Wó àwọn òṣèré tíàtà àti èèkànlú to jáde láyé ní 2022

Oríṣun àwòrán, collage
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Bii ọdun 2022 ṣe jẹ ọdun idunu fun awọn eeyan kan pẹlu oniruuru asiko to dara ati manigbagbe isẹlẹ ree.
Bakan naa, lo jẹ ọdun to mu ibanujẹ wọle fun awọn ẹbi kan, paapa julọ si awọn mọlẹbi awọn eeyan jankan jankan kan to jade laye.
Ileeṣẹ BBC News Yoruba ṣe akọsilẹ orukọ awọn eeyan jankanjankan ati osere tiata naa ati igbesi aye ti wọn gbe nigba ti wọn wa laye.
Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta

Oríṣun àwòrán, Alaafin of Oyo/Facebook
Ti a ba sọrọ nipa ọkan googi ninu Ọba alade nilẹ Yoruba, ko si bi wọn ko ṣe ni darukọ, Alaafin ti ilu Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi. Adọta ọdun Ọba Adeyemi III lo lori apere ko to waje.
Pupọ lara awọn ohun idagbasoke ti o ni ọwọ Ọba naa ninu, ti awọn araalu si fẹran Alaafin pupọ.
Iyawo mẹtala ni Ọba Adeyemi fẹ sile gẹgẹ bii aya
Ọba Adeyemi waja ninu lọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹrin ọdun 2022.
Yemi Adegunju

Oríṣun àwòrán, Yemi Adegunju/Facebook
Aarẹ Yemi Adegunju lo kọkọ se sinima agbelewo to jẹ kikida awọn obinrin nikan, to pe akọle rẹ ni "Lágídígba".
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ, Adegunju jade laye lasiko aisan kan to ba afinra, eyi ti ko ju osu meji pere lọ.
Ologbe Yemi Adegunju ni wọn ti sin sile rẹ to wa nilu Ibadan l'Ọjọru.
Ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹtala osu Kejila ọdun 2022 ni Yemi Adegunju jade laye, ti ọpọ awọn osere tiata lede Yoruba si ti n se idaro rẹ, paapaa lawọn oju opo ayelujara wọn.
Loju opo Instagram rẹ, gbajugbaja osere tiata kan, Odunlade Adekola lo kọkọ kede oku oloogbe naa, to si ni ko sun re.
Bakan na ni osere tiata miran, Bose Aregbesola naa kọrin re ki Oloogbe Yemi Adegunju pe ẹni ire lọ loju opo Instagram rẹ.
Oba Saliu Adetunji, Olubadan ti ilẹ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Saliu Akanmu Adetunji
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 1928 ni wọn bi Oloogbe Saliu Akanmu Adetunji ni agboole Adetunji, ni adugbo Popoyemoja nilu Ibadan.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, Oba Adetunji ko lọ si ile ẹkọ kankan.
O ni ibaṣepọ oun pẹlu awọ̀n oyinbo alawọ funfun, gẹgẹ bi oniṣowo lo fun oun ni anfaani lati gbọ ede Gẹẹsi.
Iṣẹ aranṣọ ni Adetunji kọkọ kọ ni owurọ aye rẹ.
Ori ade naa la gbọ pe o ku si ilewosan aladani kan nilu Ibadan ni owurọ ọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2022.
Ẹni ọdun mẹtalelaaadọrun ni.
Chief Ernest Shonekan

Oríṣun àwòrán, Earnest Shonekan
Oloye Earnest Shonekan lo jẹ aarẹ fidi rẹ lẹyin isẹjọba aarẹ ologun Ibrahim Babangida
Oloye ku ni ọjọ kọkanla oṣu kini ọdun 2022 lẹyin aisan ranpẹ nile wosan niluu Eko.
Oloogbe kẹkọọ gboye imọ ofin nilẹ Gẹẹsi, o tun jẹ oniṣowo to yanranti.
Shonekan ni ọga agba ileeṣẹ United African Company of Nigeria Plc, UAC, ki ọgagun Ibrahim Babangida to yan gẹgẹ bii Aarẹ fidihẹ lọdun 1993.
Wọn bi Shonekan lọjọ kẹsan an, ọsu Karun un, ọdun 1936 niluu Eko.
O kawe ni ile ẹkọ CMS grammar school niluu Eko ati Igbobi College, ko to tẹsiwaju kẹkọgboye ni fasiti ilu London ati Harvard Business School.
Kunle Adetokunbo, ti ọpọ eeyan tun ọ si Dejo Tunfulu.

Oríṣun àwòrán, Dejo Tunfulu
Gbajugbaja oṣere tiata, Kunle Tokunbo ti gbogbo enìyan mọ sí Dejo Tunfulu naa pẹlu awọn gbajumọ to jáde láyé lọdun 2022.
Ni oru mọjumọ ni oloogbe naa jade laye bi o tilẹ jẹ pa a ko tii le fidi ohun to se okunfa iku rẹ mulẹ.
Aadọta ọdun ni loogbe naa lo loke eepẹ, ki ọlọjọ to de.
John Adewuni Adewoye, ni ọpọ eeyan mọ si Tafa Oloyede

Oríṣun àwòrán, Tafa Oloyede
John Adewuni Adewoye, ni ọpọ eeyan mọ si Tafa Oloyede lori ere tiata.
O jẹ gbajumọ osere tiata lori mohunmaworan, sinima agbelewo ati fiimu ni ede Yoruba,
Ẹgbẹ osere Oyin Adejobi lo wa, to ti di ilumọọka osere tiata nilu Osogbo.
Ọmọ bibi ilu Ede ni Tafa Oloyede, to si ti kopa ninu ọpọ sinima, ere itage ati fiimu.
Ifeanyi Adeleke

Oríṣun àwòrán, davido/Instagram
Alẹ ọjọ Aje ni iroyin gbalẹ kan pe Ifeanyichukwu tii se ọmọkunrin kan soso ti gbajumọ akọrin takansufe, Davido bi ti jade laye.
Ọpọ eeyan naa ni iroyin ọhun n se ni kami kami kami, ti wọn ko si fẹ gba ikede iku ọmọ naa gbọ.
Amọ nigba to di aarọ ọjọ keji ni agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fidi isẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin pe lootọ ni Ifeanyi ti jade laye.
Isẹlẹ iku ọmọde yii lo dun awọn eeyan de ọkan, paapaa na to ba ku, ti ọpọ awn osere tiata, akọrin, awọn oloselu atawọn agbaagba lawujọ si ti n ransẹ ibanikẹdun si ẹbi Adeleke.
Alhaji Kamal Adebayo, ti ọpọ eeyan mọ si Sir Kay

Oríṣun àwòrán, isbae U/Instagram
Alhaji Kamal Adebayo, ti ọpọ mọ si ‘Sir Kay Warrior’ jade laye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2022.
Ọpọ eekan oṣere ni wọn ti n daro gbajumọ oṣere
Gbajumọ oṣere naa jẹ eekan adẹrinpoṣonu nigba aye rẹ to si ti kopa ninu oniruuru sinima.
Alaaji Adebayọ ni Baba Adebayọ Ridwan, ti ọpọ mọ si Isbae U Barbie lori oju opo ayelujara.
Ada Ameh

Oríṣun àwòrán, Ada Ameh/Instagram
Gbajugbaja oṣere tiata, Ada Ameh lo ti jade laye lana ọjọ Aiku ni ile iwọsan kan ni ipinlẹ Delta.
Ada Ameh jẹ oṣere tiata Nollywood ti a bi ni ọjọ kẹẹdogun ọdun 1974.
O wa lati ilu Idoma ni ipinlẹ Benue sugbọn wọn bi ni Ajegunle ni ipinlẹ Eko.
O ka ile ẹkọ akọbẹrẹ ati girama rẹ ni ipinlẹ Eko sugbọn o dẹkun lati ma lọ ile eko lẹni ọdun mẹrinla.
O darapo mọ ẹgbẹ tiata lọdun mẹtadinlọgbọn sẹyin.
Osinachi Nwachikwu

Oríṣun àwòrán, Osinachi
Arabinrin Osinachi ti awo orin "Ekwueme" tan irawọ rẹ kariaye jade laye lọjọ kọjọ oṣu kẹrin ọdun 2022 lẹyin ti wọn ni o ni ọgbẹ inu lookan aya rẹnitori iya ati lilu lọwọ ọkọ rẹ.
Lẹyin iku rẹ ni iroyin to lu jade sita pe wọn fẹsun kan ọkọ rẹ pe oun lo luu titi to fi ku.Awọn mọlẹbi oloogbe - iya, ibeji rẹ atawọn aburo rẹ, ọrẹ atawọn mii fẹsun kan pe ọkọ rẹ maa n na a.Amọṣa to fi mọ Ọlọpaa ati ile ẹjọ, ko si ẹnikẹni to tii fi aridaju eyi han sita.Iku rẹ wu ibinu jade lọkan awọn eeyan kaakiri agbalaaye tori o jẹ iyalẹnu.
















