Ó pẹ́ tí mo ti mọ̀ pé àyànmọ́ Pásítọ̀ Ghandi ni láti jẹ ọba- Pásítọ̀ Adeboye

Aworan Oba Ghandi ati Pasitọ Adeboye

Pasito ti ijọ Redeemed Christian Church of God, RCCG, Aluufa agba Enoch Adeboye, ni oun ti mọ tipẹ pe Ọba Ghandi Olaoye, Soun ti ilu Ogbomoso wa saye lati jẹ Ọba ilu Ogbomoso.

Adeboye nigba to n soro ni Beulah Baptist Conference, Ogbomoso ni bi ti isin idupe ti wọn gbe kalẹ lati se ayẹyẹ gbigba ọpa aṣẹ Soun ti ile Ogbomoso sọ wi pe oun mo wí pe Oba Ghandi yóò jẹ Ọba.

Bakan naa lo salaye idi ti ko fi da pasitọ Afolabi Ghandi Adeoye duro nigba to fi to leti pe o fẹ dupo Soun ti ile Ogbomoso.

Pasito Adeboye nii ; "Nigba ti o wa sọdọ mi lati so fun un nipa oye Oba Soun ti ilẹ Ogbomoso to ṣi silẹ, mo so fun un pe ki o lọ gbadura,

“O pada wa sọ fun mi wi pe oun ko tii gbọ nnkan kan, ti mo tun sọ fun un wi pe ki o tun pada lọ gbadura, lẹyin igba die lo pada wa.

“O sọ fun mi wi pe, Ọlọ́run ti sọrọ, oun gbọ ohun rẹ wi pe ki oun dupo Soun ti ilẹ Ogbomoso nigba naa ni mo sọ fun un pe ko lọ nitori wi pe Ọlọ́run ti kadara rẹ yoo jẹ Ọba.

“Ti mo ba sọ wipe ko ma jẹ Soun ti ilẹ Ogbomoso, ti Ọlọrun si ni ko jẹ nkọ?

“Ọrọ Ọlọrun si ṣe pataki ju ti temilọ.”

Ninu iwaasu rẹ Adeboye rọ Ọba Ghandi Olaoye lati gba awọn eniyan mọra ki o si gbe jẹ ki alaafia ati isokan jọba niluu Ogbomoso.

Lẹyin iwaasu rẹ, Pasito Adeboye fi ororo ya Ọba Ghandi Afolabi ati iyawo rẹ si mimọ, o gbadura fun pe alaafia ati ilosiwaju jọba lasiko rẹ gẹgẹ bi Soun Ogbomoso.

Màá jẹ Ọba lórí ẹ̀sìn Krìstíẹ́nì, Mùsùlùmí àti àwọn Oníṣẹ̀ṣe

Aworan Ọba Ghandi

Ninu ọrọ idupe rẹ, Oba Ghandi Olaoye sọ pe, Aluufa agba Enoch Adejare jẹ apẹẹrẹ asaaju rere fun oun to si jẹ ko di mimọ wipe “Pastor Adeboye da bi baba fun mi”.

Ọba Ghandi Afolabi rọ awọn eeyan ilu Ogbomoso lati se atilẹyin pẹlu oun, to si ṣeleri lati jẹ Ọba lori gbogbo awọn ẹlẹsin to wa ni ilu Ogbomọṣọ lai da ẹṣin kan sii.

“Inu mi dun lonii pe ẹni ti o gbe ọwọ le mi lati di Olusọ agutan ni ẹni ti o fi ororo ya mi nigba ti mo di Ọba.

“Gbogbo ọmọ ilu Ogbomoso, ẹ jẹ ka sisẹ pọ ka fi gbe ilu wa soke ati lati mu ayipada to ni apẹẹrẹ ba ilu Ogbomoso.

“Mo ni igbagbọ pe igba ọtun ti de si ilu Ogbomoso.

“Maa jẹ Ọba fun awọn Kristẹni, Musulumi ati awọn Ẹlẹsin ibilẹ. Maa jẹ Ọba fun ọkunrin ati obinrin ilu Ogbomoso.

“Mo ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo fi anu rẹ gba mi lati fi le jẹ olori rere. Mo fẹ ki gbogbo ọmọ ilu Ogbomoso ma gbadura fun mi.”