N kò ní ìbáṣepọ̀ kankan pẹ̀lú Ọkọ akẹgbẹ́ mí - Wumi Toriola

Aworan awọn oṣere tiata

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajugbaja oṣere tiata, Wumi Toriola ti ke gbajare sita pe oun ko ni ibaṣepọ kankan pẹlu ọkọ akẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi iroyin kan ṣe n ja kiri pe ọrọ ifẹ wa laarin oun ati ọkọ ẹni naa.

Toriola bọ sori opo ayelujara Instagram lati bu ẹnu atẹ lu iroyin, to si ni ero lati ba oun lorukọ jẹ ni iroyin naa.

Ki lo ṣẹlẹ saaju?

Ọsẹ to kọja ni iroyin kan ti a ko le fidi rẹ mulẹ bọ sori ayelujara pe Wumi Toriola ati Kolawole Ajeyemi, ọkọ gbajugbaja osere tiata miiran, iyẹn Toyin Abraham, n fẹ ara wọn ni kọkọ.

Ninu alaye rẹ, Wumi Toriola ni oun ko ba ẹnikẹni sun ko da oun ko ni ibasepọ pẹlu ọkọ akẹgbẹ rẹ tẹlẹ ri.

"N ko mọ idi ti awọn eeyan wọnyi fi nifẹ lati ma ba orukọ mi jẹ.

Igbakẹyin ree ti maa fesi si ọrọ kankan lati ọdọ ẹni yii.

"Emi ti tẹsiwaju, ọjọ ọla mi lo bami, ti mo si fẹ gbe ọpọlọpọ sinima jade.

"N ko ni ṣubu sọwọ awọn eeyan lagbara Ọlọrun".

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ṣaaju, gbajugbaja sọrọsọrọ kan lori ayelujara lo gbe awọn aworan ati ọrọ jade to si n darukọ Wumi Toriola tan tan tan pe o ni ajọṣepọ pẹlu akẹgbẹ rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ ololufẹ awọn oṣere tiata lo n fesi si ọrọ naa amọ a ko lee fidi rẹ mulẹ.

Kete ti Wumi Toriola fi esi rẹ sita lo fi aridaju han pe o gbọ sii amọ o bu ẹnu atẹ lu u pe irọ pọnbele ni ẹni naa n pa to si n da ọgbọn lati ba oun jẹ ni.