Àwọn agbébọn kọlu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga, wọ́n jí ọ̀pọ̀ gbé lọ

Awon akekoo to n se iwode

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Nasarawa ti bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn ní ìlú Lafia, olú ìlú ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Ìgbésẹ̀ yìí kò ṣẹ̀yìn bí àwọn agbébọn kan ṣe jí lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà gbé ní ilé ìgbé wọn.

Ní ọjọ́bọ̀ ni ìròyìn gbòde pé àwọn àwọn agbébọn jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga náà méje gbé sálọ.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé lálẹ́ ọjọ́rú ti mú kíá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù wà nínú inú fo àyà fo, ní èyí tó sì mú wọn ṣe ìwọ́de náà.

Agbenusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa, Rahman Nansel fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀, tó sì tún fi kun pé ẹ̀mí kan bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé náà lọ.

Ó ní kété tí ìròyìn kàn sí àgọ́ ọlọ́pàá pé àwọn agbébọn ń yìnbọn ní agbègbè Gandu ni àwọn ọlọ́pàá tẹ ọkọ̀ létí láti lọ báwọn níbẹ̀.

"Àwọn òṣìṣẹ́ wá lọ láti lọ dá ààbò bo àwọn ènìyàn Gandu àmọ́ a ò bá àwọn agbébọn náà, tí wọ́n sì ti pa ẹnìkan, jí ìyàwó rẹ̀ gbé.

"Gbogbo ìgbìyànjú láti ṣàwárí àwọn oníṣẹ́ ibi yìí kí a gba àwọn tí wọ́n jí gbé sílẹ̀ ló já sí pàbó."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ibrahim Ismail tó jẹ́ Ààrẹ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà ní inú ẹgbẹ́ àwọn kò dùn sí bí àwọn ọlọ́pàá ṣe fèsì lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ismail so fún BBC News Pidgin pé ìwà ìjínigbé kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wáyé ní agbègbè ilé ẹ̀kọ́ àwọn àti pé ọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò balẹ̀ rárá.

Nígbà tó ń ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé, ó ní ẹgbẹ́ àwọn gbọ́ pé àwọn kan ń dààmú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń gbé ní Confidence logde tí wọ́n ń gba fóònù wọn, fìyà jẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Ó ṣàlàyé pé èyí ló mú àwọn lọ pe àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ àwọn àtàwọn ọmọ ogun ṣùgbọ́n àwọn tó wá ṣe ìkọlù náà ti fẹsẹ̀ fẹ kí àwọn tó dé bẹ̀.

"Ohun tí a gbọ́ nígbà tó ma fi di alẹ́, mo tún gba ìpè pé àwọn agbébọn ti wọ Gandu àti pé wọ́n ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méje gbé lọ.

"Àwọn méjì tó móríbọ́ nínú ìkọlù náà sá sí orí àjà ilé wọn ni.

"Ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé báyìí máa ń wáyé lemọ́lemọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ wa. Kódà gómìnà ìpínlẹ̀ yìí, Abdullahi Sule ṣàbẹ̀wò sí wa ní nǹkan bíi ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn tó sì ṣèlérí láti wá ojútùú sọ̀rọ̀ ètò ààbò bo wá àmọ́ a ò tíì rí àbọ̀ rẹ̀."

Ismail fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọ̀rọ̀ ìjínigbé náà ti kọjá nǹkan tí agbára gíwá àgbà ilé ẹ̀kọ́ àwọn le ká nítorí pé ó ti gbìyànjú gidi àti pé gbogbo ìgbà ni àwọn ọmọ ogun máa ń ṣe àbẹ̀wò sí ọgbà àwọn.

Ó ní àwọn agbébọn náà ti mọ àsìkò tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kìí sí ní agbègbè àti pé gbogbo ọ̀nà ẹ̀bùrú láti sálọ ni wọ́n mọ̀.

Awon akekoo to n se iwode
Awon akekoo to n se iwode

Ojoojúmọ̀ ni wọ́n máa ń jí wa gbé - àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Enu ona ile eko giga Fasiti Lafia

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbé ní ìlú Gandu, níbi tí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, Federal University of Lafia wà, ní ohun tí ojú àwọn ń rí lọ́wọ́ àwọn ajínigbé kò kéré rárá.

Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti jí gbé rí, Daniel Ebuga, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ipele kẹta ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí ní àhámọ́ àwọn ajínigbé ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.

Ó ní ojoojúmọ̀ ni wọ́n máa ń jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé láìsí ìbẹ̀rù kankan.

Ó ní àwọn ọlọ́pàá kìí ran àwọn lọ́wọ́ àti pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń wá jí àwọn gbé pàápàá ni gbogbo ọjọ́ Ajé.

Ó fi kun pé inú ìbẹ̀rù ni àwọn máa ń lọ sí yàrá ìkàwé, tí àwọn kò sì mọ̀ bí àwọn ṣe máa ṣe ìdánwò nínú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀.

Akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tó ṣàlàyé pé ilé ìgbé kan tí wọ́n ń pè ní Confidence ni wọ́n ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé báyìí àti pé àwọn díẹ̀ ló móríbọ́.

Ó fẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n máa ń gba owó lọ́wọ́ àwọn síbẹ̀ kò sí ààbò tó péye fún àwọn.

"À ń fẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ọmọ ogun kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́," ó sọ.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn kìí sùn fẹ̀dọ̀ lórí òroòró mọ́.

Wọ́n ní kí iléeṣẹ́ ológun wá kọ́ ibùdó rẹ̀ kan sí ilé ẹ̀kọ́ náà kí ààbò tó péye le wà fún àwọn.

Awon akekoo to n se iwode