Oluwo of iwo: Ojú olorì tuntun tí yóò wọ ilé Oluwo lónìí rèé

Oluwo's wife

Oríṣun àwòrán, Oluwo

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Akanbi ti ṣi aṣọ loju eegun olori rẹ tuntun.

Ọba Akanbi lo fi oju olori naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ di BBC Yoruba lọjọ Abamẹta.

Ṣaaju ni a ti kọkọ jabọ fun yin pe Oluwo yoo gbe ọmọba Ado Bayero ti ilu Kano ni iyawo lonii, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022.

Àkọlé fídíò, Oluwo‘s Wedding: Àwọn èèyàn ìlú Iwo ní àwọn ń fojú sọ́nà láti tẹ́wọ́gba aya tuntun

Orukọ olori tuntun naa ni ọmọba Firdauz Abdullahi.

Iroyin ni igbeywo naa yoo waye nile Madakin ti ilu Kano laagọ mọkanla aarọ.

Oluwo's wife

Oríṣun àwòrán, Oluwo

Lẹyin naa ni wẹjẹ-wẹmu yoo tẹle ni aafin Emir ilu Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero laago mẹrin irọlẹ.

Igbeyawo Oluwo akọkọ fori ṣọpọn

Kii ṣe igba akọkọ ree ti Ọba Abdulrosheed Akanbi yoo ṣe igbeyawo.

Ṣaaju lo ti kọkọ fẹ obinirin kan, Chanel Chin, to jẹ ọmọ orilẹ-ede Jamaica.

Amọ igbeyawo naa tuka lẹyin oniruru ede aiyede laarin awọn mejeji, ti obinrin ọhun si fi Oluwo silẹ, to si ba tirẹ lọ lẹyin to bi ọmọ kan fun un.

Chanel Chin sọ fun akọroyin ati ninu oniruru atẹjade to maa n gbe sori ayelujara pe inu oun ko dun ninu igbeyawo naa, ati pe ọkan oun ko bale nibẹ.

Àkọlé fídíò, Roheem Bamimore: Ará àdúgbò ní àwọn afurasí tó pa ọmọ náà ti máa ń jalè tẹ́lẹ̀