Ìyá Ọ̀ṣun Osogbo jáde láyé

Iya Ọṣun Oṣogbo

Oríṣun àwòrán, others

Iya Ọṣun Oṣogbo, Ọṣunwẹde Ọmọdara ti jade laye.

Iya Ọṣun, gẹgẹbi ọpọ ṣe maa n pe e, jade laye lọjọru, ọjọ kẹfa oṣu kejila, wọn si ti ṣe eto isinku rẹ ni ilana iṣẹṣe ni Ọjọbọ, ọjọ keje oṣu kejila ni agbole Jagun lagbegbe Ayetoro ni ilu Osogbo.

Ọdun Marun un ni Oloogbe Ọṣunwẹde Ọmọdara lo nipo gẹgẹ bi iya ọṣun ki o to papoda ni ẹni ọdun marundinlọgọrin.

Adanu nla ni iku Iya Ọṣun fun gbogbo ilu Osogbo - Baba Oriṣa ilu Osogbo

Iya Ọṣun Oṣogbo lasiko ayẹyẹ ọdun ọṣun oṣogbo kan

Oríṣun àwòrán, others

Nigba ti BBC Yoruba kan sì Afin Ataoja ti ilu Osogbo ni ọjọ Ẹti, Alagba Ọṣunyẹmi Ifarinu Ifabode ẹni to jẹ baba Oriṣa ti ilu Osogbo se àpèjúwe ìyá osun gẹ́gẹ́ bíi oniwa tútù ati èèyàn to nifẹ ọmọ ni kejì dáadáa.

Osunyemi Ifarinu tun tesiwaju pe ìyá osun jẹ onisẹse, ó si wa lati ìdílé Ọba.

Oni gẹ́gẹ́ bíi èèyàn tí yóò jẹ oyè ìyá osun ó gbọdọ̀ wa lati ìdílé Ọba, nítorí Olori Ọba tabi ẹni to wa lati ìdílé ọba to ba wa lori oyè lo ní àǹfààní lati jẹ oyè ìyá osun.

Osunyemi Ifarinu ṣalaye pe iku ìyá osun jẹ àdánù gidigidi fun gbogbo olorisa ati fún Kabiyesi Ọba Jimoh Olanipekun, Ataoja tí ilu Osogbo.

Iya Ọṣun jẹ ẹni to karamasiki Iṣẹṣe pupọ - Ifayẹmi Ẹlẹbubọn

Iya Ọṣun Oṣogbo

Oríṣun àwòrán, other

BBC Yoruba tun ba Baba Araba Awo ti ìlú Osogbo Ifayemi Elebuibon sọ̀rọ̀ lórí iku Ọṣunwede Omodara ìyá osun ti ìlú Osogbo.

Ifayemi Elebuibon se àpèjúwe ìyá Ọṣun gẹ́gẹ́ bíi abiamọ ati gẹ́gẹ́ bíi ẹni to ní ìfẹ́ ọmọ ni kejì.

Araba Awo ilu Oṣogbo tun tẹsiwaju pe, ìyá Ọṣun jẹ ẹni ti isẹse ye dáadáa to si bọwọ fun isẹse, yàtọ̀ si pe o wa lati ìdílé Ọba, o jẹ ẹni ti oye ìyá osun tọ si.

Ifayemi Elebuibon náà tun ṣàpèjúwe iku ìyá osun bí àdánù nla fun gbogbo ọmọ bibi ìlú Oṣogbo ati gbogbo olorisa pátápátá.

Ifayemi Ẹlẹbuibon wí pe, wọn ko le jẹ oyè ìyá osun lia bi ifá lere ẹni to tọ si. Ati pé, ẹni náà gbọ́dọ̀ wa lati ìdílé Ọba to wa lori oyè báyìí.