Nigeria Governorship Election: Ọ̀pọ̀ aráàlú fi èrò wọn hàn lórí ìbò gómìnà tí yóò wáyé ní Sátidé
Ọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun osu Kẹta ọdun 2023 to ko lọla yii ni eto idibo gomina yoo waye lawọn ipinlẹ mejidinlọgbọn lorilẹede Naijiria.
Ni ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ipinlẹ mẹrin pere ni eto idibo gomina yoo ti waye, eyiun ipinlẹ Eko, Oyo ati Ogun, bakan naa si ni ibo naa yoo waye ni Kwara pẹlu.
Eyi lo mu ki BBC Yoruba jade sita lati mọ ero araalu nipa ibo gomina naa.
Nigba ti wọn n ba wa sọrọ, awọn araalu kan gbarata pe aisi owo beba Naira lati na le se akoba fun ibo naa nitori ko si owo kankan lọwọ awọn.
- Wo bí o ṣe lè mọ ibùdó ìdìbò tó yẹ kí o ti dìbò
- Afurasí méjì tó ń fọnrere wàhálà ṣáájú ìbò gómìnà wọ gàù
- Ìdí rèé tí ń kò fi le ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú olùdíje LP, Gbadebo Rhodes Vivour - Jandor
- Mr Macaroni fẹ́ gbé òṣèré tíátà, Lege Miami lọ sílé ẹjọ́, ó ń bèèrè N50m owó ìtanràn
- INEC, Bode George tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ adarí ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ ICT
Ẹnikan ninu wọn ni ipinlẹ Eko ni agọ idibo oun wa, ti oun si n gbe ni Ibadan amọ ko si owo nita boya lẹnu ATM ni lati gba, ki oun fi ri owo mọto lọ dibo.
O fikun pe aisi owo yii naa lo se idiwọ fun oun lati dibo aarẹ to kọya, to si n rọ ijọba lati ko owo sita fun araalu lati na.
Amọ awọn araalu yoku fi ero wọn han pe awọn yoo jade lọ dibo tori ẹtọ ati ojuse awọn ni lati se bẹẹ.
Bakan naa ni wọn leri leka pe awọn ko ni gba owo, ki awọn to dibo nitori awọn ko le ba ọmọluabi ati ọjọ ọla awọn jẹ rara.
- Wo ọ̀nà àbáyọ márùn ún fún obìnrin àti ọkùnrin tó bá lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀
- Wo oríṣì mágùn mẹ́sàn-án tí wọ́n n lé sí ara obìnrin nílẹ̀ Yorùbá
- Èrè tíátà sọ mí dì Àjẹ, n kò mọ̀ pé wọ́n máa ń gba àjẹ́ - Oyiboyi
- Báwo ni Oro ṣe fẹ́ dá àjèjì mọ̀, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Olóyún tó ń rọbí tàbí aláìsàn lásìkò tí Oro bá jáde ní Eko-
- Mọ́tò ya wọlé kan l‘Eko, ọmọ ìyá méjì kú, ọ̀rẹ́ wọ́n farapa



