Ọwọ́ tẹ ọba ìlú, ọmọ ikọ̀ Boko Haram tẹlẹ àti àwọn 35 míì lórí ẹ̀sùn gbígbé ògùn olóró

Oríṣun àwòrán, Twitter/NDLEA
Ajọ to n gbogun ti gbigbe oogun oloro ni Naijiria, NDLEA ni ọwọ awọn ti tẹ ọba agbegbe Kajọla, Baalẹ Akinola Adebayo fun ẹsun gbigbe oogun oloro.
Kajọla wa ni ipinlẹ Ondo ni ibode to la ipinlẹ Ondo ati ipinlẹ Edo.
NDLEA ni ọwọ awọn tun tẹ ikọ ọmọogun Boko Haram tẹlẹri, Alayi Madu to fi mọ awọn eeyan marundinlọgọta miran.
Ajọ naa ni lara igbeṣẹ awọn ni lati gbogun ti lilo oogun oloro ni orilẹede Naijiria ṣaaju eto idibo ipele keji to n bọ.
"A sun oko igbo to le ni eeka mọkandinlogoji ni Kajola"
Ninu atẹjade kan ti wọn fi si oju opo Twitter wọn, NDLEA ni aarọ kutukutu ọjọ Kẹwaa, oṣu kẹta ni awọn ṣigun bo igbo Kajọla nibi ti wọn ti sun oko igbo to le ni eeka mọkandinlogoji, 39.801546.
Baalẹ ilu Kajola, Akinola Adebayo to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji naa ni wọn mu ninu oko naa pẹlu awọn meji miran ti wọn gbagbọ pe wọn jẹ oṣiṣẹ rẹ.
Orukọ awọn meji ti wọn mu naa ni Arikuyeri Abdulrahman ati Habibu Ologun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bi ọwọ ṣe tẹ ọmọ ikọ Boko Haram tẹlẹ...
Bakan naa ni wọn ni ọwọ awọn tẹ Alayi Madu to jẹ ikọ ọmọogun Boko Haram fun bi ọgun marundinlogun amọ̀ to yọnda ara rẹ fun ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ni ọdun 2021, amọ ọwọ wọn tẹ ni ọjọ kẹsan, osu kẹta ọhun.
Madu ni wọn ri oogun oloro kilọ mẹea ni ọwọ rẹ to ni oun ra ni ilu Ibadan lasiko to n gbe oogun oloro ọhun ninu apo lọ sio ilu Maiduguri, ni ipinlẹ Borno.
Madu ni ilu Banki ni ipoinlẹ Borno ni oun ti wa ti oun si darapọ mọ ikọ Boko Haram ni ọdun200o nigba to jẹ ọmọ ọdun mẹsan.
Ni ọdun 2021 ni o ronupiwada to si jọwọ ara rẹ fun ikọ ọmọogun Naijiria, to si gba ẹkọ atunṣe igbaye eniyan pẹlu ileeṣẹ ọmọogun Naijiria fun oṣu mẹwa ki wọn to fi silẹ.
Lẹyin naa lo lọ si ilu Ibadan nipinlẹ Oyo nibi to ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọlọkada , ki o to bẹrẹ iṣẹ gbigbe oogun oloro, ti ọwọ si tẹ ẹ ni opopona Abuja si Kaduna.
Obinrin wa ninu awọn 35 ti ọwọ tẹ lori ẹsun gbigbe oogun Oloro – NDLEA
Ajọ NDLEA fikun un pe wọn ri awọn miran mu lori ẹsun gbigbe oogun oloro ni papakọ ofurufu ni ilu Eko.
Bakan naa ni wọn si awọn miran ni agbegbe ibode Idi-Iroko, ni ipinlẹ Akwa-Ibom,Kogi, Kwara, Ogun, Gombe, Benue, Kano.
Ajọ NDLEA ni obinrin wa ninu awọn ti wọn mu nipinlẹ Eko, Ogun, Akwa Ibom to fi mọ Idi-Iroko.
Ajọ naa wa kesi awọn ti wọn n ṣiṣẹ yii lati jawo kuro ninu iṣẹ ibajẹ nitori ọwọ yoo tẹ wọn laipẹ ti wọn yoo si fi oju wina ofin.















