Báwo ni Oro ṣe fẹ́ dá àjèjì mọ̀, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Olóyún tó ń rọbí tàbí aláìsàn lásìkò tí Oro bá jáde ní Eko?

Awọn Oloro

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oro ṣiṣẹ jẹ ọkan lara iṣẹṣe ati asa ni ilẹ Yoruba, ti o si wọpọ lati ilu de ilu, agboole de agboole, to fi mọ idile si idile.

Ọba ilu, awọn oniṣẹṣe, awọn Babalawo, awọn onifa , ọlọpẹlẹ ati awọn eleegun ni wọn saba maa n gbe oro ni ilẹ Yoruba.

Ni Ọjọru ni Ọba Elegushi nipinlẹ Eko kede pe oun fẹ gbe Oro jade laarin ọjọ mẹta ni agbegbe naa, eyi si bọ si asiko idibo nipinlẹ naa.

Eleyii mu ki awọn eniyan bẹrẹ si ni fapa janu lori ayelujara, nitori bi o se bọ si asiko ti idibo sipo gomina ati aṣofin ipinlẹ yoo waye.

Lati mọ ẹkunrẹrẹ alaye lori Oro ṣiṣe ni ilẹ Yoruba lo mu wa beere lọwọ onimọ nipa iṣẹṣe ati asa ilẹ Yoruba, Babalawo Idowu Olukunle Adewole, to tun jẹ Akọda Awo ti ijọba ibilẹ Ọna ara ni ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo.

Olukunle Adewole salaye ni ẹkunrẹrẹ idi ti oro fi pọn dan ni ilẹ Yoruba ati bi wọn ṣe n ṣe e.

‘’Orisirisi Oro lo wa ni ilẹ Yoruba’’

Babalawo Adewole ni oro sise jẹ ohun to pọn dandan ni ilẹ Yoruba, to si wọpọ lati agbegbe kan si omiran.

O ni Oro ṣiṣe pin si ọpọlọpọ ọna, ninu rẹ lati ri Oro idile, Oro agboole, to fi mọ Oro ilu kan de ilu miran.

‘’Awọn Oro ti wọn n ṣe wọn yii ma n waye nigba miran nitori ti iṣẹlẹ kan ba ṣẹlẹ ti ko dun mọ ẹbi ninu, ti Babalawo wa sọ fun wọn pe ki wọn se Oro.’’

‘’Ni aye atijọ, ti ilu ba fẹ jagun, wọn ma n bẹ Oro pe ki wọn lọ re, ki wọn si bọ re, ki ogun naa gbe wọn, ki wọn si ko ere oko de ile.’’

‘’Awọn orisirisi Oro to wa ni Oro ifa, oro osaoke, oro ina ti o ma n dun gangan lasiko oro. Nitori naa oro pọ lorisirisi.’’

‘’Dandan ni ọdun Oro, ko ṣe e sun si iwaju, asiko ibo gan ni wọn se ọdun Oro n’Ibadan’’

Akọda awo fikun pe ọdọọdun ni wọn ma n ṣe ọdun oro, eleyii to yatọ si pe nkan pajawiri ṣẹlẹ, ti wọn si fẹ ṣe oro lati fi sun nkan ti o ba fẹ waye si iwaju abi yipada.

‘’Idi ti wọn ki fi n pa oro jẹ ni pe ti wọn ba ṣe bi o se yẹ, yoo ri bi o ṣe yẹ ki o ri’’

‘’Awọn baba nla wa to nilẹ gba wi pe ti wọn ba bọ oro ni ọdun yii, igbe aye wọn ko ni ri bakan naa ni ọdun to n bọ.’’

‘’Igbagbọ wọn ni pe eku yoo ke bi eku, ẹyẹ yoo ke bi ẹyẹ, ti ohun gbogbo yoo dara si, ti aye yoo si tuba ti yoo si tuṣẹ.’’

Babalawo naa ni asiko idibo sipo aarẹ ti ọdun 2023 ni ọdun oro Ibadan bọ si, eleyii to pe ni ọdun ‘’Ọṣẹ meji’’, ni ọṣẹ ti o kọja.

"Oro ti Ọba Elegushi fẹ ṣe ni lati pọn dandan ni wọn ṣe fẹ se e"

Baba Awo Olukunle tẹsiwaju pe ‘’Ọjọ Aiku to ba bọ si ọjọ awo to jẹ ọṣẹ ifa ninu oṣu keji, ni wọn ma n pa ẹran rẹ se ọdun naa.’’

‘’Bi a ṣe ri pe o papọ mọ ọjọ idibo, ni ọjọ aiku ti a n reti esi idibo, gbogbo rẹ ni a ṣe patapata.’’

‘’Ọjọ Monday ni a ma n jẹ ẹran ti a ba pa, ti Ọba si wa si Oke Mapo Hall lati wa ba wọn ṣe ayẹyẹ naa, ti wọn si ṣe.’’

‘’Gbogbo eto to yẹ ki a ṣe ni a sẹ patapata nitori a kii sun ọdun oro siwaju, igba to ba yẹ ki a ṣe ni a ma n sẹ.’’

‘’Nitori naa mo gbagbọ pe oro ti Ọba Elegushi fẹ ṣe ni lati pọn dandan ni wọn ṣe fẹ see. A kii sun ọdun oro siwaju’’

Awọn wo ni ajoji ti ko le e wọ ilu tabi rin lasiko Oro?

Lara awọn ohun ti Ọba Elegushi fi lede ni pe awọn obinrin ati awọn ajọji ko lee rin lasiko oro naa, ki wọn ma baa fi oju wina oro.

Amọ bawo ni yoo ti se rọrun fun awọn Oloro lati da ajeji mọ, paapaa laarin awọn ọmọ Yoruba?

Ninu ọrọ rẹ, Babalawo Idowu Olukunle Adewole ṣalaye ni ẹkunrẹrẹ awọn ilana to rọ mọ dida awọn ti a n pe ni ajoji mọ

‘’Lasiko ọdun Oro, awọn ti wọn n pe ni ajoji ni awọn ti ko si ninu ilu lasiko ti wọn n ṣe ọdun Oro lọwọ amọ to dede wọnu ilu wa.’’

‘’Ni aye atijọ, wọn ti ma n polongo fun awọn eniyan wi pe oro yoo jade ni ọjọ bayii bayii, ki awọn eniyan duro si ile wọn.’’

‘’Ẹnikẹni to ba wọ inu ilu wa ni asiko naa ni ajoji ko niiṣe pẹlu ẹya abi boya ọmọ ilu kan ti kii ṣe ọmọ ilẹ ti wọn ti n ṣe ọdun oro naa.’’

Ki ni yoo ṣẹlẹ si obinrin to ba n rọbi lasiko ti wọn n gbe oro?

Onimọ nipa iṣẹṣe naa ni ti alaboyun ba bẹrẹ si ni rọbi lasiko ti ko yẹ ki obinrin jade lasiko oro, o ni ọna ti wọn lee gbe gba.

O ni oro ṣiṣe ko gbọdọ la ẹmi lọ nitori naa awọn eniyan ma n fi ọgbọn ṣe e ni.

‘’To ba jẹ eegun ti kii ri obinrin soju lo jade lasiko oro naa, ohun ti wọn yoo ṣe ni pe awọn ọkunrin gbọdọ tẹle ninu ọkọ.’’

‘’Ko gbọdọ jẹ obinrin naa nikan ni yoo rin, awọn eniyan to ba tẹle yoo ṣugba rẹ, ti wọn yoo si da abo boo lasiko ti wọn ba n kọja naa.’’

’Ohun ti o tun le ṣẹlẹ ni ki awọn ọkunrin kan bọ silẹ ninu ọkọ, ko si lọ ba awọn oloro naa sọrọ nipa ipenija abi obinrin to n rọbi naa, ati idi ti o fi gbọdọ lọ si ilewosan.’’

Bakan naa ni Babalawọ naa ni eleyii naa niiṣe pẹlu ẹni ti o ba n lọ si ileewosan fun pajawiri ni akoko naa, wọn lee kọja amọ wọn gbọdọ salaye ara wọn fun awọn oloro naa.

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Ariwo sọ bí Ọba Elegushi l‘Eko ṣe ń gbé Orò jáde lóru ọjọ́ ìbò gómìnà

Ọba Elegushi ati awọn Oloro

Oríṣun àwòrán, Collage

Oriade ni agbegbe Ikate-Elegushi nipinlẹ Eko, Ọba Saheed Ademola Elegushi, Kusenla Kẹta, ti kede ọjọ mẹta lati gbe oro jade ni agbegbe naa.

Oro naa yoo waye lati ooru titi di aago marun aabọ, to fi mọ̀ ọjọ Satide to jẹ idibo sipo gomina ati ti ile aṣofin ibilẹ.

Ninu atẹjade to fi lede fun awọn ara agbegbe Ikate-Elegushi ni ọba naa ti ni ko ni irinna lasiko ti wọn ba n gbe oro naa jade lati Ọjọru titi di Ọjọ Abamẹta.

"Oro ti yoo jade ko sediwọ fun idibo"

Bakan naa ni oludamọran pataki fun ọba naa lori ọrọ iroyin, Temitope Oyefeso fi lede pe lootọ ni gbigbe oro jade yoo waye ni agbegbe Elegushi.

O ni igbesẹ naa ko da idibo duro rara nitori oru ni wọn fẹ gbe oro naa, ti wọn ko si sọ fun ẹnikẹni lati maṣe jade.

Ohun ti a n ṣe yii pọn dandan fun alaafia ni gbogbo agbegbe wa ati ipinlẹ Eko ni apapọ.

‘’Awọn ajoji ti wọn ba fẹ dibo ko ni jade ni oru lati lọ dibo, aago mẹjọ aarọ ni wọn fẹ dibo nitori naa a ko da ẹnikẹni duro.’’

Oro ti wọn fẹ gbe lọjọ idibo ko da nkankan duro- Gbadebo Rhodes-Vivour ti LP

Aworan

Oríṣun àwòrán, @GRVlagos

Oludije lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Gbadebo Rhodes-Vivour ni ikede Ọba Elegushi lori oro gbigbe ni agbegbe naa ko ba nkankan jẹ.

Ninu akọjade loju opo Twitter rẹ lo ti ni ọdun oro naa ko niiṣe pẹlu idibo ti yoo waye ni ọjọ satide ti ko si ni si idiwọ tabi idena.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, aago mejila ooru si aago marun un abọ ni idaji ni oro naa yoo waye, amọ o di aago mẹjọ ki idibo to bẹrẹ.

‘’Ọdun oro ko lee di idibo ọjọ satide lọwọ, ọba Elegushi ti fi wa loju, a si dupẹ lọwọ rẹ.’’

‘’Ẹyin ara Eko e jade sita, ko si ibẹru fun yin, ẹ jade ki ẹ si dibo, idibo bẹrẹ ni aago mẹjọ.’’

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post