Ikọ̀ ajìjàgbara Yoruba Nation lulẹ̀ nílé ẹjọ́, ECOWAS kẹ̀yìn sí ìbéère wọn

Ikọ ajijagbara Yoruba Nation

Ileẹjọ to n gbọ idajọ lawọn orilẹede to wa lẹkun iwọ oorun Afirika, ECOWAS, ti wọgile ẹjọ kan ti awọn eeyan mẹrin to n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba pe.

Atẹjade kan ti akọwe feto iroyin ile ẹjọ ECOWAS naa fisita ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹtala osu Kẹta ọdun 2023 ni wọn gbe idajọ ọhun kalẹ.

Nọmba ẹjọ naa nile ẹjọ ni ECW/CCJ/APP/08/22 nigba ti awọn igbimọ ẹlẹ mẹta to gbọ ẹjọ ọhun jẹ Adajọ Dupe Aiki, Edward Amoako Asante ati Gberi-Bè Ouattara.

Ileẹjọ ni awọn olupẹjọ ko kaato to lati pe ẹjọ lorukọ ara wọn tabi fun idasilẹ Yoruba Nation

Awọn eeyan mẹrẹẹrin to si pe ẹjọ naa lorukọ Yoruba Nation ni Risquat Badmus, Ademola Faleti, Yemisi Fadahunsi-Ogunlana ati Adigun Makanjuola ti gbogbo wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Coalition of Yoruba Interest Group (CYIG).

Ninu idajọ ti igbimọ onidajọ ẹlẹni mẹta to gbọ ẹjọ naa gbe kalẹ,, wọn fẹnuko pe awọn eeyan mẹrẹẹrin yii ni ko kaato to lati pe ẹjọ lorukọ ara wọn tabi fun idasilẹ Yoruba Nation.

Ninu idajọ naa, Adajọ Dupe Aiki to lewaju igbimọ onidajọ ọhun lati ka idajọ wọn ni gẹgẹ bii ẹni kọọkan, awọn olupẹjọ naa kuna lati fidi rẹ mulẹ pe wọn lẹtọ lati duro fun ikọ ajijagbara. Yoruba Nation nile ẹjọ.

Ile ẹjọ Ecowas

Oríṣun àwòrán, Ecowas

"Ẹ ko niwe asẹ lati soju ẹya Yoruba, ẹjọ yin ko lẹsẹ nlẹ"

Adajọ Aiki ni awọn olupẹjọ mẹrẹẹrin naa ko lẹjọ lati pe olujẹjọ, iyẹn ijọba Naijiria lẹjọ.

Bakan naa nile ẹjọ ni awọn olupẹjọ naa kuna lati safihan pe wọn dantọ lati soju iran Yoruba ti wọn tori wọn pe ẹjọ naa.

“Ki asoju to ba n soju ẹnikan to le se aseyọri, iru asoju bẹẹ gbọdọ ni ẹri asẹ lati ọdọ awọn to n soju fun, bẹẹ si ni ko si ẹnikẹni to fi asẹ yii fun ikọ Yoruba Nation.

Idi si ree ti ẹjọ ti wọn gbe wa ko se fidi mulẹ nile ẹjọ.”