Ọ̀pọ̀ eré tíátà ni mo pàdánù torí ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣe mí lése ní ẹsẹ̀ - Basira Beere

Oríṣun àwòrán, basira_beere/Instagram
Òṣèré tíátà kan lédè Yorùbá, Adeola Yusuf Kafilat Omoshalewa, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Basira Beere, ti ṣàlàyé àwọn ìpèníjà tó là kọjá nínú iṣẹ́ tíátà nítorí ẹsẹ̀ tó ń dùn-ún.
Basira Beere, nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú Ojopagogo TV lórí ayélujára ní òun rò pé gbogbo nǹkan ti tán fún òun nídìí iṣẹ́ tí òun yàn láàyò lórí ẹsẹ̀ òun.
Basira Beere ní òun ní ìjàmbá mọ́tò, èyí tó mú kí ẹsẹ̀ máà dun òun.
Ó ní osu meji ni wọn fi to ẹsẹ naa laimọ pe wọn ko to o rara, lẹyin osu kẹta lo ni wọn sọ pe ẹsẹ naa ti n jẹra, ti wọn si fẹ ge.
Ó ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n gbé fún òun ló fo òun ru nítorí ọ̀pọ̀ àwọn olùdarí eré máa ń sọ wí pé òun kò lè kópa nínú àwọn eré kan nítorí ẹsẹ̀ tó ń dun òun.
"Ìjàmbá ọkọ̀ tí mo ní ní Challenge Ibadan ló kán mi lẹ́sẹ̀"
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí ó ṣe ní ìpalára lẹ́sẹ̀, Basira Beere ni kìí ṣe wí pé wọ́n bí ẹsẹ̀ náà mọ́ òun bẹ́ẹ̀ bíkòṣe wí pé ìjàmbá ẹsẹ̀ tí òun ní ló fa àléébù náà sí òun lára.
Ó ṣàlàyé pé òun jáde láti tẹ̀lé ènìyàn kan lọ ṣe MC níbì kan tó sì jẹ́ wí pé alẹ́ ni àwọn tó parí níbi òde tí àwọn lọ ọ̀hún.
Ó ní nígbà tí òun ń padà sílé ní òun ní ọkọ̀ kan tó ń múdìí bọ̀ tó sì gbá òun láti ẹ̀yìn.
“Aṣọ mi kọ́ mọ́tò wọn, wọ́n wọ́ mi láti roundabout Ìyá ni wúrà ní Challenge, wọ́n fẹ̀ẹ́ wọ́ mi dé Mr Biggs kí wọ́n tó mọ̀ wí pé àwọn ń wọ́ èèyàn.”
“Gbígbé tí wọ́n fẹ́ gbé ẹsẹ̀ mọ́tò wọn kẹ́yìn ni wọ́n gorí ẹsẹ̀ mi tí ẹsẹ̀ mi fi kán sí méjì.”
“Mi ò lérò wí pé mo le fi fi ẹsẹ̀ mi rìn mọ́ láyé nítorí ní ọjọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ tú POP tí wọ́n fi tò ó, níṣe ni ẹsẹ̀ mi dàbí ìgbálẹ̀, oṣù mẹ́fà ni mo lò nílé láì lè rìn tàbí ṣe ohunkóhun.”
“Wọ́n ti kọ́kọ́ ní wọ́n máa gé ẹsẹ̀ mi kí Ọlọ́run tó padà gba àkóso”
“Gbogbo àwọn ẹ̀gbọ́n mi àti àwọn ẹbí mi ti ń rò ó pé mi ò le fi ẹsẹ̀ mi rìn mọ́, ọjọ́ yẹn ni inú mi bàjẹ́ jùlọ nítorí mo ké gidi.”
“Mo rò wí pé gbogbo wàhálà mi nídìí iṣẹ́ tíátà ti parí ni.”
"Torí iṣẹ́ tíátà, ìyá mi ní òun yóò já mi sí ìhòòhò, bàbá mi ní kí ń fi Kùránì burá pé òun kọ̀ mí lọ́mọ"
Basira Beere nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjò rẹ̀ nídìí iṣẹ́ tíátà ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ jẹ́ èyí tó le díẹ̀ fún òun nítorí àwọn òbí òun ko kọ́kọ́ lọ́wọ́ sí iṣẹ́ tí òun yàn láàyò.
Ó ní ìyá òun máa ń sọ wí pé àwọn máa já òun sí ìhòhò tí òun kò bá gbọ́ àti pé bàbá òun ti fi ìgbà kan gbé kùránì lé òun lọ́wọ́ láti fi búra pé òun kò ní ṣiṣẹ́ tíátà mọ́.
Ó fi kun pé bàbá òun kì òun nílọ̀ pé òun kò gbọdọ̀ jẹ́ orúkọ ẹbí àwọn mọ́, tí òun kò bá kọ̀ láti fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀.
Ó ní inú òun dùn báyìí pé àti ìyá àti bàbá òun tó fi mọ́ àwọn ẹbí òun pátápátá ni wọ́n máa ń fi òun yangàn láti ara iṣẹ́ tíátà náà.
"Àwọn oríṣiṣíri eré ló yẹ kí n ṣe àmọ́ ìjàmbá ọkọ̀ gba ọ̀pọ̀ iṣẹ́ lọ́wọ́ mi"
Basira Beere ṣàlàyé pé nígbà tí ẹsẹ̀ òun ṣẹ̀ṣẹ̀ san, òun kò lè rìn dáadáa nítorí náà òun pàdánù àwọn eré tó yẹ kí òun kópa nínú rẹ̀ dáadáa.
“Àwọn oríṣiṣíri eré ló yẹ kí n ṣe nígbà yẹn tí wọ́n ní rárá àwọn ò lè fún mi nítorí ẹsẹ̀ mi.”
“Wọ́n máa ń ní kò lè sáré, ẹ fi sílẹ̀, ẹ má à jẹ́ kó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣe wàhálà, iṣẹ́ náà yóò sì bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́.”
Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ iṣẹ́, ó ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ojú máa ń ti òun láti ṣe àwọn nǹkan láwùjọ tàbí wọ aṣọ tó bá wu òun nítorí ìtìjú ẹsẹ̀ tó ń dun òun.
Ó ní àwọn èèyàn mìíràn tí wọ́n bá rí òun níta máa ń wo òun láwòjù, tí àwọn mìíràn tilẹ̀ máa ń sọ fún òun pé àwọn ò mọ̀ pé ẹsẹ̀ ń dun òun pé inú fíìmù kan ni àwọn ti ri.
Muyiwa Ademola ló gbé ìtìjú ẹsẹ̀ mi kúrò lára mi
Basira Beere tẹ̀síwájú pé lọ́pọ̀ ìgbà tí òun bá jókòó tàbí tí òun rí àwọn akẹgbẹ́ òun tí wọ́n ń wọ nǹkan tó bá wù wọ́n ni ọkàn òun máa ń gba ọgbẹ́ nípa ẹsẹ̀ òun.
Ó ní Muyiwa Ademola ló sọ fún òun pé òun kò nílò láti máa gbé ẹsẹ̀ òun pamọ́ fún arayé wí pé àmì ni ìṣòro tí òun là kọjá jẹ́ fún òun.
Ó fi kun pé Muyiwa Ademola ṣàlàyé pé tí àwọn ènìyàn bá bèèrè pé kí ló ṣe òun lẹ́sẹ̀ kí òun ṣàlàyé pé òun ní ìjàmbá ọkọ̀ ni, pé kò jù bẹ́ẹ̀ lọ.
“Má rìí ẹsẹ̀ rẹ̀ bíi àléébù, jẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ri pé ara oore Ọlọ́run ni pé o ṣì tún le máa fi ẹsẹ̀ rẹ méjéèjì rìn”
Ó ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run báyìí nítorí òun le fi ẹsẹ̀ òun rìn, wọ nǹkan tó bá wu òun nítorí òun kò rí ẹsẹ̀ òun gẹ́gẹ́ bí àléébù kankan mọ́.
“Mo ti le fi ẹsẹ̀ mi sáré báyìí, wọ bàtà gíga àmọ́ nígbà tí mo ri gẹ́gẹ́ bí àléébú, à ti sáré máa ń nira fún mi.”
Ta ni Basira Beere?

Oríṣun àwòrán, Basira Beere/Instagram
Òṣèré tíátà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lágbo eré Yorùbá ni Adeola Yusuf Kafilat Omoshalewa tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Basira Beere.
Òun ni àbíkẹ́yìn ìyá rẹ̀ tó sì ti lé ni ọgbọ̀n ọdún.
Ilé ẹ̀kọ́ St Luis Primary School ló ti kẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kó tó tẹ̀síwájú sí Olubi Memorial Grammar School, Molete, Ibadan níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ girama.
Ilé ẹ̀kọ́ Alayande College of Education ló ti gba ìwé ẹ̀rí olùkọ́ni NCE.
Ní ọdún 2009 ló bẹ̀rẹ̀ eré tíátà lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, Bose Odogboro ní ìlú Oyo àma ọdún 2011 ló mú iṣẹ́ tíátà ní òkúnkúndùn lẹ́yìn tó parí NCE rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bíi Oyenusi, Omo Esu, Ipade àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló ti kópa.















