Wo àwọn ìpínlẹ̀ tó le gbóná àti òpó mẹ́fà tó lé nípa lórí èsì ìbò gómìnà

Awọn osisẹ eleto idibo

Bi eto idibo gomina se n waye loni ọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun osu Kẹta ọdun 2023, ajọ eleto idibo, INEC, ọpọ oludibo, oloselu, awọn agbofinro ati ajọ oloselu lo ti gbararadi fun eto idibo naa.

Koda, igbaradi naa ko yọ awọn akọroyin silẹ, to fi mọ awọn onwoye ibo ni abẹle ati loke okun.

Amọ bi ọjọ idibo naa se n sunmọle, se ni inu fu, aya fun n bawọn araalu atawọn eeyan ti eto idibo yii gberu nitori awọn iroyin iwa ipa ati jagidi jagan to n waye kaakiri.

Koda, ọpọ eeyan si lo n kaye soke nipa ibo naa, ti iwa ipa lorisirisi yii si n da omi tutu si wọn lọkan nipa ibo gomina naa.

Lara awọn ipinlẹ to si le gbona jainjain lasiko ibo gomina yii, gẹgẹ bi awọn onwoye se tọkasi ni ipinlẹ Rivers , Eko , Kano , Kaduna Sokoto , Kano , Delta , Enugu ati Zamfara.

Awọn iwa yii si lawọn onwoye lero pe o le se akoba fun bi eto idibo naa yoo se lọ

Ajọ to wa fun idagbasoke ijọba alagbada ati aato ilu, Center for Democratic Development and National Development (CDD) ti kede pe ewu si wa loko longẹ lasiko eto idibo gomina yii.

Idi si ree ti wọn se n tọka si awọn isẹlẹ kan eyi to le se akoba fun bi eto idibo gomina naa yoo se lọ lonii.

Wo awọn ohun to le se akoba fun ikẹsẹjari ibo gomina lawọn ipinlẹ kan:

Eto aabo to mẹhẹ:

Atẹjade kan ti ajọ CDD naa fisita wa tọkasi aisi eto aabo to peye lawọn agbegbe kan nilẹ Naijiria gẹgẹ bii ohun to le mu idiwọ wa lasiko ibo naa.

Bakan naa ni wọn woye pe o seese ki idarudapọ wa lasiko ibo gomina naa, ti eyi si le se akoba fun esi ibo ti wọn yoo kede niru ipinlẹ bẹẹ.

Irufẹ awọn ipinlẹ ti eto aabo si ti mẹhẹ ni awọn ipinlẹ kan lagbegbe ẹkun ariwa ati ila oorun guusu Naijiria.

Eto aabo to mẹhẹ ati jagidijagan le dunkooko mọ awọn oludibo lati jade dibo:

iwa idunkooko mọ awọn oludibo lati jade lọ dibo gan le se akoba fun idibo gomina yii, to fi mọ aisi aabo to peye fun ẹmi wọn.

Lawọn ipinlẹ bii Oyo, Ondo ati Eko, akọsilẹ iwa jagidi jagan ti wa nigba to ku ọjọ kan soso ti eto idibo gomina yoo waye.

Koda, ẹmi mẹta lo bọ nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo nigba to ku ọjọ meji ki ibo gomina waye, ti wọn si tun n lọ ka awọn eeyan mọle lati pa wọn tabi se wọn lese.

Bakan naa nipinlẹ Eko ati nilu Owo, nipinlẹ Ondo, iwa jagidijagan waye eyi ti wọn se sawọn ọmọ ẹgbẹ oselu kan tabi si ẹya kan.

Gbogbo awọn igbesẹ jagidijagan yii si lo le da omi tutu sọkan awọn oludibo lawọn ipinlẹ yii lati jade wa dibo.

Aitete ko ohun eelo idibo de sawọn agọ idibo:

Bakan naa ni ajọ CDD tọkasi pe bi ajọ Inec ko ba tete ko awọn ohun eelo idibo de sawọn agọ idibo, o seese ki eyi naa tun se akoba fun ikẹsẹjari eto idibo naa.

Lasiko ti idibo aarẹ waye lọjọ kẹẹdọgbọn osu Keji ọdun 2023, ọpọ agbegbe ni awọn ohun eelo idibo ko tete de ibẹ eyi to se akoba fun ikẹsẹjari ibo lagbegbe naa.

Koda, awọn onwoye ibo labẹle ati loke okun gan mẹnuba eyi gẹgẹ bi ohun to tabuku eto idibo aarẹ to kọja naa.

Bi o ba si tun ri bẹẹ lasiko ibo gomina yii, eto idibo le mẹhẹ diẹ lawọn agbegbe ti ko ba tete ri ohun eelo idibo gba.

Ọwọn gogo epo bẹntrolu ati owo beba Naira:

Ajọ CDD ni ọwọn gogo epo ati owo beba Naira ti ko si nita le da omi tutu sọkan awọn oludibo lati jade wa dibo.

Koda wọn ni ọwọn gogo epo bẹntiroolu gan tun le se idiwọ fawọn osisẹ ajọ INEC lati tete gbe awọn ohun eelo idibo wa si agọ idibo.

Bẹẹ si ni oludibo ti ko ri owo jẹun tabi ra epo sinu ọkọ le ma kọbi ara si ibo didi.

Awọn opo mẹfa to le nipa lori esi ibo gomina:

Bakan naa ni ajọ CDD wa mẹnuba opo mẹfa to le ni ipa lori abajade ibo gomina ati tawọn asofin ipinlẹ naa.

  • Iyapa ẹlẹyamẹya tabi ẹlẹsinjẹsin
  • Irufẹ eeyan ti oludije kan jẹ tabi ẹgbẹ oselu to wa
  • Eto aabo
  • Bi awọn eeyan to lẹnu lọrọ ti to sẹyin ẹgb oselu tabi oludije kọọkan si
  • Rogbodiyan to n waye ninu ẹgbẹ oselu kan
  • Bi awọn oludibo ba se jade sita wa dibo si.
Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Ológun mú èèyàn 900 tó jẹ́ agbódegbà Boko Haram

Aworan ọmọ ologun

Oríṣun àwòrán, DHQ/Facebook

Ile isẹ Ologun ti kede pe ọwọ kẹta ati ikẹrin awọn ọmọ ogun alajumọse to n gbogun ti iwa igbesunmọmi, ti wọn wa lati oniruru orilẹede, ti mu awọn eeyan bii ẹẹdẹgbẹrun to jẹ ibatan ati agbodegba pẹlu awọn ikọ afẹjẹwẹ Boko Haram ati Ẹgbẹ ISWAP.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ikọ ologun to wa ni N’Djamena, lorilẹede Chad, Lt-Col.Kamarudeen Adegoke filede, o ni ija abẹnu laarin awọn Ọmọ ogun Boko Haram ati ISWAP pẹlu bi awọn ọmọ ologun se finna mọ awọn alakatakiti yii mu ki ọpọ wọn ṣi kuro ni ibugbe wọn lọ si ibomiran ti wọn fi ko sọwọ awọn ẹsọ ologun .

Adegoke ni ọpọlọpọ iṣi eeyan loun kuro ninu aginju Sambisa si eti odo Lake Chad.

Adegoke ninu Atẹjade naa ni”iṣi ọmọ ologun kẹta ati ikẹrin lo sisẹ papọ ni agbegbe Kamadougu ni ipinlẹ Yobe ati aala to pin orilẹede Naijiria ati Niger.

A si ri eeyan ẹẹdẹgbẹrun, eleyi ti o kun fun ọmọde, awọn arugbo ati awọn obinrin to ṣeṣe ki wọn jẹ ibatan ẹgbẹ alakatakiti Boko Haram”.

Adegoke ni iṣi ikọ ologun ẹkun kẹrin gba obinrin mẹta, ọmọde mẹrinla nigba ti wọn sa asala lọwọ ẹgbẹ akatakiti Boko Haram ati ISWAP ninu igbo Sanbisa.

Adegoke ni “ọwọ tẹ afurasi Muhammed Sabo ati Sarki Danladi ni Munguno nigbati wọn gbiyanju lati lo darapọ mo n ikọ akatakiti Boko Haram ati ISWAP”.

Ara ohun ti wọn gba lọwọ wọn ni asọ otutu meji, kaadi idanimọ meji, aago ọwọ meji kaadi irinna ti ẹgbẹ Boko Haram fọwọsi meji, asọ wiwọ ati apo ofifo ogun.

AWORAN ỌMỌ OLOGUN

Oríṣun àwòrán, DHQ/FACEBOOK

Ọjọ karun osu yii ni ikọ ologun mu Abubakar Usman pẹlu kaadi igbowo (ATM) kan ati iwe ti awọn alakatakiti kọ ti ohun ti wọn fẹ ki Abubakar ba wọn ra wa ninu rẹ.

Abubakar jẹwọ pe ọpọ ohun elo ni oun maa n ra fun awọn alakatakiti agbebọn Boko Haram.

Ọga agba ikọ ologun ti oniruru Orilẹede, ọgagun AbdulKhalifa Ibrahim, nigba to n gbosuba fun awọn ọmọ ologun fun isẹ takuntakun ti wọn n se, rọ wọn lati mase bọrẹlẹ ninu ilakaka wọn lati fopin si isẹ ibi Boko Haram ati ISWAP.

O ni opin ti fẹ de ba ikọ alakatakiti naa, to si rọ awọn olugbe agbegbe Lake Chad lati fi to awọn ẹsọ alaabo leti, ti wọn ba kẹfin ohunkohun.