Wo ipò tí IPOB, Boko Haram àti ISWAP wà láàrin agbésùnmọ̀mí àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Collage
Ajọ to n se akọsilẹ igbesunmomi lagbaye, Global Terrorism Index ti fi orukọ ikọ ologun IPOB si ara awọn ẹgbẹ alakatakiti to wa lagbaye.
Ikọ agbebon IPOB lo wa ni ipo kẹwa bayii ti ikọ agbebọn Boko Haram ati ISWAP naa ko si gbẹyin ninu akọsilẹ wọn.
Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ Global Terrorism Index lọdun 2022 se wi, ikọ ologun IPOB ṣe ọpọ ikọlu si awọn eeyan.
Koda, eniyan mẹtadinlọgọta lo padanu ẹmi wọn ninu awọn ikọlu wọn, eeyan mẹrindinlogun si lo farapa ninu ikọlu ogoji ti wọn ṣe.
Ninu awọn ikọlu naa ni wọn ti sekupa tọkọ taya osisẹ ologun, ti wọn si tun bẹ ori wọn ati ọpọ awọn ara ariwa orileede yii pẹlu awọn osisẹ alabo ti wọn sekupa.
Ajọ naa ni iṣẹlẹ isekupani latọwọ awọn agbesunmọmi dinkun pẹlu ida mẹsan si ẹgbẹrun mẹfa le ni ọkanlelẹẹdẹgbẹrin, eyi to din pẹlu ida mejidinlọgbon si igba.
Bẹẹ ni ọpọ eeyan padanu ẹmi wọn latara ogun igbesunmọmi ni ọdun 2015.

Akọsilẹ ajọ Global Terrorism Index fi han pe Afrika ni igbesunmọmi ti pọ julọ ni agbaye lọdun 2022
Akọsilẹ ajọ naa ni ikọ agbebon Boko Haram ni o lewu julọ ninu awọn ikọ alakatakiti naa, ti wọn si wa ni ipo keje lagbaye.
Eeyan mẹrinlenigba lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ mẹrinlẹlọgọta ti ikọ Boko Haram se, ti eeyan mọkanlẹlaadọta si farapa.
Ni ẹkun Iwọ oorun Afrika Ikọ alakatakiti ISWAP lo ṣiwajui ẹgbẹ ologun to lewu julọ pẹlu ikọlu to le ni ọgọta ti eeyan to le ni igba padanu ẹmi wọn eeyan ejidinlọgọta farapa ninub awọn ikọlu naa.
Akọsilẹ ajọ Global Terrorism Index fi han pe apa ilẹ olooru Afrika ni isẹlẹ igbesunmọmi ti pọ julọ lọdun 2022 lagbaye.

Oríṣun àwòrán, ScreenGrab
Orilẹede meji,Burkinafaso ati Mali ko ida ẹtadinlaadọrin lagbaye ninu awọn isekupani to waye ni agban ile olooru Afrika lodun 2022,awọn ikọlu yii ti n tan ka si orilẹede Togo ati Benin.
Ọdun 2017 ni ijọba orilẹede yii kede ikọ IPOB gẹgẹ bi ikọ alakatakiti,Boko Haram ni ọdun 2013.
Ninu ikọ Boko Haram ni ẹgbẹ ISWAP ti jade.















