipinlẹ ni ipinlẹ Kano lọjọ Satide.