'Orí ló kó èmi àti ìyàwó mi yọ, àwa náà ìbá kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó gbẹ̀mí àwọn ọba mẹ́ta l'Ogbomoso'

Aworan awọn alaye mẹta to papoda

Ibẹru boju ni ọpọlọpọ arin irinajo to n gba ọna Oyo si Ogbomoso wa lati ti bi oṣu kan bayii nitori bi ọpọ ẹmi ṣe n bọ loju opopona naa.

Ọsẹ to kọja ni ọba alaye mẹta padanu ẹmi wọn ninu ijanba pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Benz E230 kan ati ọkọ akero Scania to ni nọmba idanimọ 301 XF loju opopona.

Ni bayii ,eeyan mẹrindinlogun ṣe ṣalabaapin ninu ijanba ọkọ ayọkẹlẹ ni agbegbe ilu Ogbomoso laarin ọṣẹ to kọja ti awọn Ọba alade mẹta sii wa lara awọn to padanu ẹmi wọn.

Ileeṣẹ BBC Yoruba kan si awọn mọlẹbi awọn ọba alaye naa, ti wọn si salaye bi isẹle naa se waye.

Ori lo komi yọ, o ṣe e ṣe ki emi ati iyawo mi ba iṣẹlẹ ijamba naa lọ - Ọmọọba Adetunji

Adetunji Johnson, ẹni to ọmọ Ọba Olodogbo ti ilu Odogbo, to padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ ayọkẹlẹ lopopona Ogbomoso si Oyo laipẹ yii, ba akọroyin ileeṣẹ BBC Yoruba sọrọ, ṣalaye wi pe,

"Emi ni mọ fọ ọkọ ayọkẹlẹ ti Kabiyesi Ọba Amos Adetunji Olodogbo ti ilu Odogbo àti awọn Ọba meji miran gun jade ṣaaju ki wọn to padanu ẹmi wọn.

"Baba mi rọ mi ati iyawo mi lati tẹlẹ oun lọ si ibi ode inawo ti oun lọ ni agbegbe Oolo ṣugbọn nitori wi pe mọ fẹ ṣe iṣẹ die laarọ ọjọ naa ti mo si ṣeleri lati wa pade wọn laarin wakati meji si mẹta.

"Ko ti pe iṣẹju marun-un ti wọn kuro nile ni iroyin kan mi lara wi pe wọn ṣe alabapade ijamba ọkọ ayọkẹlẹ ni agbegbe Aje Iya, to wa leba ọdọ arinkinkin,

"Lẹsẹkẹsẹ ni mo lọ sí ile iwosan LAUTECH Teaching Hospital, mọ bá baba mi Kabiyesii Oolodogbo ti ilu odogbo lori beedi ti wọn tẹ si, to si n gba itọju ṣaaju ki wọn to gbeṣe lọjọ naa

ỌmọỌba Adetunji ṣalaye wi pe Kabiyesi Amos Adetunji gan lo wa ọkọ ayọkẹlẹ ohun lọjọ naa ti akọbi ọmọ ọmọ Kabiyesi Olodogbo naa si wa rẹ pẹlu ninu ọkọ ọhun.

Adetunji nii ọmọ ọmọ Kabiyesi Olodogbo nikan ni o yee ninu gbogbo awọn to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ Benz naa".

'Wakati kan lẹyin ti mo gbe wọn lọ si ile Kabiyesi Olodogbo ni wọn pe mi wi pe Baba ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ayọkẹlẹ.'

Adeniran Bukola ọkan lara ọmọ Kabiyesi Samuel Adedoyin Adeniran Kabiyesi ilu Ayetoro Lailai ti oun naa wa lara awọn Kabiyesi mẹta to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ayọkẹlẹ lopopona Ogbomoso si Oyo naa ba BBC Yoruba sọrọ;

"Wakati kan lẹyin igba ti mo gbe wọn lọ si ile Kabiyesi Olodogbo ni wọn pe mi wi pe Baba ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ayọkẹlẹ ".

Adebisi Christiana akọbi ọmọ Kabiyesi Adedoyin Adeniran, ṣalaye wi pe, Kabiyesi Alayetoro ti ilu Ayetoro Lai lai , kii sabaa jade fun inawo nitori wi pe Kabiyesi Adedoyin jẹ ẹni ọdun mejilelaadorun(92) lọjọ ori.

Christiana ẹni ti o jẹ oṣiṣẹ ile iwosan LAUTECH Teaching Hospital nibiti wọn gbe awọn Ọba naa lo fun itọju ṣalaye wi pe, iyalẹnu lo jẹ nigbati oun ri Kabiyesi Alayetoro lori ibusun ile iwosan ṣaaju ko to jade laye.

Lẹyin ipapoda awọn ọbalaye l'ọyọ, eeyan mẹrin mii tun ti padanu ẹmi wọn nibẹ - Araalu

Awọn ọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ ti parọwa si ijọba apapọ lati wa ojutuu si awọn ijamba ọkọ ayọkẹlẹ to n ṣẹlẹ lemolemo lagbegbe ọhun.

Awọn omobibi ilu Ogbomoso ti rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lati yara pari opopona marosẹ Ibadan si Ilorin ti ijọba apapọ ti beere lati ọdun 1999,wọn ni aipari ọna ọhun lọ ti sokunfa iku fun ọpọlọpọ arinrin-ajo to n lọ oju ọna marosẹ Ibadan si ilu Ogbomoso.

Wọn rọ ijọba ipinlẹ Oyo ati ijọba apapọ lati kọ opopona agbẹyefo si awọn agbegbe kọkan bí Takie,Caretaker lati dẹkun bí ọpọlọpọ ṣe máa ń padanu ẹmi wọn nigbati wọn ba n fọ opopona ohun kọja.

Aworan