Wo bí o ṣe lè mọ ibùdó ìdìbò tó yẹ kí o ti dìbò

Oríṣun àwòrán, inec
Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC yoo tun ṣe eto idibo si ipo gomina ati ijoko ile igbimọ aṣofin ipinlẹ lọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023.
Ibo gomina yii lo n waye lẹyin ti INEC ṣe eto idibo si ipo aarẹ ati ijoko ile igbimọ aṣofin apapọ lọjọ karundinlọgbọn oṣu keji ọdun 2023.
Ireti wa si ni pe ọpọ awọn oludibo lo tun ṣeeṣe ko jade wa dibo lasiko idibo naa.
Saaju ni ajọ INEC naa ti sun eto idibo gomina yii siwaju kuro niSatide ọjọ Kọkanla si Satide ọjọ Kejidinlogun osu Kẹta ọdun 2023.
Eyi ko si sẹyin awọn atako kan ti ajọ naa ri lọdọ awọn ẹgbẹ oselu to n fapa janu lori esi ibo aarẹ to kọja, ti wọn gbe INEC lọ sile ẹjọ.
Awọn ipinlẹ wo ni idibo si ipo gomina yoo ti waye?
Ipinlẹ mejidinlogun ni ireti wa pe idibo gomina yoo ti maa waye.
Gbogbo ipinlẹ to wa ni ẹkun ila oorun ariwa ati iwọ oorun ariwa lapa oke ọya Naijiria ni idibo naa yoo ti waye.
Bakan naa ni idibo yii yoo tun waye ni gbogbo awọn ipinlẹ to wa lẹkun aringbungbun ariwa yatọ si ipinlẹ Kogi.
Ni ẹkun iwọ oorun gusu Naijiria, ipinlẹ Ekiti, Ondo ati Ekiti ko ni ṣeto idibo sipo gomina.
Bẹẹ si ni ibo gomina ko ni waye ni ipinlẹ Bayelsa, Edo lẹkun aringbungbun gusu Naijiria ati ipinlẹ Anambra ni ẹkun ila oorun gusu Naijiria.

Oríṣun àwòrán, other
Eto idibo sile asofin lawọn ipinlẹ ati ibo lati yan alaga ijọba ibilẹ ni Abuja yoo waye pẹlu
Amọṣa, awọn eto idibo si ijoko ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ni awọn ipinlẹ wọnyii yoo waye.
Eyi ni awọn ipinlẹ ti eto idibo sipo gomina yoo ti waye ni Abia, Adamawa, Akwa Ibom, Bauchi, Benue, Borno, Cross river, Delta, Ebonyi, Enugu, Ati Gombe.
Bakan naa ni ibo gomina yoo waye ni ipinlẹ Imo, Jigawa, Kaduna, Kano, Katsina, Kebbi, Kwara, Eko, Nasarawa, Niger, Ogun, Ọyọ, Plateau, Rivers, Sokoto, Taraba, Yobe ati Zamfara.
Bẹẹ ni idibo ọjọ Abamẹta yoo tun waye lati yan awọn alaga ibilẹ tuntun ati kansilọ lawọn ẹkun agbegbe mẹfa ni olu ilu Naijiria, Abuja - Abaji, Abuja Municipal, Bwari, Gwagwalada, Kuje ati Kwali.
Bawo lo ṣe le da ibudo idibo rẹ mọ lasiko idibo lọjọ Satide?
Ajọ INEC ti mu afikun ba iye awọn ibudo idibo to wa ni Naijiria lati ẹgbẹrun lọna ọgọfa o din diẹ (119,974) lọdun 2019 si ẹgbẹrun mẹtadinlọgọsan o din diẹ (176,846).
Ajọ INEC ti rọ ọpọ awọn eeyan lati ṣe awari ibudo idibo wọn ki ọjọ idibo to pe.
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ awọn eeyan lo ti ri ibudo idibo wọn ti wọn si dibo lasiko idibo si ipo aarẹ to waye lọsẹ meji sẹyin, sibẹ ọpọ lo fi ẹsun kan pe awọn ko ri orukọ awọn ni ibudo idibo ti awọn fi ọkan si pe awọn wa ṣaaju idibo naa.

Oríṣun àwòrán, screenshot
Wo awọn igbesẹ to yẹ ki o gbe lati mọ ibudo idibo rẹ lọjọ idibo gomina
Eyi ni awọn igbesẹ to yẹ ki o gbe lati mọ ibudo idibo ti o yẹ ki o tidibo lọjọ idibo gomina ipinlẹ ti yoo waye lọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun 2023.
Igbesẹ akọkọ: Lọ si oju opo ayelujara INEC ni inecnigeria.org tabi inecnigeria.org
Igbesẹ keji: lo iwe ori ayelujara to wa nibẹ lati fi ṣe awari ibudo idibo rẹ tabi ipo rẹ gẹgẹbi oludibo.
Igbesẹ kẹta: Lati mọ ọna lati de ibudo idibo rẹ, tẹ ila alawọ eweko to wa nibẹ.
Igbesẹ kẹrin: lo aworan afinimọna maapu to wa nibẹ tabi ilana atọnisọna lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ lati mọ ibi ti o yẹ ki o ti dibo.















