Mọ́tò ya wọlé kan l‘Eko, ọmọ ìyá méjì kú ọ̀rẹ́ wọ́n farapa

Aworan Ijamba Ọkọ

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ijamba ọkọ ayọkẹlẹ kan to waye ni agbegbe Isolo nipinlẹ Eko lo ti gbẹmi ọmọ iya meji kan ti ẹnikẹta si wa ni ile iwosan pelu farapa.

Orukọ awọn ọmọ iya meji naa ni Abibu Bello, ọmọ ọdun mẹtadinlogun ati Bolaji Bello ọmọ ọdun mẹrinla.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju ni awakọ naa ṣẹṣẹ kuro nile aṣerunloge kan to wa ni agbegbe ohun ni, ko to sọ ọwọ ijanu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ nu.

Ọkọ naa si lo ya wọnu ile ti awọn ọmọ naa ti n sere.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni, bi ago mẹjọ ku ogun iṣẹju ni irọlẹ ana ni ijamba naa waye ti ọkọ ayọkẹlẹ naa ṣaaju rọlu sọọbu kan to wa ni iwaju ile ko to ya wọnu ile agba oloselu ti o si gbẹmi ọmọ rẹ meji.

Osoju mi koro kan sọ fun iwe iroyin Punch pe ni,”meji ninu awọn ọmọ mẹta ti ọkọ ayokẹlẹ naa rọlu lo padanu ẹmi wọn loju ẹsẹ, baba wọn jẹ gbajugbaja oloṣelu ni adugbo, ọmọ kẹta jẹ ọrẹ wọn, ẹsẹ rẹ ti ge o si n gba iwosan ni ile iwosan ijọba to wa ni Isolo.

Obinrin to wa ọkọ ayọkẹlẹ naan wa ni ile iwosan nitori farapa to ni ninu iṣẹlẹ ijamba na.

Alukọrọ fun ile isẹ ọlọpa ipinlẹ Eko Benjamin Hundeyin fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Jàgùdà ṣọsẹ́ n‘Ibadan, wọ́n fi PoS gbowó, gba dúkìá, wọn tún fipá báni lòpọ̀

Awọn adigunjale ati ẹrọ PoS

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ọpọ awọn olugbe adugbo Olode, Olomo, Alakuta, Ayegun, Olose ati Arijo ti gbogbo wọn wa ni agbegbe Apete nilu Ibadan ni wọn wa ninu ipaya bayii tori bawọn adigunjale ṣe n ṣe ọṣẹ nla ni agbegbe wọn.

Ọjọ manigbagbe si ni alẹ ọjọ Satide, ọjọ Kọkanla osu kẹta ọdun 2023 jẹ fawọn eeyan agbegbe naa nigba tawọn Ọlọṣa ya bo awọn adugbo yii ni deede ago kan oru, ti wọn si ko wọn ni dukia lọ.

Awọn adigunjale ọhun, ti wọn dihamọra pẹlu ọpọ ohun ija oloro ni wọn tun mu ẹrọ to n gba owo latinu ike owo ta mọ si PoS lọwọ.

PoS yii si ni awọn alọkolohunkigbe naa fi n gbọn owo awọn eeyan adugbo naa sinu apo asuwọn owo tara wọn nitori bi aisi owo beba se n daamu awọn ọmọ Naijiria lọwọlọwọ.

Koda, ko si ẹnikẹni to yẹ awọn adigunjale naa lọwọ wo, titi ti wọn fi sisẹ laabi wọn tan ni adugbo ọhun.

"Ọlọṣa meji pere lo wa da agbegbe naa laamu, ti wọn si gba ọpọ dukia lọ"

Iroyin isẹlẹ idigunjale yii lo ta BBC Yoruba nidi kan, ta fi se abẹwo sawọn adugbo naa sugbọn ọpọ awọn eeyan to ba wa sọrọ kọ lati foju han lori ẹrọ ayaworan wa tabi pe ka gba ohun wọn silẹ.

Nigba to n ba wa sọrọ lori bi isẹlẹ naa se waye, ọkan lara awọn aladugbo ọhun, Akinola Olumide ṣalaye fun akọroyin BBC Yoruba pe awọn adigunjale gba ọpọlọpọ dukia lọwọ awọn eeyan ti wọn ka mọle.

Ninu ọrọ rẹ, alaga agbegbe naa, Alufa Oluniyi Babatope ni meji ni awọn igara ọlọṣa to wa ṣiṣẹ ibi naa.

Babatope ni lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye tan, ni awọn gbọ, ti oun ati awọn kọọkan rin adugbo naa ka, boya ọwọ yoo tẹ awọn ọlọṣa yii.

"Awọn Adigunjale yii fi tipa ba ololufẹ ẹni ti won wọ ile rẹ lopọ"

Oluniyi ati Olumide ni iṣẹlẹ naa ki ṣe akọkọ ladugbo awọn nitori irufẹ iṣẹlẹ naa waye ni Otun, ọlọjọ, Ẹlẹsin, Olomo ati awọn agbegbe miran ti ko jinna pupọ sì Olode nibiti iṣẹlẹ miran ti waye.

Ọkan lara awọn oloye agbegbe naa, Giwa Oladele ni oru ọjọ Satide ni iroyin kan oun pe awọn ọlọṣa wa si adugbo naa.

O ni awọn Ọlọsa naa si gba foonu olowo iyebiye iPhone 11 Pro Max ati iphone XS Max lọwọ eeyan agbegbe naa lẹyin ti wọn fo iganna ile wọle.

Oloye Giwa ni awọn ọdaran naa fi tipatipa ba ololufẹ ẹni ti won wọ ile rẹ lopọ.

Àwọn agbófinró kò pèsè ààbò tó péye fún wà -Oladele

Oloye Giwa Oladele wa bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbofinro agbegbe Apete ko ṣe jẹ ki eto aabo mu yanyan lagbegbe wọn.

O ni irufẹ iṣẹlẹ idigunjale yii ti waye ni adugbo ọhun ri, ti wọn tun fipa ba arabinrin kan lopọ.

Oladele ni ọpọ igba ni awọn agbofinro kọ lati ṣe iṣẹ wọn.

Bẹẹ ni Giwa ni "ta ba mú ọdaran lọ si ọdọ awọn ọlọpa lẹyin ọjọ meji sì mẹta, wọn a ti tu silẹ".

Laipẹ yii ni ọwọ tẹ ọdaran kan to fi ada ṣá ẹnikan, títi di asiko yii awọn ọlọpa ko tii ri ojutu sì iṣẹlẹ naa".

O wa rọ kọmisọna ọlọpa ipinlẹ Oyo lati jí giri si ipese eto aabo to peye.

O ni ti awọn ba gbiyanju lati mu ọdaran lọna aṣa ilẹ Yoruba, o seeṣee ki awọn agbofinro fi panpẹ Ọba mu awọn ara adugbo naa.

Giwa tun rọ awọn ẹka eleto aabo lati fi ofin mu ọdaran, kí wọn si ṣe idajọ rẹ lọna to yẹ lati mu adinku ba iṣẹlẹ idigunjale nipinlẹ Oyo.