Magun (thunderbolt): Wo oríṣì mágùn mẹ́sàn-án tí wọ́n n lé sí ara obìnrin nílẹ̀ Yorùbá

Ọkunrin ati obinrin to n ni ibalopọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ diẹ sẹyin ni iroyin jade pe babalawo kan ku lasiko to n ni ibalopọ pẹlu iyawo pasitọ kan nipinlẹ Ekiti.

Bo tilẹ jẹ pe iwadii ko ti sọ nkan to pa babalawo naa, Fadayomi Kehinde 'Ejiogbe', awọn eeyan kan gbagbọ pe Magun lo pa a, ni ile itura kan niluu Ikere-Ekiti.

Igbagbọ yii kan naa la gbọ pe o mu ki awọn akẹẹgbẹ ati awọn ọdọ kan, lọ fi ibinu kọlu ṣọọṣi pasitọ to jẹ ọkọ obinrin naa.

Iru awọn iroyin bayii ti n jade tipẹ, eyi lo mu ki BBC ba babalawo kan sọrọ lasiko diẹ sẹyin, lati tan imọlẹ si ọrọ Magun nilẹ Yoruba.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba, Babalawo Idowu Olukunle, Akoda Awo ṣalaye pe, lati igba iwaṣẹ ni Magun ti wa, ti awọn agba fi n ṣe iṣọra fun awon iyawo wọn, paapaa julọ, ti wọn ba ti n fura pe iru obinrin bẹẹ n rin awọn irin ti ko tọna.

Àkọlé fídíò, 2023 Nigeria Election: Ìgbàgbọ́ wa ní pé Nàìjíríà ṣì máa dùn lẹ́yìn ìdìbò ọ̀la yìí

O fi kun un pe, ẹya gbogbo lo ni agbara ti Eleduwa fun un; lara agbara ti Eleduwa si fun ilẹ Yoruba ni Magun, ma debẹ si lẹrọ rẹ.

Agba awo naa ni ohun to dara ju ni ki awọn eeyan maa duro ti nnkan won, ki wọn maa si ṣe ojukokoro si obinrin olobinrin.

Akoda awo ṣalaye siwaju sii pe, bi ọkunrin ba ni iyawo to si ṣakiyesi pe awọn ọkunrin miran ko jẹ ko sinmi, yoo wa nnkan to ba mọ lati fi ṣọ iyawo rẹ.

Baba Awo Idowu Olukunle ni orisirisi magun pọ pupọ, ko si lopin, ohun ti wọn ba fi se, si ni yoo sọ nipa eewọ rẹ, amọ diẹ lara orisi Magun to mẹnuba ree:

Magun onilẹpọ:

Eyi ni irufẹ Magun ti yoo mu ki ọkunrin ati obinrin lẹpọ bi wọn ba ti n ṣe ere ifẹ, ti wọn ko si ni lee ya.

Irufẹ Magun yii lo saba n fara han lori ayelujara lode oni.

Àkọlé fídíò, Òǹtàjà aṣọ ni mí tẹ́lẹ̀, ọ̀dá owó ló sọ mi di alábárù

Magun ma mu omi:

Iru Magun yii ni yoo ma mu ki ọkunrin to ba lu maa pongbẹ fun omi, ni kete ti o ba ti ba obinrin ti wọn ba le ni magun ni aṣepọ.

N ṣe ni ọkunrin bẹẹ yoo maa pongbẹ omi, koda bi wọn gbe odindi odo fun un pe ko mu, ko ni tan oungbẹ naa.

Omi yii ni yoo si mu, titi ti yoo fi gba ọrun alakeji lọ.

Magun Olokiti:

Bi ọkunrin ba ti lu Magun yii lara obinrin, ọna bi yoo ṣe takiti ni yoo maa wa, bi o ba si ti le e takiti bayii, ọrun laalaa ni.

Magun alakukọ:

Bi eeyan ba ti lee lu iru magun yii lara obinrin, yoo maa gun un tabi ṣe e bii ko kọ bi akukọ ni.

Ni kete ti o ba si ti lee kọ fun igba mẹta, ẹlẹkọ ọrun yoo polowo fun un ni.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Magun Ẹlẹyin:

Bi ọkunrin ba lu Magun yii, yoo maa wa ẹyin kiri ni, to ba si ti rii ni yoo jade laye.

Magun Majẹla:

Ọkunrin to ba ba obinrin ti wọn ba le iru Magun yii si lara, ko gbọdọ jẹ ila, ni kete to ba ti le fi ẹnu kan ila, ọrun laala niyẹn.

Baba awo fi kun un pe ohun ti wọn ba le fi pilẹ Magun bẹẹ, ni yoo maa wu ọkunrin bẹẹ lati jẹ tabi se.

Àkọlé fídíò, Imam ìjọ Shafaudeen in Islam, Sabit Olagoke gbàdúrà pé kò sí olólùfẹ́ BBC Yorùbá tó máa ṣì

Magun Mafogọta:

Gọta ni yoo ma wu ọkunrin to ba lu Magun yii lati fo, ni kete ti o ba si ti fo o bayii, yoo jade laye ni.

Magun Majẹkengbe:

Bi ọkunrin to ba lu iru Magun yii ba ti jẹ kengbe, iyẹn akara ti wọn fi epo din, ọrun laala.

Àkọlé fídíò, Alagbalúgbú jẹ́ ọ̀rọ̀ Yorùba tí a fi ń ṣàpèjúwe agbára òkun

Magun Majẹ-ibẹpẹ:

Ọkunrin to ba ba obinrin ti wọn ba le iru Magun yii si lara laṣepọ, yoo maa pongbẹ lati jẹ ibẹpẹ ni. Ni kete to ba si n ti fi ẹnu kan an, ọrun laala o.

Akoda awo wa rọ awọn ọkunrin lati jinna si ṣina, ki wọn tọju obinrin wọn nitori ohun to ba wu ọkọ iyawo lo lee fi sọ iyawo rẹ.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are