Wo Bàbá tó tá ọmọ rẹ oṣù mẹjọ fún òníbara mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Aworan Baba to ta ọmọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ogun

Ọkunrin kan, ẹni ọgbọn ọdun, Daniel Chigozie, to jẹ olugbe agbegbe Abele ni Sango Ota nipinlẹ Ogun, lo ti wọ gau pẹlu ikọ alaabo Amotekun lẹyin to ta ọmọ rẹ ọkunrin fun onibara mẹta ọtọọtọ.

Ọga agba fun ileeṣẹ Amotekun nipinlẹ Ogun, Daniel Akinremi lo safihan ọkunrin afurasi naa lẹyin ti ọwọ ileeṣẹ Amotekun tẹ pe o ta ọmọkunrin bibi inu rẹ, Dainel Chinonye Darlington, fun onibara mẹta lati agbegbe ọtọọtọ ni Sango, Meiran ati Apapa nipinlẹ Eko.

N150,000, N400,000 ati N700,000 ni afurasi naa gba lọwọ awọn eeyan to ta ọmọ rẹ fun

Ọkunrin naa lo gba N150,000, N400,000 ati N700,000 lọwọ awọn onibara naa laarin oṣu kẹjọ ninu ọdun 2022 si oṣu keji ninu ọdun 2023.

Akinremi, ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin ni iwadi ileeṣẹ Amotekun fi han pe Baba ọmọ naa lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọdaran kan lati wa gba ọmọ rẹ pada lọwọ onibara to ta fun, lẹyin to ba gba owo lọwọ wọn.

Onibara ikẹyin ni Dokita Nosa ni Apapa.

Akinremi tẹsiwaju pe afurasi naa ti jẹwọ si ẹsun naa.

O ni ajọ to n gbogun ti tita awọn eeyan lorilẹede Naijiria si ti bẹrẹ iwadi lati gba ọmọ naa pada lọwọ ẹni to ta fun .

Nibayii, ajọ naa ti setan lati gbe awọn afurasi naa lọ si ileẹjọ.

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Obìnrin ayálégbé fa nǹkan ọkùnrin ‘Landlord’ rẹ̀ lásìkò ìja, ikú dé

Ifeoma Ossai

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ni ọwọ oun ti tẹ obinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan fun ẹsun ipaniyan.

Arabinrin Ifeoma Ossai ni wọn fi ẹsun kan pe o pa onile rẹ, Monday Surulere Oladele, to jẹ ẹni aadọta ọdun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ija to waye laarin wọn lo ja si iku baba onile naa.

'"Owo ile lo fa ija laarin baba onile ati ayalegbe, ti ẹmi fi bọ"

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn fi panpẹ ọba mu afurasi obinrin ayalegbe naa lẹyin ti wọn wa fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Sango Ọta.

Arakunrin to wa fi ẹjọ sun naa sun, to jẹ aburo si oloogbe ọhun salaye pe ija laarin ayalegbe ati onile lori sisan owo ile lo mu onile gba ibẹ lọ.

Wọn fi ẹsun kan Ossai pe nigba ti wọn bẹrẹ si ni ja, ni obinrin naa di nkan ọkunrin onile gbe, to si daku gbọnran-gandan, ko to dipe o gba ibẹ lọ.

Bi onile naa ṣe subu lulẹ ni wọn gbe lọ si ileewosan ijọba amọ ti dokita to wa ni ẹnu iṣẹ ni o ti di oloogbe.

Lẹyin naa ni ọlọpaa lọ si ibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si fi panpẹ ọba mu obinrin afurasi apaniyan ọhun.

Baba onile ko pese omi sinu ile, ni mo se kọ lati sanwo ina, eyi to fa ija - Afurasi apaniyan

Ileeṣẹ ọlọpaa ni obinrin ọhun ṣalaye pe onile oun lo kọ lati pese omi si inu ile oun.

O ni eyi lo mu ki oun kọ lati san owo ina titi ti onile yoo fi se omi si inu ile naa gẹgẹ bo ṣe ṣeleri fun oun nigba ti oun gba ile.

Igbesẹ yii da ija silẹ laarin wọn, ti afurasi naa si di nkan ọmọkunrin onile mu, to si fa a pẹlu rẹ lasiko ija.

Afurasi naa ni wọn lo subu lulẹ, ti wọn si gbe lọ si ileewosan, ki dokita to sọ pe o ti gba ibẹ lọ.

Nibayii, wọn ti gbe oku baba onile naa lọ si ile igbokusi fun ayẹwo oku.

Amọ, kọmiṣana ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Frank Mba ti paṣẹ ki wọn gbe afurasi naa lọ si ẹka ọlọpaa to n gbọ ẹsun iwa ọdaran fun ẹkunrẹrẹ iwadii to peye lori iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Ajínigbé jí akọ̀rọ̀yìn ní Ijebu Ode, ọlọ́pàá ya bò wọ́n ní Eko, ẹ̀jẹ̀ ń sàn

Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi lede pe oun ti doola ẹmi akọroyin kan, Oduneye Oluṣẹgun ti awọn ajinigbe ji gbe.

Akọroyin naa ni wọn lo n pada bọ lati Abeokuta, ti wọn si jigbe ni agbegbe Mobalufọn ni Ijebu-Ode ni Ọjọ Kẹsan an, Osu Kẹta, ọdun 2023.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, SP Abimbola Oyeyemi lo fi iroyin ọhun lede pe wọn doola ẹmi akọroyin naa ni agbegbe Idimu nipinlẹ Eko.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun ati Eko lo ṣiṣẹ pọ pẹlu kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Frank Mba.

Ileeṣẹ ọlọpaa naa ni lasiko ti wọn pe iyawo akọroyin ti wọn jigbe naa lati gba milọnu lọna ọgbọn naira gẹgẹ bi owo idoola ẹmi, ni oye agbegbe ibi tawọn ajinigbe naa wa to foju han.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni lẹyin ti wọn gba ipe wọn naa tan, ni wọn wa wa wọn lọ si ibi ti wọn sa pamọ si ni agbegbe Idimu, nipinlẹ Eko.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

"Araalu, ileewosan ati oniṣẹṣe, tí ẹ ba ri ẹnikẹni pẹlu oju ọgbẹ ọta ibọn, ẹ fi to awa ọlọpaa leti"

Gẹgẹ bi ọrọ Oyeyemi, akọroyin naa wa ni alaafia amọ awọn ajinigbe naa fi ara gbọta lasiko ti wọn kọju ọlọpaa.

Bakan naa ni wọn ri ọkọ akọroyin naa, Toyota Camry ni agbegbe Idimu nipinlẹ Eko, nibi ti awọn ajinigbe naa ti n duro de owo ẹmi ti wọn fẹ gba.

‘’Bi wọn ‘se ri awọn ọlọpaa ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn fun bi iṣẹju marundinlaadọta, ki wọn to fi ọkọ naa silẹ, ti wọn si sa asala fun ẹmi wọn.’’

Ileeṣẹ ọlọpaa dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa ti wọn ṣiṣẹ lati doola ẹmi akọroyin naa.

Bakan naa ni wọn kesi awọn araalu, ileewosan ati awọn oniṣẹṣe lati fi to ọlọpaa lori ti wọn ba ri ẹnikẹni pẹlu oju ọgbẹ ọta ibọn ni ara wọn.

Kọmiṣọna ọlọpaa naa wa rọ awọn adigunjale lati fi ipinlẹ naa silẹ fun wọn abi ki wọn reti lati fi ẹmi ara wọn di.