Brt-Train Accident: Grandma Oreoluwa ní ìlá alásepọ̀ ló ní òun máà se fún òun tó bá dé

Àkọlé fídíò, Brt-Train Accident: Grandma Oreoluwa ní ìlá alásepọ̀ ló ní òun máà se fún òun tó bá dé

Adura ti abiamọ maa n gba ni pe ki oun ma mọ saare ọmọ amọ lọrun lo mọajo alọọde.

Gaga ni ara Oreoluwa Aina ya ni Ọjọbọ, ọjọ kẹsan osu Kẹta ọdun 2023, to si gba ọna ọọfisi to ti n sinru lọ bii agunbanirọ lai mọ pe ko ni pade sile.

Ọmọde adumaradan yii lo wa lara awọn eeyan mẹfa to ku lasiko ti ọkọ ero BRT ko sẹnu ọkọ reluwe ni aarọ Ọjọbọ naa nilu Eko.

Nigba ti BBC Yoruba de ile agunbanirọ naa, a ba iya baba rẹ to n gbe ni ọdọ rẹ ati ẹbi rẹ meji miran.

Nigba to n ba wa sọrọ, Mama agba naa ni Oreoluwa sọ fun oun nigba to n jade nile pe oun yoo wa se ila alasepọ fun oun, ti oun ba de lati ibi isẹ lai mọ pe ko ni pada wa sile mọ.

O wa se apejuwe ọmọ-ọmọ rẹ naa bii olutọju oun, to mọ itọju agbalagba se, kii roju, to si mọ itju ile se.

Bakan naa lo ni Oreoluwa gba ẹkọ, o gbọran, to si tun gba Jesu bii Oluwa ati Olugbala rẹ.

Mama agba naa wa salaye bi wn se tu ọfọ ọmọ naa fun oun.

Bakan naa ni ara ile Ore kan sọ fun wa pe ọmọbinrin naa lo kọ awọn ni orin ti ẹgbẹ akọrin kọ ni ọjọ isinmi to kọja.

O ni ara ko tiẹ fu awọn pe obinrin naa yoo ku ni Ọjọbọ.