Ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP fẹ́sùn kan àràwọn lórí rògbòdìyàn tó gbẹ́mìí èèyàn mẹ́ta n'Ibadan

Aworan Seyi Makinde ati Teslim Folarin

Oríṣun àwòrán, Google

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ipinlẹ Ọyọ ti fi ẹsun kan wi pe ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP ipinlẹ Ọyọ lo n gbiyanju lati da omi alaafia ipinlẹ naa run.

Ninu ọrọ ti agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ, Ọlawalẹ Ṣadare ba BBC Yoruba sọ, o ṣe alaye wi pe ọfisi ti ẹgbẹ naa n lo ni Iyana Kootu ni tosi ile tuntun ni ijọba ibilẹ Ila Oorun-Guusu ni awọn ọmọ ẹgbẹ wọn korajọpọ.

O ni nnkan bii aago mẹta ọsan kọja iṣẹju diẹ l'Ọjọbọ lati jiroro pẹlu awọn oludije fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, ki o to di pe awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP to n ṣe ipolongo ibo kọja ni agbegbe naa bẹrẹ sini sọ awọn ọrọ kobakungbe si awọn ọmọ ẹgbẹ APC to n ṣe ipade ni ile ẹgbẹ wọn.

Ṣadare ni iṣọri meji ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to ṣe ipolongo ibo ni agbegbe naa pin ara wọn si.

O ni oloṣelu akọkọ ti o kọja nibẹ ni aṣoju ile igbimọ aṣofin tẹlẹri, Họnọrebu Akeem Ademọla Ige.

O tẹsiwaju pe ilu ti awọn ọmọ ẹgbẹ APC gbọ lo mu ki wọn yọju lati oke ile alaja kan ti ẹgbẹ wọn n lo.

O ni, "Awọn ẹgbẹ oṣelu PDP to n ṣe iwọde wa bẹrẹ sini sọrọ si awọn eeyan wa pe "Ẹ ti lulẹ o" Ẹ o le wọle o", ṣugbọn wọn ko fa ijọngbọn yatọ si gbolohun ti wọn fi n ranṣẹ si awọn ọmọ ẹgbẹ APC to n ṣe ipade."

Ṣadare ni lẹyin bi iṣẹju mẹta ti awọn ti o tẹle Ademọla Ige kuro nibẹ, ni awọn iṣọri keji awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti o wọ tẹle Họnọrebu Abass Adigun Agboworin naa tun de si tosi ile ẹgbẹ oṣelu APC.

"Ilẹkun a n ti lọwọ ki a to bẹrẹ sini gbọ iro ibọn lati isalẹ."

"Gẹgẹ bi awọn ti isaaju ṣe ṣe naa si ni awọn naa tun bẹrẹ eebu ti wọn si bẹrẹ sini ju oko ati afọku igo lati isalẹ ṣugbọn alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ijọba ibilẹ naa, Ọmọọba Tajudeen Aṣankẹ paṣẹ fun awọn to n ba ṣe ipade wi pe ki wọn ti ilẹkun ile ẹgbẹ naa, ki wọn ma si ba ẹnikẹni fa wahala."

Ṣadare tẹsiwaju wi pe ilẹkun yii ni wọn n ti lọwọ ki wọn to bẹrẹ sini gbọ iro ibọn lati isalẹ.

Gbogbo gilaasi ọkọ ipolongo Warith Adegoke ti o jẹ ọkan lara awọn oludije to wa nibi ipade ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn fọ.

Lẹyin ọrẹyin, o ni awọn ko mọ bi ibọn ṣe ba mẹta ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ṣadare ke si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lati ṣiṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Ẹgbẹ Oṣelu PDP fesi lori iṣẹlẹ naa

Igbimọ ipolongo ibo fun Gomina Ṣeyi Makinde ti bẹnu atẹ lu bi " ọmọ ẹgbẹ wọn mẹrin ṣe pade iku ojiji lati ọwọ awọn afurasi janduku ti wọn jẹ alatilẹyin oludije fun ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ aburada ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnetọ Tẹslim Folarin.

Igbimọ ipolongo ibo fun Makinde to ke si awọn ẹṣọ aabo lati nawọ gan Fọlarin "ati awọn isọmọgbe rẹ to ṣeku pa awọn ọmọ ẹgbẹ oṣẹlu PDP" fi kun ọrọ wọn wi pe iṣẹlẹ yii gan an lo fi idi ọrọ mulẹ wi pe "ẹni ipa ati baba isalẹ awọn janduku ni oludije fun ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC."

Atejade ti oluranlọwọ pataki fun Gomina Makinde lori ikede ati ipolongo, Moses Alao fi ṣọwọ si awọ oniroyin lorukọ igbimọ ipolongo ibo fun Makinde tọka ẹsun si Fọlarin ati ẹgbẹ oṣelu APC pe gbogbo iṣẹsi wọn nitori oṣelu lo n da omi alaafia ipinlẹ Ọyọ ru.

Atẹjade naa ke si ọlọpaa lati ṣe iwadii iṣẹlẹ naa ki wọn si fi idi ododo mulẹ.

Ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ọyọ fi Ọrọ Lede

L'ọjọ Ẹti ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ pẹlu alaye wi pe eeyan mẹta lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adewale Osifeso lo ṣe alaye ọrọ naa lasiko to n da si eto kan lori Redio nilu Ibadan.

O ni igbakeji Kọmisana ajọ ọlọpaa to wa ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ ti gba aṣẹ lati ko awọn ọlọpaa lọ ṣe ayẹwo si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Agbébọn 30 tó daṣọ dúdú bojú ya bo agboolé wa n‘Ibadan, ọ̀pọ̀ farapa - Folarin

Teslim Folarin ati agbebọn

Oríṣun àwòrán, Teslim Folarin

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni awọn agbebọn ti yabo agboole sẹnatọ Teslim Folarin to wa ni igboro ibadan ni agbegbe Oja’gbo.

Agbẹnusọ fun Teslim Folarin, YSO Olaniyi si lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

O ni bii ago mẹjọ alẹ kọja ni awọn agbebọn naa de ninu ọkọ ayọkelẹ Toyota Hillux bi mẹwa, eyi ti wọn fi ọra bo nọmba idanimọ rẹ.

Awọn eeyan kan ti isẹlẹ naa soju wọn ni ”Ori lo ko wa yọ ṣugbon ọpọ ninu wa lo farapa bi a ti n sa fẹmi wa, awọn agbebọn naa wọ iboju asọ dudu.

Wọn si n pariwo ‘nibo ni Folarin wa, Iku lo kan ẹ, bẹẹ ni wọn dabọn bolẹ, ti wọn si da gbogbo inu ile ru’’.

Ẹlomii to wa nibi iṣẹlẹ na ni’’a n duro de Folarin, la gbọ ti wọn yinbọn, Ọlọrun lo ko wa yọ."

"Awọn agbebọn bii ọgbon ni wa, ti wọn si gbe ọkọ ayọkẹlẹ mẹwa wa"

Olaniyi ni’’ Awọn agbebọn to to ọgbon ni wọn wa se isẹ ibi naa, ti wọn si gbe ọkọ ayọkẹlẹ mẹwa wa pẹlu erongba ati paa Teslim Folarin’’.

‘’Wọn ro wi pe Folarin yoo wa ni ile lakoko ti wọn wa, nitori o yẹ ki Folarin se ipade pọ pẹlu awọn molẹbi rẹ lalẹ ana.

Sugbọn ko le wa nitori ifọrọwerọ to se pẹlu ile iṣẹ oniroyin kan ni ilu Ibadan’’.

Olaniyi ni awọn ti fi ọrọ naa to awọn ẹsọ alaabo leti, o wa rọ wọn lati fofin mu awọn to wa nidi isẹ ibi naa, ki wọn si fimu wọn kata ofin.

PDP àti APC kọlù ara wọn n‘Ibadan, òkú mẹ́ta sùn

Awọn ọkọ ti wọn bajẹ

Oríṣun àwòrán, APC Oyo

Eniyan mẹta ti padanu ẹmi wọn lasiko ti ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP koju ija si ara wọn nipinlẹ Oyo.

Agbegbe Ile-tuntun nilu Ibadan ni ijọba ibilẹ guusu Ibadan, nipinlẹ Oyo, ni iṣẹlẹ naa ti waye .

Gbogbo agbegbe naa ni lo dakẹ rọrọ lẹyin ti wọn bẹrẹ si ni gburo ibọn kikankikan, ti ọrọ si di ti ẹni ori yọ, o dile.

Oṣojumikoro kan sọ fun awọn oniroyin pe awọn mẹta to ku lasiko iṣẹlẹ naa ti wa ni ile igbokusi.

Bakan naa ni wọn ni asiko ti ẹgbẹ oṣelu APC n ṣe ipade lọwọ ni ọọfisi wọn to wa ni Iyana Court, Ile-tuntun, ni Ibadan, ni awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP n kọja ni agbegbe naa.

Lẹyin naa ni ija bẹ silẹ, ti wọn si fi ẹsun kan ẹgbẹ oṣelu PDP pe awọn ni wọn kọkọ bẹrẹ si ni yinbọn fun awọn eniyan awọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ lati le fi idi otitọ mulẹ lori iṣẹlẹ naa, ki alaafia si jọba nipinlẹ Oyo.

Janduku APC pa Kanselọ ọmọ ẹgbẹ wa mọ ile rẹ niwaju iyawo ati ọmọ rẹ - PDP

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni oun padanu eniyan mẹta ninu ija to bẹ silẹ laarin ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP naa.

Wọn ni awọn onijagidijagan naa lo lọ si ile councillor kan, ti wọn si yinbọn pa a niwaju iyawo ati ọmọ rẹ.

Aṣojuṣofin ni ile igbimọ aṣofin agba ni Naijiria to n ṣoju iha Guusu Ibadan, Honorẹbu Abass Adigun lo fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, lasiko to n ba awọn akoroyin sọrọ.

‘’Emi gangan ni wọn fẹ mu balẹ lasiko ti a n ṣe ipolongo idibo ni agbegbe Orita Aperin si Adesola.

Nigba ti a de agbegbe Ile-Tuntun, ni a ri awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn bẹrẹ si ni ju omi lu wa ati okuta.

Mo sọ fun awọn eniyan mi pe ki wọn ma da wọn lohun, ti mo si pe ọlọpaa ni kiakia.

Ko pẹ lẹyin naa ni mo ri awọn ọmọ ẹgbẹ wa lori kẹkẹ pẹlu ẹjẹ.

Ko pẹ rẹ ni mo gbọ pe wọn ti pa councillor ni ẹkun mi, ni ile rẹ ni Ile-Tuntun ti wọn si pa awọn meji miran.’’

Ohun ti APC sọ ree lori iṣẹlẹ naa ree

Ẹgbẹ oṣelu APC, nigba toun naa n salaye bi isẹlẹ naa se waye ni awọn n ṣe ipade lọwọ ni, oludije lẹgbẹ oṣelu PDP ati aṣojuṣofin to jẹ ọkan lara awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa wa pẹlu awọn alatilẹyin rẹ.

Wọn ni aṣojuṣofin naa ni wọn ri to sadede mu ibọn, to si bẹrẹ si ni yin in ibọn ọhun lu awọn eniyan, ti wahala si bẹ silẹ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC naa fi ara pa yanna-yanna, ti wọn si ni ori lo ko oludije sipo aṣofin ipinlẹ lẹgbẹ osẹlu APC, Warris Alawuje yọ ninu iṣẹlẹ naa.

Alawujẹ sọ fun awọn akọroyin pe oun dupẹ pe ẹmi oun ko lọ si iṣẹlẹ naa amọ ori lo ko oun yọ.

‘’A wa nibi ipade lọwọ ni a gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP n kaakiri agbegbe ọọfisi wa’’

‘’A rọ awọn eniyan wa pe ki wọn duro, ki wọn lọ, amọ laipẹ rẹ ni ilumọọka kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ọhun sọrọ wuyẹ wuyẹ si awọn alatilẹyin rẹ.

Wọn bẹrẹ si ni yinbọn. Ọpọlọpọ fi ara pa, ti wọn si ba awọn ọkọ jẹ ninu iṣẹlẹ naa.’’