₦90.66B ni Makinde yà sọ́tọ̀ fún ètò ẹ̀kọ́ nínú àbá ètò ìṣúná ọdún 2024

Aworan Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/SEYI MAKINDE

Gomina Seyi Makinde ti taari apinlẹkọ owo to le diẹ ni ẹrinlelọgbọnlenirinwo biliọnu naira (₦434,221,765,938,79) siwaju ile aṣofin ipinlẹ Oyo gẹgẹ bii aba eto iṣuna ipinlẹ naa fun ọdub 2024.

Gomina Makinde, to pe aba eto iṣuna ọhun ni “Irapada Ọrọ Aje”, gbe e ka iwaju awọn aṣofin ipinlẹ naa nibi akanṣe ijokoo to waye lọjọ Iṣẹgun ninu gbọngan awọn aṣofin to wa nibujoko ijọba ipinlẹ Oyo, l’Agodi n’badan.

Aba eto iṣuna ọhun lo fi biliọnu mẹrinlelọgọfa ju ti ọdun 2023 to n tan lọ yii lọ.

Eto ẹkọ lo ni gba ipin to pọ julọ ninu aba eto iṣuna naa pẹlu ida ogun ati ẹsun mejidinlaadọrun ninu ida ọgọrun tii ṣe aadọrun biliọnu naira o le ẹsun mẹrindinlaadọrin.

Ninu alakalẹ eto iṣuna ọhun, biliọnu mẹrinlelaadorin naira o le miliọnu mẹrindinlogunlelọọdunrun ati ẹsun diẹ ni yoo wa fun iṣẹ akanṣe ati ipese ohun amayedẹrun.

Eto ilera ni yoo gba ogoji biliọnu naira o le ejidinlẹgbẹrun miliọnu, nigba ti biliọnu mẹẹdogun o le ejidinlaadọtalelẹgbẹrin miliọnu ati ẹsun diẹ yoo wa fun eto ọgbin.

Nigba to n lewaju awọn aṣofin lati tẹwọ gba aba eto iṣuna naa, adari ile, Adebo Ogundoyin, jẹ ẹjẹ pe awọn aṣofin yoo ṣe agbeyẹwo ati ifọwọsi aba naa ni kiakia fun anfaani awọn araalu.

Ogundoyin waa gboriyin fun Gomina Makinde fun gbogbo igbesẹ rẹ lati mu ki owo wọle sii sapo ijọba ipinlẹ Oyo latọdun 2019 to ti gba iṣakoso ipinlẹ naa.

O fi kun pe awọn aṣofin ipinlẹ naa ko nii fasẹyin ninu ojuṣe wọn nibamu pẹlu alakalẹ ofin fun akoyawọ ati iṣejọgba gbangba laṣa n ta.

Lara awọn eekan ilu to wa nibi agbekalẹ aba eto iṣuna naa ni igbakeji alaga apapọ fun iwọ-oorun-guusu lẹgbẹ oṣelu PDP, Taofeek Arapaja, akọwe ijọba ipinlẹ Oyo, Ọjọgbọn Olanike Adeyemo, adajọ agba nipinlẹ Oyo, Onidajọ Iyabo Yerima, awọn oriade arawọn olori ẹsin.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post