Canada fi kún iye owó tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ òkèrè gbọdọ̀ ní kí wọ́n tó lè gba 'Visa', àlàyé rèé

Canada

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orilẹede Canada ti kede afikun si iye owo ti awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere gbọdọ ni ki wọn to wọ orilẹ-ede naa bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024.

Minisita to n ri si ọrọ wọle-wọde lorilẹede naa, Marc Miller lo sọ bẹẹ, ọrọ ọhun si kan awọn to ṣẹṣẹ fẹ lọ kẹkọọ nilẹ naa atawọn akẹkọọ to ti wa nibẹ ṣaaju asiko yii.

Awọn atunṣe tuntun ọhun lo wa ninu awọn atunṣe ti orilẹ-ede naa ṣe si ilana awọn to ba fẹ kawe nibẹ.

Bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024, ẹni to ba fẹ kawe ni Canada gbọdọ fi ẹri silẹ pe oun ni owo ti iye rẹ to ogun ẹgbẹrun dọla ($20,000) ko to le maa gbe nibẹ, eyii to jẹ ẹgbẹrun mẹwaa dọla ($10,000) tẹlẹ.

Ọdọdun ni ijọba naa n ṣagbeyẹwo iye owo ti eeyan gbọdọ ni ko to maa gbe ni Canada, eyii ti wọn n pe ni LICO.

LICO n tumọ si iye owo ti eeyan gbọdọ ni lati maa gbe nilẹ naa ki iya ma ba jẹ irufẹ ẹni bẹẹ.

Bẹrẹ lati ọdun 2024, ẹni to ba fẹ lọ si orilẹede naa gbọdọ fi ẹri han pe oun ni ẹgbẹrun lọna ogun ati ojilelẹgbẹta o din marun un dọla (20,635) tabi ida 75% owo LICO, to fi mọ owo ile ẹkọ rẹ fun ọdun kan akọkọ atawọn owo pẹpẹpẹ mii.

Adinku si iye akẹkọọ to n wọle

Ọrọ mii ti minisita naa tun sọ ni bi wọn yoo ṣe bojuto iye akẹkọọ ti wọn n fun ni fisa.

Miller sọ pe awọn ile ẹkọ gbọdọ ri daju pe iye akẹkọọ ti wọn le bojuto nikan ni wọn n gba wọle lati wa si orilẹ-ede naa.

O ni ijọba ti ṣetan lati mu adinku ba iye eeyan to n fun ni iwe irinna lọna ati ri pe awọn akẹkọọ ti agbara ile ẹkọ ka nikan lo n gba wọle.

Iye wakati ti akekọọ le maa fi ṣiṣẹ laarin ọsẹ

O fi kun pe iṣẹ n lọ lọwọ lati ri pe awọn fi kun iye wakati ti awọn akẹkọọ le maa fi ṣiṣẹ.

Lọwọ yii, ogun wakati pere ni akẹkọọ le fi ṣiṣẹ laarin ọsẹ kan, amọ o ni awọn n woye boya awọn le ṣafikun iye wakati naa si ọgbọn wakati laarin ọsẹ.