Oluwo: Mo nígbàgbọ́ pé ọmọ olóríire ló ti inú Olorì Firdaus jáde

Ayọ̀ abara bíńtín! Oluwo ti Iwo bí ọmọ tuntun làǹtì-lanti

Oluwo ati Olori rẹ

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo land

Oluwo tilu Iwo, ba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu kinni ati Olori rẹ, Firdaus ti bi ọmọ tuntun kan lanti lanti.

Irọlẹ Ọjọru, ọjọ Kẹẹdogun osu kẹta ọdun 2023 ni Oluwo gba alejo ayọ naa.

Atẹjade kan ti akọwe fun eto iroyin Oluwo, Alli Ibraheem fisita fawọn akọroyin lo sisọ loju isẹlẹ ayọ to waye ni aafin Ọba alaye naa.

Amọ Atẹjade naa ko wa yan boya akọ ni ọmọ tuntun naa abi abo ni.

Ọba Adewale ati Olori Firdaus Akanbi

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo land

Mo nigbagbọ nla pe ọmọ oloriire lo ti inu Ayaba Firdaus jade - Oluwo

Nigba to n salaye bi ayọ rẹ ti pọ to, Ọba Akanbi fi ọpẹ nla fun Olodumare fun bo se fi ẹbun ayọ ọmọ ọhun ta ilẹ Yoruba ati ilu Iwo lọrẹ.

Ọba alaye naa wa mọ riri iya ọmọ tuntun ọhun, Olori Firdaus bo se ru u re, to si sọ ọ re.

“Ki eeyan ru oyun fun osu mẹsan, jẹ ohun to lewu pupọ, tori naa ni mo se n ki ayaba mi ku ewu ọmọ tuntun nitori pe o tọ ni ẹni ti eeyan n gbe osuba fun.

Mo si nigbagbọ nla ninu iru eso to ba ti inu rẹ jade, ọmọ naa yoo jẹ oloriire, ti yoo si se rere ju mi lọ.”

Ọpọ eeyan ati awọn eeyan ilu Iwo si lo ti n ba Kabiesi yọ ayọ ọmọ naa.

Oluwo ati Olori tẹlẹ, Chanel

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo Land

Olori Chanel lo kọkọ bi ọmọkunrin kan, Oduduwa fun Ọba Akanbi lori itẹ

Bẹẹ ba gbagbe, iwoyi esin gan ni Oluwo ati Ayaba Firdaus se igbeyawo alarinrin nilu Kano, tii se ilu abinibi Olori naa.

Ọjọ Satide, ọjọ Kọkandinlogun osu Kẹta ọdun 2022 ni Oluwo lọ fẹ ayaba ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa, tii se ọmọ ọba Ado Bayero nilu Kano.

Ayaba Firdaus yii si ni ọmọ Madakin Kano to ti jade laye, Abdullahi Sarkin Sani Yola ati ọmọ ọmọ fun Ọba Ado Bayero to waja.

Amọ Olori Firdaus kọ ni Olori akọkọ fun Ọba Adewale Akanbi ni aafin Iwo nitori o ti kọkọ fẹ Olori kan, Chanel Chin lati ilẹ Jamaica.

Amọ ni bii ọdun mẹta sẹyin ni igbeyawo naa tuka, ti ba si kọ Olori naa silẹ

Sugbọn Ọba oke si fi ọmọkunrin kan lanti lanti sinu igbeyawo naa, ti orukọ rẹ n jẹ Oduduwa.

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Oluwo ṣèrànwọ́ owó, oúnjẹ, ẹ̀rọ ìránṣọ fàwọn aráàlú torí ọ̀wọ́n gógó náírà

Oluwo, Oba Abdulrosheed Akanbi lasiko to n pin ounjẹ fawọn ara ilu.

Oríṣun àwòrán, OLUWO

Nítorí bí owó náírà ṣe di ọ̀wọ́n gógó tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kò rí owó ná, Oluwo ti ìlú Iwo, Oba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti ṣe ìrànwọ́ owó, irinṣẹ́ àti ohun èèlò fún àwọn ènìyàn igba tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Iwo.

Ìkúnpá náà ni pínpín ẹ̀rọ ìránṣọ, ẹ̀rọ ìlọta àtàwọn oúnjẹ bíi ìrẹsì, Semo àti òróró fáwọn ènìyàn láti mú àdínkù bá ìṣòro táwọn ènìyàn náà ń kojú.

Oba Akanbi tún fún àwọn ọlọ́jà tó ń ta ọjà kéékèèké ní owó ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà láti fi ran okoòwò wọn lọ́wọ́.

Oluwo wá kọminú lórí ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọ̀wọ́n gógó owó náírà ti gbalẹ̀ pẹ̀lú ìrètí pé ìwọ̀nba ètò ìrànwọ́ náà yóò ṣe ohun díẹ̀ nínú okoòwò wọn.

Ẹ̀rọ ìránṣọ ti Oluwo pín fun awọn ara ilu

Oríṣun àwòrán, OLUWO

"Mo mọ nǹkan ti àwọn ènìyàn ń là kọjá ní àsìkò yìí pàápàá àwọn ọlọ́jà wóróbo"

Oba alayé náà ní gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà tó rọ́wọ́ fi họrí ló yẹ kí wọ́n dìde sí ọ̀rọ̀ ìpèníjà tí ọ̀wọ́n gógó náírà ń kóbá àwọn ènìyàn.

O sì tún rọ ìjọba ni ẹlẹkajẹka lati tun ran àwọn olókoòwò kékeré lọ́wọ́ lásìkò yìí.

Ẹ̀rọ ìránṣọ ọgbọ̀n, ẹ̀rọ ìlọta mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ báàgì ìrẹsì, Sẹmo àti òróró ni Oluwo pín fún àwọn ènìyàn ìjọba ìbílẹ̀ Iwo, Ayedire àti Ola Oluwa.

“Mo mọ nǹkan ti àwọn ènìyàn ń là kọjá ní àsìkò yìí pàápàá àwọn ọlọ́jà wóróbo, àsìkò tí èèyàn le ṣe ìrànwọ́ fáwọn tó ń la ìṣòro kọjá nìyí.”

Ẹ̀rìlọta tí Oluwo pin fun awọn ara ilu.

Oríṣun àwòrán, OLUWO

"Àwọn ènìyàn mi máa mú àlékún bá nǹkan kékeré tí ènìyàn bá fún wọn"

Ọba Akanbi tẹsiwaju pe “Mo ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn mi máa mú àlékún bá nǹkan kékeré tí ènìyàn bá fún wọn.

Ìdí niyi tí mo fi pín àwọn ẹ̀bùn yìí ni láti ran àwọn ènìyàn ìlú mi lọ́wọ́.”

“Àwọn tó ń kọ́ṣẹ́ ìránṣọ lọ́wọ́, tí wọn kò ní owó láti ra ẹ̀rọ ìránṣọ la pín wọn fún.

Bakan naa, a wo àwọn tó nílò ẹ̀rọ ìlọ́ta náà dáadáa kí a tó pin fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”

“A tún pín ẹgbẹ̀rún márùn-ún náírà fún àwọn ènìyàn tó lé ní àádọ́ta, tí mo sì ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn tó jẹ àǹfàní ètò yìí máa ṣàmúlò rẹ̀ dáadáa.”

Ẹ ó rántí pé kò pẹ́ tí Ọba Abdularosheed gorí àpèrè àwọn bàbá rẹ̀, ló ṣe àgbékalẹ̀ ètò fífún àwọn opó àti àwọn tó kù díẹ̀ káàtó fún ní oúnjẹ àti aṣọ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.

Oluwo, Oba Abdulrosheed Akanbi lasiko to n pin ounjẹ fawọn ara ilu.

Oríṣun àwòrán, OLUWO