Olùkọ̀ àgbà lé akẹ́kọ̀ọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó fi ìwé àwòràn ìbò Peter Obi ṣe ìpolono ìbò
Aworan kan lo gba ori ẹrọ ayelujara kan nibi ti olukọ agba ni ileẹkọ girama ti paṣẹ fun akẹkọọ lati gba ile rẹ lọ lori ẹsun pe oun ṣe ipolongo fun oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi.
Iṣẹlẹ naa ni wọn ni lo waye ni ileẹkọ Odomola Junior Secondary school ni agbegbe Epe, nipinlẹ Eko.
Akẹkọọ ọmọ ọdun mẹwaa naa ni wọn fi ọwọ osi juwe ile fun nitori o fi iwe ipolongo Peter Obi bo iwe rẹ.

Oríṣun àwòrán, LASG

Lẹyin naa naa ni olukọ agba naa fun ni ni iwe ‘lọ gbe ile rẹ’, to si buwọ lu u.
Ninu iwe pelebe to fun ọmọ naa ni wọn kọ ọ si pe;
‘’Ọmọdebinrin Barinada Marvelous to wa ni ipele keji ni ileẹkọ girama, ni a gba laaye lati maa lọ si ile rẹ.
A fẹ ki o lọ maa ṣe ipolongo ibo fun Peter Obi, eyi to lodi si ifẹ awọn ara Eko.’’

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ijọba ipinlẹ Eko fesi pe iwadi ti bẹrẹ lori isẹlẹ naa
Ileeṣẹ ijọba to n risi eto ẹkọ nipinlẹ Eko ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iroyin ti obi kan fi lede lori bi wọn ṣe le ọmọ rẹ kuro ni ileẹkọ.
Kọmiṣọnna fun Eto ẹkọ, Abilekọ Folasade Adefisayo ni awọn ti fi iwe ipẹjọ ranṣẹ si olukọ agba ileẹkọ naa lati wa ṣalaye bi ọrọ naa ṣe jẹ.
Adefisoye ni ijọba ipinlẹ Eko tabi ileeṣẹ ijọba kankan ko ni paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ wọn lati hu iwa aitọ yii ni agbegbe wọn.
O ni ohun to lodi si ofin ni ki oṣiṣẹ tabi olukọ fi ero rẹ han lori oṣelu tabi ṣe ipolongo idibo fun ẹnikẹni.
Ijọba ipinlẹ Eko ni ẹnikẹni ti o ba jẹbi ẹsun yii yoo foju wina ofin labẹ ijọba ipinlẹ Eko.
Bakan naa ni wọn ni olukọ agba kan ni ileẹkọ Odogunyan ti oun sọ fun awọn akẹkọọ rẹ ẹni ti o yẹ ki wọn dibo fun ti kosi panpẹ wọn.
Ileeṣẹ eto ẹkọ naa ni awọn ti fi ijiya to tọ si jẹ olukọ agba naa fun iṣeṣi rẹ to tako ofin to de eto ẹkọ nipinlẹ Eko.
















