Òògùn ìdún rán géńdé ọkùnrin méjì lọ sí àhámọ́ ọlọ́pàá

Idun

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àwọn ọkùnrin méjì kan ní orílẹ̀ èdè France ti kó sí gbaga ọlọ́pàá fẹún ẹ̀sùn wí pé wọ́n gba owó lọ́wọ́ àwọn àgbàlagbà méjì kan láti báwọn ra oogun ìdun tí wọn kò nílò.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Strasbourg ni àwọn ọkùnrin méjèèjì ọ̀hún máa ń lọ sí ilé àwọn tí wọ́n lù ní jìbìtì náà, parọ́ iṣẹ́ tí wọn kò ṣe, tí wọ́n sì ma gba owó gọbọi lọ́wọ́ wọn.

Wọ́n ní àpapọ̀ àwọn àgbàlagbà méjìdínláàdọ́ta tí ọjọ́ orí wọn ti lé ní àádọ́rùn-ún ni wọ́n ti lù ní jìbìtì náà.

Káàkiri orílẹ̀ èdè France ni ìdun ti ń yọ wọ́n lẹ́nu láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn.

Èyí sì ti ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lórílẹ̀ èdè náà tí ìjọba sì ti ń wá ojútùú sí ìṣòro ọ̀hún.

Àwọn onímọ̀ ìlera ti ṣèkìlọ̀ pé bí ìdun ṣe bẹ́ sílẹ̀ náà ti ṣokùnfà kí àwọn àìsàn kan máa jáde.

Àwọn aláṣẹ ní àwọn afurasí náà máa pe àwọn ènìyàn láti sọ fún wọn pé ìdun ti wà ní agbègbè wọn tí àwọn sì máa nílò láti báwọn fín agbègbè wọn.

Wọ́n ṣàlàyé pé àwọn afurasí náà máa lọ sílé àwọn tí wọ́n bá ti pè yìí pé òṣìṣẹ́ ìlera ni àwọn tí wọ́n sì máa lo oògùn aerosol láti báwọn fi fín ilé.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa fún wọn ní ipara láti fi pa ara wọn pé ìdun kò ní lè jẹ wọ́n.

Wọ́n máa wà bèrè owó tí iye rẹ̀ tó €300 sí €2,100 lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yìí.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ó ti tó àwọn ènìyàn mẹ́sàn-án tí wọ́n ti wá fẹjọ́ sun àwọn.

Èyí ló mú kí àwọn ọlọ́pàá dọdẹ wọn tí wọ́n sì mú àwọn afurasí náà lẹ́yìn tí wọ́n fẹ́ kúrò nílé kan ní Strasbourg.

Bí ìdun ṣe ń jà ní Paris ti ń mú ìbẹ̀rù bojo bá àwọn èèyàn pé ó lè tàn dé London.