Èèyàn 81 ni ìbúgbàmù Kaduna ṣekúpa - Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà

AWORAN BAALU ILEEṢẸ OLOGUN

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN AIR FORCE HQ/FACEBOOK

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria ti ni eeyan mọkanlelọgọrin ni aṣita ado oloro ti ileeṣẹ ologun oriilẹ ju si aarin awọn eeyan to n ṣajọyọ Malud Nabiyy ni ileto Tudun Biri, nijọba ibilẹ Igabi nipinlẹ Kaduna pa.

Ọgagun Edward Buba, agbẹnusọ ileeṣẹ ologun ni eeyan aadọrin miran lo farapa pẹlu.

Saaju ni Ajọ to n ri si isẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria ti kede pe eeyan marundinlaadọruun lo ba isẹlẹ naa lọ, ti awọn ẹgbẹ mi si ni iye naa ju bẹ lọ.

Ileeṣẹ ologun ni awọn yoo maa se ofin toto agbegbe daada ki wọn to ju ado oloro si agbegbe

“A yo tẹsiwaju ninu sise isẹ wa ni ilana to ba ofin ati isẹ wa mu

“Ohun to waye ni Kaduna, a ti kọ ẹkọ pupọ, ti a yo si se atunse. A ri idaju pe irufẹ isẹlẹ yii ko waye mọ lọjọ iwaju”

Ọgagun Buba tun fesi si ẹsun ti awọn ẹgbẹ kan ni apa ariwa fi kan ileeṣẹ ologun pe wọn se ikọlu naa lati mu adikun ba iye eeyan to wa ni apa aeiwa.

O ni “Ileeṣẹ ologun Naijiria ni awọn osisẹ lati gbogbo ẹya, ti ọrọ naa ko si ri bẹ, asise ni ikọlu naa.”

Nǹkan yẹpẹrẹ ni ọ̀rọ̀ tí Iléeṣẹ́ ológun sọ pé nítorí pé àwọn kẹ́ẹ́fín àwọn jàndùkú ni wọ́n fi sọ àdó olóró - Gómìnà Sani

Aworan Gomina Sani ati Igba keji Aarẹ Kashim Shettima ni ile iwosan

Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani ti bu ẹnu atẹlu ọrọ ti ileeṣẹ ologun sọ sita lori ibu gbamu to waye agbegbe Tudun Biripe awọn ro pe awọn janduku lo lo wa nibi ti awọn ju ado oloro si.

Isẹlẹ yii to waye Aiku ọsẹ yii sekupa ọpọ eeyan , ti awọn miiran si farapa yanayana

Gomina Sani lasiko to n sọrọ pẹlu Ileeṣẹ Channels sapejuwe ọrọ ti ileeṣẹ ologun sọ sita gẹgé bi ohun to kudiẹ kato, to si yẹ ki wọn wo ọrọ naa wo ki wọn to gbe igbesẹ.

“Ohun to waye ni Tudun Biri jẹ ohun to bami lọkan jẹ pupọ. Sugbọn ko si wahala bayii nitori ọga gba ti gba pe awọn se asise.

“Sugbọn lati sọ pe awọn janduku wa ni agbegbe naa ni o nilo pe ki wọn fi di rẹ mulẹ. Mo ro pe ọrọ naa kydiẹ kato nigba ti mo gbọ lanaa.

“Ti ẹ ba lọ si ile iwosan lati lọ ri nnkan to n sẹlẹ, ẹ ma bu ẹnu atẹlu ọrọ naa.”

Ileeṣẹ ologun ni lati ko ọrọ wọn jẹ

Gomina Sani ni ileeṣẹ ologun si ni ifọwọsowọpọ oun nini gbigbe ogun ti awọn janduku sugbọn wọn ni lati ko ọrọ wọn jẹ pada.

“Eyi kọ ni a n sọ bayii, sugbọn gẹgẹ bi mo se sọ tẹlẹ, a yoo tẹsiwaju lati ma se atilẹyin fun ileeṣẹ ologun nipinlẹ Kaduna.

Sani wa kesi Ọga ileeṣẹ ologun, Ọgagun Lagbaja lati rio pe wọn ri ọrọ naa pada.

“Mo ro pe ọrọ akọkọ ọgagun Lagbaja, mo ro pe oun ni mo mu pe ko yẹ ko lọ bẹ.

“Ọrọ keji ti agbẹnusọ ileeṣẹ ogun sọ. Mo n igbiyanju lati kan si Ọgagun Lagbaja lati ri pe wọn ko ọrọ wọn jẹ pada.

Atunse yoo bẹrẹ laarin ọsẹ mẹta si asiko yii

Gomina Sani ni ipinlẹ Kaduna yoo bẹrẹ si ni se atunse si ilu Tudun Biri nijọba ibilẹ Igabi ni ọsẹ mẹta si asiko yii, to si fi da awọn araalu pe Igba keji Aarẹ ti ṣe ileri lati jẹ ko waye .

“Isẹlẹ to wa yii, a ti gbe igbimọ kalẹ , gbogbo ilu naa ni a yoo tun kọ.”

“Igbakeji Aarẹ ti pe mi, o si fi da mi loju pe sise atunse si ilu naa yoo bẹrẹ ni aipẹ.

“Ko ni yamilẹnu to ba bẹrẹ laarin ọsẹ meji.

“Lonii, wọn ti gba pe awọn se asise. A yoo bẹrẹ iwadii lati mọ awọn to lọwọ ninu isẹlẹ naa, ti wọn si jiya labẹ ofin.”