Alfa fipá ṣí ọmọdébìnrin mẹ́rin láṣọ wò nílé kéú, ariwo sọ

Aworan obinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọwọ ofin ti tẹ alfa ile keu kan ni ipinlẹ Gombe lori ẹsun pe o fi ipa ba awọn ọmọdebinrin mẹrin sun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Gombe fi idi rẹ mulẹ fun BBC pe ọmọ ọdun mejila, mẹsan ati mẹjọ lawọn ọmọdebinrin naa, ọmọ baba kan naa si ni wọn jẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Gombe, Mahid Mu’azu Abubakar ṣalaye pe alfa naa gangan kọ ni olukọ awọn ọmọdebinrin naa ni ile keu ọhun, o kan n gbe ni ile keu naa naa ni.

“Nigba ti awọn ọmọdebinrin naa wa san owo ẹkọ keu wọn ni Alfa to n kọ wọn ni keu gangan, sọ fun wọn pe ki wọn lọ san owo naa fun alfa to hu iwa kotọ naa, nibẹ ni onitọun si ti fi anfani naa hu iwa kotọ yii pẹlu wọn.”

Alfa tun fi ipa ba ọmọdebinrin baba yii kan naa, to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo pọ, ni asiri se tu

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Mu’azu sọ pe fun igba pipẹ ni iwa buruku yii fi n lọ ṣugbọn ti awọn ọmọdebinrin ọhun ko le sọ fun awọn obi wọn nipa ohun ti oju wọn n ri ni ile keu.

Nigba ti arakunrin miran tun fi ipa ba ọmọdebinrin baba yii kan naa, to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo pọ, ti wọn si gbe ọrọ naa de ọdọ ọlọpaa ni ọrọ ṣe kọlọkọlọ bi ọka ṣe de inu ọka jade sita.

“Alfaa keu naa to jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe igba akọkọ oun niyi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ti gbe awọn ọmọdebinrin naa lọ si ile iwosan fun itọju ti wọn si ti gbe alfaa naa lọ sile ẹjọ.