Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà figbe ta pé jàǹdùkú fẹ́ gún òun lọ́bẹ ní àgọ́ ìdìbò

Chioma Akpota

Oríṣun àwòrán, chiomakpotha/Instagram

Gbajumọ osere tiata lede Oyinbo, Chioma Akpota ti ke gbajare loju opo ayelujara Instagram rẹ pe awọn janduku kan kọlu oun.

Chioma, ti ara rẹ n gbọn tori isẹlẹ naa ni, oun yiju ọkọ pada kuro lọna ibi ti oun doju kọ nitori awọn janduku naa ti wọn yọ ọbẹ lati gun oun.

Agbegbe Lagos Island nilu Eko si ni gbajumọ osere tiata naa ti lọ dibo, to si se ayẹwo orukọ amọ to ni oun ko le dibo.

Chioma Akpota lede pe “Se ni mo sa asala fun ẹmi mi, mo sa kuro ninu ọkọ naa, ti n ko si le sọ bi wọn se ba mọto naa jẹ si.

Wọn fọ digi ẹgbẹ ọkọ mi, ti wọn si tun ba awọn apa kan ọkọ mi jẹ, n ko tiẹ roju mu foonu mi lati ka awọn ohun to n sẹlẹ silẹ.

Chioma Akpota figbe ta pé òun ṣe àyẹ̀wò orúkọ àmọ́ tọ́ọ̀gì fi ọ̀bẹ lé òun ní àgọ́ ìdìbò

Awọn janduku naa n mu ọbẹ jade, wọn fẹ gun mi, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe mo wa pẹlu awọn eeyan kan.

Mo n lọ sibi ti awọn ọmọ ologun duro si ni agbegbe VGC, mo si n lọ sọ fun wọn nipa ohun to sẹlẹ.

O ti su mi, n ko tiẹ mọ ohun ti eeyan fẹ sọ mọ, ki lo sẹlẹ si eto idibo ti ko ni mọdaru ninu ti wọn seleri fun wa.”

Chioma Akpota wa n pariwo pe ko si nnkan to lọ geerege bo se yẹ pẹlu afikun pe se ni wọn kan n dunkooko mọ awọn eeyan kiri.

Bo si se ri ọkọ ologun ti wọn gbe kalẹ lagbegbe VGC naa lo duro lati salaye ohun to sẹlẹ si wọn.

"Ẹgbẹ oselu Labour Party ni mo n ti lẹyin lati oke de isalẹ"

Chioma Akpota tẹsiwaju pe alatilẹyin ẹgbẹ oselu Labour Party ni oun se lati oke de isalẹ.

O ni bi Peter Obi ba tiẹ gba ẹtọ rẹ pada, to si di aarẹ , ọpọ ijakulẹ lo wa nilẹ fun ti ko ba ni awọn gomina, asoju-sofin atawọn ọmọ ile asofin ipinlẹ ti yoo ti lẹyin.

Ẹgbẹ oselu LP ko wa fun ipo aarẹ nikan amọ igbimọpọ lati le awọn iwa kotọ to ti wa pẹlu wa, fun ọjọ pipẹ kuro.

Ki wa lo de ti ijọba to dantọ yoo fi maa se ẹru bawọn eeyan pẹlu janduku?

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Àkọlé fídíò, Agbaje sọ èyí nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀.

Ẹ̀gbọ́n mi ni 'ìyá Chukwudi' n kò ní èròńgbà búburú - MC Oluomo

Aworan Mc Oluomo

Oríṣun àwòrán, MC Oluomo

Alaga ẹgbẹ awọn awakọ ati gareji ni ipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya, ti ọpọ mọ si MC Oluomo ti ke gba ja ri sita pe oun ko ni erongba buburu si ẹnikẹni lori fọnran kan to n ja kiri lori ayelujara

Mc Oluomo ni ẹgbọn oun ni Iya Chukwudi ti oun ba sọrọ lori fọnran naa to ma ta Indomie fun oun.

Nigba to n sọrọ lori fọnran tuntun to gbe sori opo ayelujara rẹ, Akinsanya ni oun iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti oun bẹrẹ si ni ma ri awọn iroyin kan lori ayelujara pe oun ko irira awọn ẹya igbo nipinlẹ Eko.

O ni: "Ipade ti mo lọ ni ana ni mo ti n ba ẹgbọn mi kan sọrọ pe Iya Chukwudi, to ba timọ pe o ni dibo fun mi joko sile o

"Ko pẹ ni mọ bẹrẹ si ni ma ri awọn iroyin lori ayelujara ti wọn darukọ mi.

"Gbogbo eeyan lo mọ pe eeyan alaafia ni mi ni gbogbo igba, ti ẹ ba dẹ wo nipinlẹ Eko, ipinlẹ alaafia ni.

"Ki ni idi ti maa fi ni ki awọn eeyan ma jade wa dibo, ti wọn ko ba jade wa dibo, bawo ni ẹgbẹ oṣelu APC se fẹ wọle.

"Bawo ni igbo ati Hausa ko se ni dibo fun awa APC, ẹ yọ mi kuro ninu awọn to ni erongba buburu."

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí fọ́nrán tí wọ́n ní MC Oluomo ti ń dúnkokò sáwọn ènìyàn lórí ìdìbò gómìnà - Ọlọ́pàá

Aworan MC oluomo ati Kọmisọna ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Google

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fesi lori fọran kan to ja kiri lori ayelujara, ni bi ti alaga ẹgbẹ awọn awakọ ati gareji ni ipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya, ti ọpọ mọ si MC Oluomo ti n dunkoko sawọn eniyan lori eto idibo gomina.

Kọmisọna fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Idowu Owohunwa lo kede ọrọ sita nigba to n kopa ninu ifọrọwerọ kan to se pẹlu ileeṣẹ Arise Tv.

MC Oluomo, ninu fọran ọhun lo ti n dunkoko mọ awọn ẹya Igbo niluu Eko to kọ lati dibo fun ẹgbẹ oṣelu to n ṣe atilẹyin fun, APC lati duro sile lasiko idibo.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

O ni, "A ti bẹ wọn, sugbọn ti wọn ba ni awọn ko ni dibo fun wa, ko si n se ija.

"Ẹ sọ fun wọn, Mama Chukwudi, ti ẹ ba ni dibo fun wa, ẹ joko sile."

Nigba to n fesi Owohunwa ni iwadii ti bẹrẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti bẹrẹ lati ma yanayana fọran naa.

"Bẹni, a mọ nipa fọran naa, gbolohun ati idunkoko naa ti ti a si ti bẹrẹ iwadii lori wọn.

''Ti awọn ọrọ ba tako ofin ilẹ wa, nitori ko ẹnikẹni ko kọja ofin ati iwa wa ti a wa lori da le lori gbigbe ofin duro.

'Ti a ba kẹfin pe awọn ọrọ naa tako ofin , a gbe igbesẹ lori awọn ẹsun naa."