Àánú táwọn èèyàn yóò fi máa sọ wí pé ọ̀nà wo lo gbà ni yóò wọlé fún ọ ní ọdún yìí

Àkọlé fídíò, Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ náà ni ọdún náà ń gorí ara wọn.
Àánú táwọn èèyàn yóò fi máa sọ wí pé ọ̀nà wo lo gbà ni yóò wọlé fún ọ ní ọdún yìí

Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ náà ni ọdún náà ń gorí ara wọn.

A tún ti bọ́ sí ọdún tuntun, ọdún 2023. Láṣẹ Èdùmàrè ọdún a yabo fún gbogbo wa.

A kú ọdún tuntun káàkiri gbogbo ilẹ̀ Yorùbá àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ ìgbàgbọ́ Yorùbá wí pé tí a ó bà á bẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo àdúrà náà ni a máa fi ń ṣáájú kí ìgbésẹ̀ àti ohunkóhun tí a bá fẹ́ ṣe le ní àṣeyọrí rere.

Ìdí nìyí tí BBC Yorùbá ṣe tọ àgbà wòlíì, Wòlíì Babatunde Samuel, Olùdarí àpapọ̀ ìjọ Sotitobire láti fún wa ní àdúrà láti bẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun yìí.

A gbà á ní àdúrà wí pé bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ ọdún 2023 yìí, ọ̀tun ọ̀tun tí ọjọ́ ń yọ ni ọ̀rọ̀ gbogbo wa yóò máa já sí.

Wọn ò ní bọ́ bàtà ọ̀fọ̀ sí ẹnu ọ̀nà kálukú wa nínú ọdún tuntun yìí.

A ò ní báwọn ní ìpín nínú gbogbo aburú, ẹkún, ọ̀fọ̀, òṣe nínú ọdún tuntun yìí àti ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

BBC Yorùbá ń kí wa kú ọdún a kú ìyèdún, ẹ̀mí wa máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láyé.

Wolii Babatunde Samuel