Ọkọ̀ ẹ̀yìn gómìnà Katsina ko ìjàmbá mọ́tò ní ìdìbò ku ọ̀la, èèyàn mẹ́ta kú

Aworan ijamba mọto

Oríṣun àwòrán, The Nation

Eniyan meͅta ti soͅ eͅmi wọn nu ni aleͅ oͅjoͅ ti idibo ku olaͅ nipinleͅ Katsina.

Eyi waye nigba ti oͅkoͅ ti o maa n saaju oͅkoͅ ti gomina ipinleͅ Katsina woͅ, ko agbako ijamba oͅkoͅ.

Agbegbe ijoͅba ibileͅ Musawa ni opopona Jikamshi ni isͅeͅleͅ naa ti waye.

Adari eͅka eto iroyin fun gomina ipinleͅ Katsina fi idi isͅeͅleͅ naa muleͅ to si ni oͅloͅpaa meji ati araalu kan lo ku ninu isͅeͅleͅ naa.

Arakunrin Isa ni gomina Masari naa wa loͅna ile reͅ ni ijoͅba ibileͅ Kafur lati lọ darapoͅ moͅ eto idibo sipo gomina ati ti idibo asofin nigba ti isͅeͅleͅ naa waye.

Agbeͅnusoͅ ileesͅeͅ oͅloͅpaa nipinleͅ naa ni lootoͅ ni ijamba naa waye amoͅ ko lee soͅ pupoͅ nipa isͅeͅleͅ oͅhun.

Bakan naa ni woͅn fikun un pe iwadii ti beͅreͅ lori isͅeͅleͅ naa.

Jàǹdùkú ya bo ilé olùdíje sílé àṣòfin l‘Ondo, wọn ba ọkọ́ àti ilé rẹ̀ jẹ́

Aworan

Awọn janduku oloṣelu kan ti n da omi alaafia ilu ru nigba to ku ọjọ diẹ ki idibo waye ni ilu Owo, nipinlẹ Ondo.

Ibẹ ni wọn ti sekọlu sile oludije si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa fẹgbẹ oṣelu ‘’New Nigeria People's Party’’, Emmanuel Taiwo Adekunle, ETA, ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ nibẹ.

Awọn oṣojumikoro wipe oludije naa ni wọn n lepa ẹmi rẹ, amọ ti aisi nile rẹ jẹ ki wọn ba ọkọ ati ile naa jẹ.

"Awọn alatilẹyin mi ṣe iwọde lọ aafin Ọlọwọ, awọn oloye ni ka lọ sọ fun agbofinro"

Gẹgẹ bi oludije naa ṣe wi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, nkan bii aago mẹjọ alẹ Ọjọbọ ni ikọlu naa waye, lẹyin bii ogun iṣẹju to jade kuro nile.

Adekunle nii “aago meje kọja diẹ ni mo jade kuro nile.

Ko ju ogun iṣẹju lọ ti mo kuro nile, ni awọn eeyan pe mi pe awọn janduku kan ti yabo ile mi pẹlu ibọn, ada, ati oniruuru ohun ija, ti wọn si ba ile ati ọkọ jẹ.

Ore-ọfẹ Ọlọrun lo yọ mi pe mo ti jade kuro nile”.

Oludije ẹgbẹ NNPP naa ni eyi lo mu ki awọn alatilẹyin ohun ṣe iwọde lọ aafin Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, ti awọn oloye si ni ki ohun lọ fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.

Adekunle fikun pe bi o tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ti pe awọn mejeeji si ipade lati rọ wọn ki wọn gba alaafia laaye.

Aworan

"Ìwọ́de alálàáfíà ni à n ṣe, tí wọ́n fi fọ́ mi lórí’’

Ẹwẹ, lakoko ti wọn ṣe iwọde ifẹhonuhan lọ agọ ọlọpaa, ni awọn janduku miran tun ṣe akọlu si wọn.

Ọkan lara awọn to farapa nibi akọlu ẹlẹẹkeji ọhun to waye laarọ Ọjọbọ, Kemisola Adebiyi, wipe ori ere lohun wa, ti wọn fi fọ ohun lori.

Kemisola, to jẹ ọkan lara awọn to n fi ẹhonu han lori ikọlu ti wọn ṣe si ile Adekunle sọ pe “bi a ṣe de aafin Ọlọwọ, awọn oloye ni ki a lọ si ọgba awọn ọlọpa la ti fi ẹjọ sun tori pe kabiyesi ko si nile.’’

‘’ Bi a ṣe n lọ lọna ni a ri ọkọ ẹgbẹ oselu APC ti wọn wa gunlẹ si oju kan, tawọn to wa ninu rẹ si bẹrẹ sii bu wa.

Ka too wi, ka too fọ, wọn ti n fi igo, ada ati okuta le wa.

Nigba ti mo raye duro ni mo to o mọ pe wọn ti fọ mi lori”.’’

N kò mọ nkankan nípa àkọlù tí wọ́n ṣe - Asofin Oluwole Ogunmolasuyi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ondo, to jẹ olori ọmọ-ile to pọ julọ, to si tun jẹ oludije lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, fun ẹkun Ọwọ kini, Emmanuel Oluwole Ogunmolasuyi lo ti salaye tiẹ.

O ni pe ahesọ ọrọ ni pe awọn alatilẹyin oun lo ṣe ikọlu si alatako rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu NNPP.

Ogunmolasuyi ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba wipe “lootọ ni mo gbọ nkan to jọ bẹẹ, amọ ẹgbẹ wa kii ṣe ẹgbẹ oni jagidijagan.

Kete ti a gbọ ọrọ naa ni mo lọ agọ awọn ọlọpaa lati mọ ohun to ṣẹlẹ”.

Ogunmolasuyi tẹsiwaju pe “nigba ti mo de agọ ọlọpaa, wọn ni ko tii si ẹnikẹni to wa fi ọrọ lọ awọn leti nibẹ.

Wọn si ti ranṣẹ pe alatako mi to ke gbajare ọrọ naa, ti wọn si rọ awa mejeeji lati gba alaafia laaye.

A si fi da awọn agbofinro loju pe alaafia ilu Owo lo jẹ wa logun”.

Aṣofin naa fikun pe “oniruuru ete ni awọn oloṣelu n ta lakoko ibo.

O ṣeeṣe ko jẹ pe ọna lati mu ki awọn araalu dibo aanu fun wọn ni wọn ṣe da iru ọgbọn alumọkọrọyi yii.

O dami loju pe emi ati awọn alatilẹyin mi ko ni ohunkohun ṣe pẹlu dida ilu ru”.

Aworan

Ohun tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà rèé

Alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya ni awọn ti pari ija fun awọn oludije mejeeji, ti ko si si laasigbo kankan mọ.

Odunlami-Omisanya wipe ni tootọ lawọn gbọ pe awọn janduku kan fẹ da ilu Owo ru, nitori oṣelu.

Amọ o ni awọn ti pe awọn oludije mejeeji si ipade alalaafia, ti wọn si ti ṣeleri nipa titi ọwọ bọ iwe adehun lati kilọ fun awọn alatilẹyin wọn lati yago fun iwa to le fa idarudapọ laarin ilu.

Omisanya fikun pe ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ naa ko nii faaye gba iwa jagidijagan kankan lasiko ati lẹyin idibo ọjọ Abamẹta yii.