Aláboyún kú lásìkò isẹ́ abẹ ṣùgbọ́n ọmọ ń kọ́?, Mọ̀lẹ́bí béèrè lọ́wọ́ Dókítà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mọlẹbi arabinrin kan, Rachael Sampson, oloyun ti wọn ni o ku lasiko ti Dokita Happiness Iheukumere ti ọpọ mọ si Dr Hagi n se isẹ abẹ fun un ti n beere fun idajọ ododo lori iku ọmọ wọn ati ẹjẹ ọrun to ba lọ.
Dokita Hagi ni ti wọn ti fẹsun kan o ṣe isẹ abẹ fun obinrin naa to si ku sọwọ rẹ.
Ẹgbọn Racheal, Ruth Sampson ni awọn fẹ ki Dokita Hagi gbe ọmọ to yọ ninu oloogbe fun awọn lati lọ fi pẹtu si awọn obi wọn.
“O ni lati pese ọmọ naa fun wa nitori pe ọmọ nikan ni a le fi pẹtu si awọn obi wa.
“Wọn ko le padanu ọmọ wọn, ki wọn tun padanu ọmọ-ọmọ. A ko ni owo lati se ẹjọ sugbọn a fẹ idajọ ododo.
“A fẹ ki ijọba ran wa lọwọ lati gba idajọ ododo fun Racheal nitori pe ti a ko ba wadi nọọsi, a ko ni mọ pe wọn ti gbe oku Racheal si ile igbe oku si.
“To ba jẹ pe otitọ ni pe wọn ṣe aṣiṣe, o yẹ ki wọn ransẹ pe wa pe nnkan ti sẹlẹ. A nilo idajọ ododo"

Oríṣun àwòrán, EMEKA ORTUKA
Lẹyin ọṣu meji ti ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers mu dokita yii fun ẹsun karakata ọmọ, wọn tun mu fun ẹsun pe o ṣekupa obinrin oloyun, ẹni ogun ọdun to si tun ta ọmọ rẹ.
Dokita yii lo n sisẹ ni ile iwosan Hagi Medical Center ni agbegbe Agboga nijọba ibilẹ Ikwerre nipinlẹ Rivers,
O se isẹ abẹ fun oloyun kan, ti orukọ rẹ n jẹ Racheal Sampson lati yọ ọmọ ninu rẹ sugbọn obinrin naa padanu ẹmi lasiko isẹ abẹ naa, ti wọn si tun fẹsun kan oe o gbe ọmọ to yọ ninu obinrin naa ta fun olubara kan ti wọn ko ti le fidi rẹ mulẹ.
Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers, SP Grace Iringe- Koko fidi isẹlẹ naa mulẹ fun ileeṣẹ BBC pe Dokita Iheukeumere ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa fun iwadii.
Bawo ni asiri se tu sita?

Oríṣun àwòrán, RIVERS STATE POLICE COMMAND
Ọrọ bẹ sita lẹyin ti ẹgbọn oloogbe Racheal Sampson bọ sori ayelujara lati pariwo sita bi wọn se mọ pe oloogbe naa ku, to si fẹsun kan dokita.
O ni Dokita Iheukeumere sọ fun nọọsi lati sọ fun pe oloogbe naa jade laye ninu ijanba ọkọ.
“Lọjọ kẹdogun, oṣu kọkanla ọdun 2023, obinrin kan ti a ko mọ ri wa sọ fun wa pe oloogbe ku sinu ijanba ọkọ. Obinrin yii fun wa ni ayederu nọmba. A bere pe nibo ni oku oloogbe wa sugbọn ko ri nnkan sọ.
O fikun pe awọn ti n ba oloogbe sọrọ lori foonu nọọsi nigba to wa pẹlu wọn.
O tẹsiwaju pe awọn fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ti wọn si pese iranlọwọ lati sawari obinrin ajoji to wa fun ni iroyin iku oloogbe.
“Obinrin ajoji yii n sọ pe oun se se isẹ POS ni agbegbe Choba nipinlẹ Rivers sugbọn iwadii fihan pe oun n pa iro ni ati pe nọọsi ile iwosan ni.
Ọwọ ọlọpaa pada tẹ obinrin nọọsi naa, to si jẹwọ pe dokita lo gbe oloogbe lati wa ni ọdọ oun fun ọsẹ kan sugbọn to pada wa gbe lọjọ Aje ọjọ kẹtala oṣu kọkanla.
“Lẹyin ọjọ meji, dokita pe nọọsi lati sọ fun pe aburo mi ti ku nigba to n gba ẹbi rẹ, to si sọ fun pe ko ma sọ fun mọlẹbi rẹ. O si gbegi le nọmba wa.
O fikun pe ileeṣẹ ọlọpaa bere awọn ibeere lọwọ awọn nọọsi n ba dokita naa sisẹ, ti wọn si jẹwo pe awọn wa nibẹ nigba to n se isẹ abẹ naa, to si jade laye lẹyin ti dokita fun ni abẹrẹ kan ati pe o ke irora ku ni.
Awọn nọọsi yii ni ọmọ tuntun yii siwaye sugbọn dokita ti gbe lọ ibi kan ti awọn ko mọ.”












