Mo padà sí ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti ran Tinubu lọ́wọ́ kí ó le ṣe àṣeyọrí – Adelabu

Aworan Adebayo Adelabu

Oríṣun àwòrán, Others

Minisita fun ẹka amusagbara lorilẹede Naijiria, Adebayo Adelabu ti kede pe oun ti pada sinu ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin to kuro ninu ẹgbẹ oṣelu Accord Party to fi dupo gomina lọdun 2023.

Adelabu ni oun ko gbe igbesẹ yii lati le ni anfani lati gba agbara lọwọ Gomina Seyi Makinde lọdun 2027.

O sọ eyi ni ọfisi ẹgbẹ oṣelu APC to wa ni oke ado niluu Ibadan.

Nigba to n ba awọn ololufẹ ẹgbẹ naa sọrọ, o ni gbogbo awọn to kuro ninu ẹgbẹ oṣeiu naa pẹlu oun lo ti pada sinu ẹgbẹ oṣelu APC bayii lati fun ẹgbẹ naa ni agbara ati ilọsiwaju.

O salaye oun kuro ninu ẹgbẹ oṣelu naa nitori ilana, ti ko dẹ ki n se nitori pe oun ni iṣoro kankan pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC tabi pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ.

“Pipada mi kii se nitori eto idibo ọdun 2027 tabi pe mo ni erongba lati gba isakoso ẹgbẹ naa sugbọn nitori pe mo ni igbagbọ ninu ẹgbẹ oṣelu to gbe Aarẹ Tinubu wọle, a dẹ nilo lati se iranlọwọ fun un ko le se aṣeyọri.

“Asiko oṣelu kọ ni a wa yii. Asiko ijọba lawa yii , Tinubu si nilo iranlọwọ wa lati se aṣeyọri .

“Mo pada sinu ẹgbẹ yii nitori a nilo lati sisẹ pọ ki se nitori pe mo fẹ gba isakoso ẹgbẹ.

“A wa n fi da yin loju pe a yoo sisẹ pọ lati mu ilọsiwaju de ba ẹgbẹ naa, ti a yoo si gba eto iṣejọba ipinlẹ Oyo lọdun 2027.

Ninu ọrọ rẹ, Alaga ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Oyo, Isaac Omodewu, ẹni ti akọwe ẹgbẹ, Alhaji Tajudeen Olanike soju fun ni ilẹkun ẹgbẹ oṣelu APC si silẹ fun ẹnikẹni , ti ẹgbẹ naa si setan lati gbọ erongba awọn ọmọ ẹgbẹ.

Bakan naa, Igbakeji Gomina tẹlẹri nipinlẹ Oyo, Moses Adeyemo pe fun alaafia ati isọkan laarin awọn ọmọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo.