Àwọn aṣòfin kò jẹ̀bi pẹ̀lú ọkọ̀ olówógọbọi tí wọ́n fẹ́ rà, owó Naira to yọ̀lẹ ni ká dá lẹ́bi -Mínísítà tẹ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, bbc/Nigeria senate
Oniruru ọrọ lo ti jade si obitibiti owo ti awọn to dipo oṣelu mu lorilẹede Naijiria maa n na lori ọkọ ti wọn fẹ lo.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu Ọjọgbọn Abubakar Ọlanrewaju to figba kan ri jẹ minisita nigba aye Aarẹ Goodluck Jonathan nilu Ilọrin, o ṣalaye pe ko si oun to buru ninu ọkọ ti awọn aṣofin n ra nitori pe ọkọ ti wọn yoo fi ṣe iṣẹ ni.
“Ọpọlọpọ awọn aṣofin wọnyi ni ko ni ọkọ ki o to de aga aṣofin ti o si gbọdọ lọ si bi iṣẹ.”
O ni kii owo agbara owo Naira to lọ silẹ lo n mu ki owo ti wọn n na lori ọkọ o da bi i gọbọi.
- Mo kọ́ bí igi ṣe ń sọ̀rọ̀ -Arole, agbẹ́gilére
- Kàyééfì! ‘Kọ̀rọ̀ Afọ́jú’ ìletò àwọn afọ́jú níbi tí ọmọ afọ́jú kò ti lè jogún òbí rẹ̀
- Ìjọba Nàìjíríà ń dọ́gbọ́n láti da ọwọ́ bo ìdadìí ikọlù àdó olóró t’ólógun jù s’áráàlú ní Kaduna
- Forbes kéde Ngozi Okonjo-Iweala, Mo Abudu, àwọn obìnrin méjì míràn láti Áfíríkà lára àwọn obìnrin 100 tó lẹ́nu jùlọ lágbáyé
- Ooni Adeyeye's father John Ogunwusi: Ohun to ṣẹlẹ̀ láàrin Ooni àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lásìkò tó fẹ́ jẹ Ọba rèé
Ti awọn aṣofin la n wi, ki la fẹ sọ lori awọn Minisita ati gomina? – Ọjọgbọn Abubakar Ọlanrewaju

Oríṣun àwòrán, X/Nigeria house of reps
Ọjọgbọn Abubakar Ọlanrewaju ṣalaye pe sisọ ti awọn aṣofin n sọ owo ti wọn n na fun araye lo n mu ki awọn eeyan maa fi oju si wọn lara.
O ni pọ minisita ati gomina lo n lo ọkọ to pọ ju eyi ti awọn aṣofin wọnyi n lo ṣugbọn ti wọn ko ni sọ fun araalu. Minisita tẹlẹ naa fi kun un pe ẹnikẹni to ba sunmọ awọn aṣofin yoo kaanu wọn pupọ.
O ni bi awọn eeyan ba wo o daadaa, owo ti awọn aṣofin n gba kere nitori pe ọpọ awọn araalu lo ti ko gbogbo bukata wọn le awọn aṣofin lọrun.
O ni oungbẹ to yẹ ko maa gbẹ awọn ọm Naijiria bayii ni bi awọn alaṣẹ yoo ṣe wa nnkan ṣe si ọr ọr aje to dẹnukọle eyi ti igbe aye yoo fi dẹrun fi gbogbo mutumuwa.





