Mọ̀ si nípa àìsàn tó ń mú kí obìnrin fẹ́ ìbálòpọ̀ láì sinmi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, àwọn nǹkan tí ènìyàn bá ń rí, ṣe tàbí gbọ́ nígbà mìíràn máa ń ṣokùnfà ohun tó le mú kí ìbálòpọ̀ máa wu ni láti ṣe.
Àmọ́ èyí kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn obìnrin kan nítorí gbogbo ìgbà ni ara wọn máa ń wà lọ́nà láì sí ohunkóhun tó le fa kí ìbálòpọ̀ máa wù wọ́n ṣe.
Fún irú àwọn obìnrin tí irúfẹ́ nǹkan báyìí bá ń ṣe, àwọn onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó gbàgbọ́ wí pé kìí ṣe ojú lásán, irú àwọn àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ní àìsàn kan tó ń báwọn fínra ni.
Orúkọ àìsàn yìí ni wọ́n ń pè ní Persistent Genital Arousal Disorder (PGAD).
Kí ni Persistent Genital Arousal Disorder, PGAD tó wọ́pọ̀ lára obìnrin?
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà nípa ètò ìlera lórí ayélujára tó ń jáde nílẹ̀ Amẹ́ríkà WEBMD ṣe sọ, PGAD jẹ́ àìsàn tó máa ń mú kí ara ènìyàn máa fẹ́ ìbálòpọ̀ láì sí ìdádúró.
Àìsàn yìí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ àmọ́ àwọn obìnrin ni ó máa ń ṣe jùlọ.
Ìwọ̀nba àwọn ọkpunrin péréte ni àìsàn yìí máa ń dà láàmú èyí tí yóò mú kí nǹkan ọmọkùnrin wọn kàn máa le fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàkátì, kódá bí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ìbálòpọ̀ tán.
Ẹni tí àìsàn yìí bá ń dà láàmú, ní kété tó bá ní ìbálòpọ̀ tàn-án, náà ni ara rẹ̀ yóò tún ti wà lọ́nà láì sinmi.
Àwọn tí wọ́n bá lùgbàdì àìsàn yìí kìí lè mú ara dúró àyàfi kí wọ́n rí ọkùnrin tí yóò bá wọn ní àjọṣepọ̀ fún gbogbo ọjọ́ tàbí wákàtí, tí nǹkan náà bá de sí wọn lára.
Nǹkan tó tún wà níbi àìsàn yìí ni pé kò ní ìgbà tàbí àsìkò èyí tó le fi ṣe àwọn tó bá ni lára, ó lé wáyé fún bíi ọjọ́ méjì, mẹ́ta, mẹ́rin, márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Bákan náà ló le máa ṣe obìnrin fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, oṣù tàbí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pàápàá.
Àwọn ìnira tí PGAD máa ń fa fún ara
Ileeṣẹ́ ìròyìn nípa ìmọ̀ ètò ìlera ìyẹn Medical News Today nínú àkọsílẹ̀ wọn kan ní Persistent Genital Arousal Disorder máa ń fa ìnira tó pọ̀ fún obìnrin tó bá ni.
Wọ́n ní gbogbo ojú ara obìnrin tí àìsàn yìí ń bá fínra ni yóò wà nínú ìnira nítorí gbogbo idọ àti ojú ìdí ni yóò máa ró.
Bákan náà ni yóò máa ṣe obìnrin bẹ́ẹ̀ bíi pé ó fẹ́ dà sára, tí gbogbo abẹ́ rẹ̀ yóò sì máa tutù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láì ṣe wí pé ó rí nǹkan tí yóò mu kí ìbálọ̀pọ̀ wù ú ṣe.
Nǹkan obìnrin bẹ́ẹ̀ yóò máa yun fún ọ̀pọ̀ ìgbà, tó sì jẹ́ wí pé tí obìnrin bẹ́ẹ̀ bá dà tán ni yóò tún fẹ́ ìbálòpọ̀ ní ojú ẹsẹ̀.
Àìsàn yìí tún máa ń fa ìrònú àpọ̀jù fún àwọn tó bá ni, àyà wọn a máa já ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí ọkàn sì máa ń pami.
Ọ̀pọ̀ wọn ni kìí fẹ́ ní ìbálòpọ̀ mọ́ nítorí lọ́pọ̀ ìgbà ni ìbálòpọ̀ kìí tán ìṣòro wọn.
Kí ló ń fa Persistent Genital Arousal Disorder?
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí àwọn onímọ̀ ṣe fi múlẹ̀, kò ì tíì si ohun kan pàtó èyí tí wọ́n le nawọ́ sí wí pé òhun ló ń fa àìsàn yìí.
Àmọ́ iléeṣẹ́ Webmd ní lára àwọn nǹkan tó ṣe é tọ́ka sí wí pé ó ń fà á ni ṣíṣe wàhálà púpọ̀ jù.
Bákan náà ni wọ́n ka àwọn ipa tí oògùn mìíràn tí ènìyàn bá ń lò gẹ́gẹ́ bí ohun tó le fa àìsàn yìí.
Iléeṣẹ́ ìròyìn Medical News Today náà fi kun pé àwọn mìíràn tún le lùgbàdì àìsàn látara ilé ìgbọ̀nsẹ̀.
Ìwádìí tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ènìyàn tó bá ní àìsàn Tarlov cysts tún le ní àìsàn yìí.
Ìwádìí iléeṣẹ́ MRI tọdún 2012 ṣàfihàn rẹ̀ pé ìdá mẹ́rìndínláàdọ́rin nínú ìdá ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tó ní Tarlov cysts ló ní Persistent Genital Arousal Disorder.
Ìtọ́jú Persistent Genital Arousal Disorder
Nítorí pé kò ì tíì sí ìwádìí láti fìdí ohun tó ń fa àìsàn yìí múlẹ̀, kò ì tíì sí ìtọ́jú kan ní pàtó èyí tí wọ́n fi ń tọjú àìsàn yìí.
Fún àwọn tó bá jẹ́ wí pé Tarlov cysts ló fa ti wọn, wọn yóò ṣe iṣẹ́ abẹ fún wọn láti yọ Tarlov cysts náà, tí àwọn dókítà sì lè dá oògùn dúró fún ẹni tí wọ́n bá fura sí pé oògùn kan ló ń fà á fun.
Àmọ́ fún àwọn tí wọn kò bá mọ́ okùnfà rẹ̀, wọ́n kàn máa ń ṣe ìtọ́jú ìpalára tí àìsàn náà bá ń fà fún wọn ni.
Báwo ni ènìyàn ṣe lè sá fún àìsàn Persistent Genital Arousal Disorder?
Iléeṣẹ́ ìròyìn Medical News Today ní à ti sá fún àìsàn Persistent Genital Arousal Disorder le nira díẹ̀ nítorí tí wọn kò mọ ohun tó ń fà á.
PGAD kò ì tíì ní ìwòsàn lọ́wọ́ yìí nítorí náà tí ènìyàn bá ń rí àmì àpẹẹrẹ ohun tó jọ ọ́ kí ènìyàn tètè lọ yọjú sílé ìwòsàn ló tọ́ fún àyẹ̀wò tó péye.
Ọlọ́run kò ní fi àìsàn tí kò gbóògùn ṣe wá o.















