Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ojú mi rí gẹ́gẹ́bí àkàndá lẹ́nu iṣẹ́ kí n tó di ‘Perm Sec’ – Ayanwale Kayode, akọ̀wé àgbà nípínlẹ̀ Kwara
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ojú mi rí gẹ́gẹ́bí àkàndá lẹ́nu iṣẹ́ kí n tó di ‘Perm Sec’ – Ayanwale Kayode, akọ̀wé àgbà nípínlẹ̀ Kwara

Ọdun 1991 ni Ọgbẹni Ayanwale Peter Kayọde bẹrẹ iṣẹ olukọ pẹlu ijọba ipinlẹ Kwara ni gba ti o di ọdun 2018 to yẹ ko ni igbega ṣugbọn kaka ki wọn fun un, wọn gbe ẹlomiran si ipo rẹ.
Amọṣa, o ni gomina ipinlẹ naa gbọ ohun oun lẹyin ti oun pariwo sita lori irẹjẹ naa ti o fi sọ oun di akọwe agba.
‘Igbona lo sọ mi di afọju’

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, wn ko bii gẹgẹbi afọju, aisan igbona to ṣe e nigba to pe nnkan bii ọmọ ọdun mẹfa ni o fi di ẹni to padanu oju rẹ kan.
O ni awọn obi oun gbiyanju titi ki oun le gbadun ṣugbọn nigba ti rọ naa yoo fi ja si ibi kan lo fi di ti oju osi fi fọ.
Nigba to di ọdun 1995 ni oju keji rẹ tun bẹrẹ si ni da a laamu.
Nigba to kaakiri awọn ile iwosan lawọn dokita sọ fun un pe ko si ọgbọn ti wọn le da si ati riran rẹ.






