Wo kókó àyípadà 16 tí Buhari ṣe sí ìwé òfin Nàìjíríà lẹ́sẹẹsẹ

Oríṣun àwòrán, Collage
Igbákejì Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ahmed Idris Wase ní Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lu àwọn àtúnṣe mẹ́rìndínlógún òfin tó wà nínú ìwé òfin Nàìjíríà.
Wase, tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ tó rí sí àtúnṣe ìwé òfin Nàìjíríà tọdún 1999, kan sáárá sí Ààrẹ Buhari fún bó ṣe buwọ́lu àwọn àyípadà náà.
Ó ní àyípadà àwọn òfin yìí, àwọn ìpínlẹ̀ yóò ní agbára si ju ti àtàyìn wá lọ àti pé gbogbo agbára àti àkóso Nàìjíríà kò ní wà lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ nìkan.
Lára àwọn òfin tí ààrẹ Muhammadu Buhari ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lu náà ni èyí tó fi ààyè gba àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ àti ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ láti máa ṣe àkóso owó wọn fúnra wọn láì sí lábẹ́ àwọn gómìnà mọ́.
Ó wòye pé mẹ́rin nínú àwọn òfin tuntun náà fi ààyè gba díndín agbára ìjọba àpapọ̀ kù tó sì tún pọkún agbára àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ẹ̀ka ètò ìdájọ́ ti ìpínlẹ̀.
Òfin mìíràn tó wà lára àwọn àtúnṣe tí ààrẹ tọwọ́bọ̀ náà ni èyí tó fi dandan le pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ tàbí gómìnà gbọdọ̀ yan àwọn mínísítà àti àwọ kọmíṣọ́nà láàárín oṣù méjì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti búra wọlé fun tán.
Nínú oṣù Kìíní ọdún yìí ni ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ fi àwọn àtúnṣe òfin márùndínlógójì nínú ìwé òfin Nàìjíríà ṣọwọ́ sí ààrẹ Buhari fún ìbuwọ́lù.
Àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ló ti ṣe àgbéyẹ̀wó àwọn òfin yìí tí ìpínlẹ̀ mẹ́rìnlélógún sì ti faramọ́ ìgbésẹ̀ yìí kí wọ́n tó fi ṣọwọ́ fún ìbuwọ́lù ààrẹ gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe làá kalẹ̀.
Àma àwọn ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ náà kọ̀ láti buwọ́lu òfin èyí tó ń pè fún fífún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láàyè láti máa ṣètò owó wón fúnra wọn.
Àwọn àtúnṣe òfin tí ààrẹ Buhari buwọ́lù nìyí:
- Yíyí orúkọ ìjọba ìbílẹ̀ Akifpo North àti Afikpo South padà
- Yíyí orúkọ ìjọba ìbílẹ̀ Kunchi padà
- Yíyí orúkọ ìjọba ìbílẹ̀ Egbado North àti Edgbado South padà
- Ṣíṣe àtúnṣe sí orúkọ ìjọba ìbílẹ̀ Atigbo àti àwọn nǹkan tó bá fi ara pẹ.
- Ṣíṣe àtúnṣe sí orúkọ ìjọba ìbílẹ̀ Obia/Akpor àti àwọn nǹkan tó bá fi ara pẹ.
- Fífi ààyè gba àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ àti ẹ̀ka ìdájọ́ ìpínlẹ̀ láti máa lè ṣètò àti ná owó wọn fúnra wọn.
- Láti ṣe àmójútó àwọn tí wọ́n bá dìbò yàn sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ àti sí ti àwọn ìpínlẹ̀ káàkiri Nàìjíríà.
- Pípa òfin tó fàyè gbà títọ́ka sí àwọn kó òfin tó de ìwà ọ̀daràn àti àwọn òfin pẹ́pẹ̀pẹ́.
- Yíyọ ìgbà àti àsìkò tí àwọn ètò kọ̀ọ̀kan bá wáyé kúrò nínú iye àsìkò láti fi gbọ́ ẹ̀hónú ìbò àti àwọn ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí èsì ìbò.
- Láti fi ààyè gba pé ìpolongo fún ipò Akọ̀wé ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀ka ìdájọ́ ìyẹn National Judicial Council tí wan bá fẹ́ gba ènìyàn sí ipò náà.
- Pípáàrọ̀ orúkọ ọgbà ẹ̀wọ̀n kórò ní “prísons” sí “Correctional Services” àti yíyọ ẹ̀ka náà kúrò lábẹ́ èyí tó jẹ́ wí pé ìjọba àpapọ̀ nìkan ló ní àṣẹ lórí rẹ̀.
- Yíyọ ẹ̀ka ìrìnnà ojú irin reluwé kúrò ni èyí tí ìjọba àpapọ̀ le ṣòfin lórí rẹ̀.
- Fífi ààyè gba àwọn ìpínlẹ̀ láti máa pèsè iná mọ̀nàmọ́ná fúnra wọn, kí wọ́n sì máa pin iná bẹ́ẹ̀ sí àwọn àyè tó bá wà lábẹ́ iná ìjọba àpapọ̀.
- Ríri dájú pé ààrẹ tàbí gómìnà tí wọ́n bá búra wọlé fun fi orúkọ àwọn ìgbìmọ̀ tí yóò bá ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí mínísítà àti kọmíṣọ́nà ṣọwọ́ ilé ìgbàmọ̀ aṣòfin láàárín oṣù méjì.
- Láti ṣe àtúnṣe sí àṣìṣe tó wà lórí ààlà oríkò ìjọba Nàìjíríà ìyẹnn Abuja.
- Ri dájú pé ìjọba ń gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti ri pé oúnjẹ tó tọ́ ni àwọn ènìyàn ń jẹ àti pé oúnjẹ pọ̀ yantutu ní ìlú.















