Obìnrin olùṣirò owó tó lu $28m ọ̀gá rẹ̀ ní póńpó rí ẹ̀wọ̀n àádọ́ta ọdún he

Aworan afihan oṣiṣẹ ẹlẹwọn ni South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty

Arabinrin ọmọ orileede South Africa kan to ji miliọnu mejidinlọgbọn ẹni to gba ṣiṣẹ ti gba idajọ ẹwọn aadọta ọdun lọjọ Ẹti.

Ọdun mẹtala gbako ni Hildegard Steenkamp fi n yọ ji owo yi lakoto ọga rẹ nileeṣẹ itọju ilera kan to jẹ olusiro owo nibẹ.

Agbegbe Gauteng ni ileeṣẹ naa wa.

Ṣaaju ni arabinrin Steenkamp ti bẹbẹ pe oun jẹbi ẹsun jibiti onigun ọọdunrunlemẹrindinlogoji ti wọn fikan niwaju adajọ.

Wọn wọ lọ siwaju adajọ ileẹjọ majistireeti to sọ pe oun ko ti ṣe idajọ lori ẹsun ikowojẹ to to iye owo ti arabinrin yi ji ko.

Adajọ Philip Venter sọ pe iyalẹnu nla lo jẹ ti o ṣi ṣoro fun oun ''lati fọkan ro wi pe eeyan kan ninu oṣiṣẹ le ji aduru owo nla ribiti yi lọdọ ẹni to gba siṣẹ'

Ọkọ mi lo fipa mu mi lati ji owo naa-Steenkamp

Awijare kan ti o jade lati ẹnu arabinrin Steenkamp ni pe ọkọ rẹ to lo n fi iya jẹ oun to si ti wa doloogbe bayi lo fipa mu oun lati ji owo naa.

Arakunrin Venter tako ọrọ yi to si ni ''Oun nikan lo da ji owo gbe''

Iwadii ọtẹlẹmuyẹ fihan pe arabinrin Steenkamp na owo yi nina bujẹdanu lori faaji,tẹtẹ rira awọn nkan meremere ati irinajo afẹ.

Lasiko irinajo kan to ṣe wọn ri wi pe o na ẹgbẹrun lọna ọtalenigba le mẹta dọla lalẹ ọjọ kan ṣoṣo nidi tẹtẹ.

Ileẹjọ tun gbọ pe Steenkamp na iye to fẹrẹ to miliọnu meji dọla $1.6m lori irinajo silẹokere ati pe bi ẹni n lọ si ọja lo ṣe n fo fẹrẹ lọ si Dubai ni gbogbo igba.

Laarin ọdun 2004 si 2017 lo fi ba ileeṣẹ to ti ji owo ṣiṣẹ ko to wa fẹyinti nidi iṣẹ.

Bawo lo ṣe d'ọgbọn alumọkọrọyi to fi ji aduru owo yii?

Steenkamp ribi dọgbọn jibiti yi nigba ti wọn fun laṣẹ lati yọ tabi ṣafikun orukọ awọn ti ileeṣẹ ọga rẹ jẹ ni gbese gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa South Africa ṣe ṣalaye.

O fi orukọ ọkọ rẹ kun awọn ti ileeṣẹ jẹ́ẹ ni gbese to si bẹrẹ si ni san owo sinu akoto rẹ.

Ọdun 2018 ni Steenkamp jọwọ ara rẹ fawọn agbofinro ti wọn si gba beeli rẹ.

Ni ibẹrẹ ọdun yi lo bẹbẹ pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan niwaju adajọ.