“Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ondo, wá sọ ìdí tí o kò fí ni gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣe àyẹ̀wò ìlera Akeredolu”

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/RICHARD OLATUNDE
Ileẹjọ giga kan nipilẹ Ondo to filu Akure ṣe ibujoko lo ti tẹwọ gba iwe ipẹjọ ti awọn ọmọ ipinlẹ naa kan gbe ka iwaju rẹ nipa ailera gomina ipinlẹ ọhun, Oluwarotimi Akeredolu.
Awọn ọmọ ipinlẹ Ondo mẹrin naa, Olufemi Lawson, Isijola Kike, Ologun Ayodeji ati Arogbo Olaniyi lo fẹẹ ki ileẹjọ o paa laṣẹ fun abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ naa, Olamide Oladiji, ati apapọ ile aṣofin naa lati gbe igbimọ awọn oniṣegun oyinbo ti yoo ṣe ayẹwo ipo ilera Gomina Akeredolu kalẹ.
Awọn mẹrin yii lo wi pe awọn fẹẹ ki igbimọ awọn oniṣegun naa o woo boya Akeredolu lee tẹsiwaju bii gomina ipinlẹ naa lẹyin to ti fi ipinlẹ ọhun silẹ lati bii oṣu mẹfa nitori ailera rẹ.
“Ofin la fẹẹ ki ile aṣofin o tẹle”
Agbẹjọro fun awọn olupẹjọ naa, Olukayode Mogbojuri, ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba wi pe ohun ti awọn onibara oun n fẹ ni lati mọ ipo ti gomina ti wọn dibo yan wa ni tootọ.
Mogbojuri ṣee lalaye pe ẹbẹ awọn niwaju ileẹjọ ni pe “ki adajọ o paa laṣẹ fun abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ Ondo lati ṣe iṣẹ rẹ nibamu pẹlu abala kọkandinlaadọwa ẹsẹ ikẹrin ninu iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.
“Ẹsẹ ofin yii ko ni ẹsẹ kankan ninu iwe ofin wa toi n ṣe idiwọ fun-un, nitorina, ko si ohunkohun to lee da abẹnugan duro lati ma gbe igbesẹ yii ti ileẹjọ ba ti paa laṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Kayode Mogbojuri
“N ko lee sọ Yoruba, nitorinaa, n ko nii lee sọ nkankan”
Nigba ti akọroyin BBC Yoruba kan si agbẹjọro ile aṣofin ipinlẹ Ondo, Femi Emodamori, lati gbọ ohun to nii sọ nipa ọrọ naa, agbẹjọro ọun ni ohun ko lee sọ nkankan.
Emodamori sọ lede Gẹẹsi pe “nko gbọ Yoruba, nitori naa, ko si bi mo ṣe lee dahun ibeere yin”.
Nigba tii a wi pe ki agbẹjọro o sọ ọrọ rẹ lede oyinbo, o dahun pe “mi o fẹẹ ki ẹ si ọrọ mi tu nigba ti ẹ ba fẹẹ tuu si Yoruba. Eyi ko nii jẹ ki n wi nkankan bayi”.
Kini ẹjọ yii da le lori gan?

Oríṣun àwòrán, Kayode Mogbojuri

Oríṣun àwòrán, Kayode Mogbojuri

Oríṣun àwòrán, Kayode Mogbojuri
Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹwa, ọdun yii ni awọn olupẹjọ yii lọ iwaju ileẹjọ lati gba aṣẹ ti yoo mu ki ile aṣofin ipinlẹ Ondo ati abẹnugan rẹ o gbe igbimọ iwadi kalẹ lati mọ ipo ilera Gomina Oluwarotimi Akeredolu.
Ile aṣofin Ondo, abẹnugan ile, Gomina Akeredolu ati agbefọba agba nipinlẹ naa ni wọn pe lẹjọ niwaju ileẹjọ giga naa.
Awọn agbẹjọro awọn olupẹjọ, Dotun Ajulo, Fadeshola Ojamomi, A.V Àjàyí ati K.A Mogbojuri lo rọ ileẹjọ lati paa laṣẹ fun olujẹjọ kini ati ikeji pe ki wọn o tẹle abala kọkandinlaadọwa ẹsẹ ikẹrin ninu iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999 lai deena pẹnu.
Ileẹjọ lo ti waa fun awọn olupẹjọ laṣẹ lati fi iwe ẹjọ naa ṣowọ sawọn olujẹjọ .
Onidajọ D. I. Kolawole ninu ọrọ rẹ sun igbẹjọ si ọjọ kọkanla oṣu kini, ọdun 2024 fun awọn olujẹjọ lati fara han niwaju ileẹjọ naa.












